US Election 2020: Ta ni Kamala Harris obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ igbá-kejì ààrẹ orílẹ̀èdè Amẹrika?

Kamala Harris

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi wọn ba ni pe ki ẹ pe koṣẹlẹri wa, Kamala Harris to jẹ obinrin akọkọ ti yoo dipo igbakeji aarẹ mu ni Amẹrika ni kẹ pe.

Yatọ si pe o jẹ obinrin akọkọ oun ni obinrin alawọdudu akọkọ ti yoo dipo yi mu.

Nilu Oakland California ni wọn ti bi lọdun 1964.

Iya rẹ jẹ ọmọ ilẹ India ti Baba rẹ si jẹ ọmọ Jamaica.Awọn mejeeji gbiyanju ọrọ aje wa si Amẹrika ni.

Aworan Kamala Harris

Oríṣun àwòrán, Facebook/KamalaHarris

Ninu ọrọ rẹ arabinrin Harris sọ pe oun ko ni wahala kankan pẹlu ibi toun ti wa ati pe oun a ma juwe ara oun gẹgẹ bi ''ọmọ ilẹ Amẹrika.''

Ni fasiti Howard to jẹ gbajugbaja fasiti awọn alawọdudu lo ti kawe gboye imọ ofin .

Lọdun 2003 o di agbẹjọro agba akọkọ ilu San Fransisco lẹyin igba naa lo tun di agbẹjọro agba nilu California.

Aworan Kamala Harris

Oríṣun àwòrán, Facebook/KamalaHarris

Oun ni eeyan alawọdudu akọkọ ti yoo di ipo yi mu.

Lọdun 2019 Harris ṣe ifilọlẹ ipolongo rẹ lati di oludije ipo aarẹ Amẹrika labẹ asia ẹgbẹ Democrats ṣugbọn o fidi rẹmi lọwọ Joe Biden.

Biden pada yan gẹgẹ bi igbakeji ti awọn mejeeji si jijọ dije dupo aarẹ ti wọn si ti wa jaweolubori bayi.