US Election 2020: Biden jẹ́jẹ̀ẹ́ láti gbé ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá kalẹ̀ fún ìtọ́jú Coronavirus

Aarẹ tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan ni orilẹede Amẹrika, Joe Biden ti fọwọ sọya pe oun yoo mu irẹpọ ba orilẹede naa.
Biden fọwọ idaniloju naa sọya ninu ọrọ akọsọ rẹ to bawọn eeyan orilẹede Amẹrika sọ lasiko ti wọn n se ajọyọ bo se bori ibo naa.
Aarẹ tuntun naa naa lo fi ẹyin aarẹ Donald Trump janlẹ ninu eto idibo aarẹ to waye lọjọ Isẹgun amọ Trump ni oun yoo tako esi ibo naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Biden ni "Mo jẹjẹ lati jẹ aarẹ ti ko ni wa iyapa orilẹede Amẹrika amọ maa wa ọna ti irẹpọ yoo se wa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹni ti ko ni maa wa abala to jẹ buluu tabi pupa kiri ni orilẹede naa, amọ orilẹede Amẹrika nikan ni maa ma ri."
Aarẹ tuntun naa, ẹni to gun ori pepele lati sọrọ pẹlu ibomu lẹnu rẹ tun kede pe, oun yoo se agbekalẹ igbimọ to yoo maa tete gbogun ti arun Coronavirus.
O ni oun yoo tun ri daju pe oun se amusẹ awọn ipinnu ti wọn ba gbe kalẹ ni kete ti wọn ba se ibura tan fun oun ni osu kinni ọdun to n bọ.
Sanitáísa leé ba ìwé ìtẹ̀ka ìbò jẹ́ - Àjọ CDC kìlọ̀

Ibi ti ajakalẹ arun Coronavirus bá orilẹede Amẹrika de ti ni ipa nla lorii idibo wọn. Ṣugbọn awọn onimọ ni bi awọn ara Amẹrika ṣe dibo yan aarẹ lonii, o ṣeeṣe ki ọrọ covid-19 ṣe akoba lọna mii.
Ajọ to n mojuto gbigbogun ti ajakalẹ arun nilẹ Amẹrika, CDC ti ṣaaju fi ikilọ sita pe sanitaisa to ni ọti ninu ni agbara lati ba iwe itẹka ibo jẹ.
Idi eyi ni pe awọn iwe itẹka to n jẹ "ballot" ti ogun apakokoro sanitaisa ba jẹ ko tutu lee lẹpọ o si lee ha sẹnu ẹrọ idibo.
- Àwọn àkọ́lé ìròyìn mẹ́ta tó leè tẹ̀lẹ́ ìdìbò Ààrẹ ilẹ̀ Amẹrika
- US Election 2020: Nígbà wo laó mọ èsì ìdìbò àti pé ṣé ó ṣeé figagbága?
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Joe Biden, tó ń kojú Trump nínú ìbò America
- Mọ̀ sí i nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́sàn-án tó ń díje nínú ìdìbò ilẹ America lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun
- US Election 2020: Ṣé èsì ìdìbò Ààrẹ Amẹrika yóò jáde lálẹ́ ọjọ́ ìdìbò?
Ajọ CDC naa lo ni sanitaisa gbudọ wa lawọn ibudo idibo lati rii pe abo to daju wa fawọn oludibo ṣugbọn wọn rọ awọn oṣiṣẹ eto idibo atawọn oludibo lati rii pe ọwọ wọn gbẹ daadaa ki wọn to fọwọ kan iwe itẹka.
Ṣaaju ni ibẹrẹ ọdun yii, iwe itẹka to tutu fa wahala lasiko idibo ẹkun kan ni New Hampshire.
Bakan naa loṣu to kọja, Saramento ti California, ọpọlọpọ ibo lo bajẹ lẹyin ti awọn eeyan fin iwe itẹka wọn pẹlu ogun apakokoro eyi to si jẹ ki ọda rọ mọ ọ lara ti ko si ṣee ka mọ afi igba ti wọn ko iwe itẹka miran fun wọn.












