Sunday Igboho: Àwọn olùgbé Igangan ní ó sàn káwọn kú, ju kí Seriki Fulani padà sílùú lọ

Oríṣun àwòrán, Nuj Kwara
Àwọn olùgbé ìlú Igangan níjọba ìbílẹ̀ Ibarapa nípìnlẹ̀ Oyo tí búra o, pé láí, àwọn kò le gbà kí Seriki Fulani, Abdulkadri Saliu pada wá sí ìlú Igangan.
Gẹ́gẹ́ bi wọ́n ṣe sọ, gbígba Seriko Fulani padà wá sí inú ìlú náà kò yàtọ́ sí pé ènìyàn fẹ́ fọ́wọ́ ara rẹ̀ gba ẹ̀mi ara rẹ̀ ni.
Wọ́n fikun pé yóò san kí àwọn kú, jú kí wọ́n gbà á padà lọ.
- Wo ọ̀dọ́mọdé olówó, tí àwọn ọkọ̀, fóònù, ọtí wáínì, ẹ̀ṣọ́ ilé rẹ̀ jẹ́ kìkìdá góòlù
- Buhari fọnmú bí Transparency International ṣe fi Nàíjíríà ṣípò kejì nínú ìwà àjẹbánu
- Ó wù mí kí ń padà sí Igangan, tí wọn bá fún mi láàyè - Seriki Fulani
- Èèyàn 75 di àwátì, 18 jáde láyé bí agbébọn ṣe gbàjọba yíka Nàíjíríà l‘Ọ́jọ́bọ
- Bí Sunday Igboho bá tàpá sófin, kí lẹ ṣe fáwọn ọ̀daràn Fulani tó ń pa èèyàn - Gani Adams
"Gbogbo ìlú yóò ya pa ara wọn ju kí a fi ààyè gba Seriki pada lọ, ó sì sàn kí a fi ẹ̀mí wa lélẹ̀, ju kí àwa àti ìràn wa tún dúró sí abẹ́ Seriki Fulani Igangan "
Olùdásílẹ̀ Igangan Development Advocate, (IDA), Oladiran Oladokun lo sọ bẹ́ẹ̀ fún àwọn oníròyìn lónìí.
Oladokun ń fèsì sí ọ̀rọ̀ tí Seriki Fulani sọ fáwọn oníròyìn lọ́jọ́bọ pé, ó wú òun láti pada sí ìlú Igangan tí wọ́n bá fún òun ni ànfàní míràn.
Saliu, tí àwọn ẹbi rẹ̀ ń ṣe àtìpó nílùú Ilorin lọ́wọ́lọ́wọ́ lo sọ di mímọ̀ lọ́jọ́bọ.
Tí ẹ o bá gbàgbé, ó pé ọjọ́ mẹ́jọ lónìí tí Sunday Igboho lọ sí ìlú Igangan, láti láti lé àwọn Fúlàni tó n huwa ibajẹ́ níbẹ̀ jáde.
Oladokun sàlàyé pé, láti ìgbà tí wọ́n ti lé Seriki Fulani agbègbè náà, ni èémí àláfíà ti wọ̀lú.
Ó fi kún pé, àwọn olùgbé àdúgbò náà ti n fẹ̀dọ̀ lórí òróǹro báyìí, tí olúkúlùkù sì tí ń pada sí ẹnu iṣẹ́ oko wọ́n láì sí ìbẹ̀rù ìjínigbé tàbí fífi ipá báni lòpọ̀.
Olórí IDA sọ pe àwọn ènìyàn ìlú náà ni àwọn kò fẹ́ àṣẹ ti yóò da omi aláfíà, ti àwọn ń gbadun lọ́wọ́lọ́wọ́ rú láàrín ìlú náà.
- 'Bí a ṣe rí ibi ti ọ̀gágun olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ti kú kówó pamọ́ sí.'
- Ewu ń bẹ pẹ̀lú kíkó Amotekun lọ Ibarapa lórí ọ̀rọ̀ Fulani - Baajigan Ilaji Ile
- Sunday Igboho ṣọ́ra ṣe, jẹ́ kí Seyi Makinde ṣiṣẹ́ tí òfin gbé le lọ́wọ́ - Ooni Ife
- Ẹlẹ́nu méjì ni ìjọba Buhari, òun ló ń pín Nàíjíríà yẹ́lẹyẹ̀lẹ - Wole Soyinka
- Wo ìgbẹ̀yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀ Yorùbá tó ran Fulani lọ́wọ́ láti kógun ja ìlú Osogbo
Ó wá rọ ilé iṣẹ́ ààrẹ àti gómínà ìpińlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí tó péye lórí ẹ̀sùn ti wọ́n fi kan Seriki Fulani, ki wọ́n si di òkodoro inú rẹ̀ mú láti fi ẹnikẹni ti igbá ọ̀rọ̀ náà bá ṣímọ́ lórí jófin.
Ó wù mí kí ń padà sí Igangan, tí wọn bá fún mi láàyè - Seriki Fulani

Seriki Fulani nilu Igangna, Saliu Abdulkadir ti sisọ loju rẹ pe ilu Ilorin ni awọn ẹbi oun wa bayii amọ oun sare wa sapa oke ọya fun abẹwo.
Seriki, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nilu Ilorin ni awọn ẹbi oun to wa ni Ilorin ti tẹwọ gba awọn amọ oun setan lati pada maa gbe nilu Igangan ti wọn ba gba oun laaye lẹẹkan si, ti alaafia si jọba pada.
- Bí Sunday Igboho bá tàpá sófin, kí lẹ ṣe fáwọn ọ̀daràn Fulani tó ń pa èèyàn - Gani Adams
- 'Bí a ṣe rí ibi ti ọ̀gágun olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ti kú kówó pamọ́ sí.'
- Ewu ń bẹ pẹ̀lú kíkó Amotekun lọ Ibarapa lórí ọ̀rọ̀ Fulani - Baajigan Ilaji Ile
- Sunday Igboho ṣọ́ra ṣe, jẹ́ kí Seyi Makinde ṣiṣẹ́ tí òfin gbé le lọ́wọ́ - Ooni Ife
- Ẹlẹ́nu méjì ni ìjọba Buhari, òun ló ń pín Nàíjíríà yẹ́lẹyẹ̀lẹ - Wole Soyinka
- Wo ìgbẹ̀yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀ Yorùbá tó ran Fulani lọ́wọ́ láti kógun ja ìlú Osogbo
"Ko si ẹnikẹni to pe mi si ipade kankan titi di akoko yii, ko si ibi ti mo fẹ gbe mọ nilu Igangan, gbogbo ọkọ ati ile mi ni wọn ti jo nina.
Bi mo se n ba yin sọrọ yii, apa ariwa ni mo wa, amọ awọn ọmọ mi wa nilu Ilorin nitori mo ni ile kan nibẹ ti wọn de si.
Seriki wa sisọ loju rẹ pe oun ko sẹ awọn eeyan Igangan rara, nitori awọn janduku ilu naa lo jẹ ọmọ onilu, ti ọwọ ọlọpaa si ti ba wọn, wọn wa lọgba ẹwọn Agodi.
"Lọwọ lọwọ bayii, asaaju awọn janduku naa, Janbele wa lagọ ọlọpa, eyi si wa lara ohun to n da ọta silẹ laarin awa Fulani atawọn eeyan ilu naa.
Lọjọ ti Fatai Aborode ku, awọn janduku yii fi awa atawọn Yoruba sinu igbekun ni, gbogbo wọn ni wọn si ri bi Fatai se n bẹbẹ, to si ni oun setan lati san iyekiye bii owo irapada ẹmi.
Amọ awọn apaayan naa ko gba owo abi ẹbẹ rẹ, ti wọn si pa a."
- Ẹ múra mi sílẹ̀ ẹ̀yin apààyàn Fulani ní Ogun, mò ń bọ̀ kánkán - Sunday Igboho
- Àwọn olóṣèlú ti ń fowó bẹ̀ mí kí n má bá Fulani jà torí ìbò 2023, àmọ́ o ti bọ́ - Sunday Igboho
- Sunday Igboho kò lẹ́tọ̀ọ́ láti lé Fulani nílùú, wọ́n sì le pè é lẹ́jọ́ - Femi Falana
- Wò ó bí Afọnja ṣe finú wénú pẹ̀lú Fulani ní Ilọrin títí tó fi jẹ iwọ
- Seyi Makinde lo ṣí ilé mi tó jóná pẹ̀lú ‘transformer 500kva’ - Sunday Igboho
Seriki Fulani wa ffi ọwọ sọya pe irẹpọ wa laarin oun ati agboole ti wọn ti bi Aborode, tii se ile Alagbẹdẹ
Àwọn ilé mi, ọkọ̀ 12, ọmọ àti ènìyàn méje pẹ̀lú ₦500m ni mo sọnù ní Igangan - Seriki Fulani

Seriki Fulani ní ìlú Igangan níjọba ìbílẹ̀ Ibarapa nípìnlẹ̀ Oyo, Alhaji Salihu Abdulkadir ti fẹ̀sù kan pé ajafẹ́tọ ọmọ Yorùbá, Sunday Adeyemo, ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Sunday Igboho, àti àwọn ìsọ̀mọ̀gbé rẹ̀ pa méje nínú àwọn ènìyàn òun lásìkò tí wọn wa síbẹ̀.
Sáájú ni Igboho ti fún àwọn Fulani ni gbèdéke ọjọ́ méje láti kúrò ninú ìlú Igangan.
Lẹ́yìn ti ọjọ́ náà pé ni Sunday Igboho lọ ilú náà lọ́jọ Ẹtì tó kọ́já nítori pe ó fi ẹ̀sùn kan wọ́n pé àwọn ni wọ́n wà nídìí, ìpàniyan, ìjínigbé àti ìfipá bánilòpọ̀ tó n wáye níbẹ̀.
AbdulKadir sọ pé Fulani méje, àti ǹkan ìní tó tó mílíọ̀nù lọ́nà ẹ̀ẹ̀dẹ́gbẹ́ta náírà ni òun pàdànú.
"Awọn ile mi, ọkọ mejila to jẹ temi, awọn ọmọ mi ati alejo meje ni wọn dana sun, ti a ko si ri oku meji ninu wọn, bẹẹ́ ni wn ji awọn ẹran ọsin mi ko lọ."
Bákan náà ni ó fi kun pé, òun kò lọ́wọ́ nínú gbogbo ẹ̀sùn ti wọ́n fi kan òun nípa ìjínígbe ni agbègbè náà, pàápàá jùlọ ìpànìyàn ọmọwé gboye Havard tó jẹ́ ọmọ ìlú náà, ọ̀mọ̀wé Fatai Aborode ti wọ́n pa ni ìpakúpa.
Lásìkò tó n bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nílùú Ilorin, ti ṣe olúùlú ìpińlẹ̀ Kwara lo ti ni irọ́ pọ́nbélé ni Sunday Igboho ń pa mọ́ òun.
Ó ní òun àti ẹbí òun tí n gbé ìlú Igangan láti bí àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, ti ko sì sí ẹni tó yẹ òun lọ́wọ́ wò.
Ó wa ké pe gbogbo àwọn Emir àwọn ìpínlẹ̀ Arewa mọ́kàndínlogun àti àwọn olóyè, láti dide iranlọ́wọ́ fún gbogbo Fulani tó wà ni ilẹ̀ Yoruba.
Bákan náà lo fi kún pé, nígbà ti wọn wá fi ẹjọ́ ọmọ Fulani kan ti wọ́n ń pe ni Omomogeto sun oun, ẹni ti wọ́n lo fipa bá ọmọbìnrin kan lò pọ̀, òun fá à le ọlọ́pàá lọ́wọ́ ni.
"Lẹ́yìn ti wọ́n mu, ti wọ́n ṣe ìwádìí, tí aje ọ̀rọ̀ náà sì ṣí mọ́ lórí, mo fi si ìkáwọ́ àwọn ọlọ́pàá ni.
Bákan náà ni wọ́n fipa bá ọmọbinrin miraǹ to jẹ́ ọmọ Igangan lòpọ̀ lọ́dún tó kọja, debi pé, ọmọbinrin náà kú, kò sí ǹkan ti wọ́n ṣe sí ẹni tó bá ọmọbinrin náà lòpọ̀ di òní yìí.
O wa kesi ijọba lati tanna wadi awọn ẹsun naa, ẹnikẹni to ba si jẹbi ni ko fi imu ko ata ofin.
Sunday Igboho: Seriki Fulani àti ẹbí rẹ̀ gba inú igbó dé ìpínlẹ̀ Ogun lásìkò làásìgbò Igangan

Ọkan lara awọn ọmọ Seriki Fulani ilu Igangan tawọn janduku ṣe ikọlu si Gaa wọn, ti ṣalaye ohun ti oju wọn ri fun BBC.
Arakunrin Umar Salihu Abdulkadir sọ fun BBC, lasiko ifọrọwerọ rẹ pẹlu a, lati nkan bi ago mẹrin ọsan tawọn ti sa kuro ni Igangan, awọn ko duro titi di ago mẹta oru tawọn de ipinlẹ Ogun.
O ni pupọ awọn eeyan awọn lawọn ko mọ ibi ti wọn wa, to fi mọ Seriki Fulani to jẹ baba oun.
- Ìfẹ́ Yorùbá ló mú mi fi ẹ̀mí wéwu láti kojú ajínigbé ní Kishi - Sunday Igboho
- N kò jà fún ìṣọ̀kan Yorùbá láti wá ipò tàbí orúkọ - Sunday Igboho
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ lórí ohun tó kan fún ilẹ̀ Yorùbá lọ́dún 2021
- Wo ìgbésẹ̀ tí àwọn lọ́balọ́ba, ọlọ́pàá àti Seyi Makinde fẹ́ gbé lórí áàwọ Ibarapa
- Mo ń padà bọ̀ ní Ibarapa lọ́sẹ́ tó ń bọ̀- Igboho; Gbogbo dúkìá mi làwọn ọmọ Igboho jó tán- Seriki Fulani
- Wo ǹkan mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sunday Igboho tí orúkọ rẹ̀ gbẹnu aráyé kán
- Ó tó gẹ́! Ọ̀gá Ọlọ́pàá pàṣẹ pé kí Kọmísọ́nnà Oyo mú Igboho wà sí Abuja
- Igboho vs Fulani: Báyìí ni nǹkan ṣé ń lọ nílé Sunday Igboho lónìí
- Wo ohun tí BBC rí nílé Seriki Fulani ní Igangan
- ''Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo kò bẹ̀rù idúnkokò mọ́ni iléeṣẹ́ ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ àwọn Fulani darandaran''
Salihu ni niṣe ni awọn to ṣigun wa ba awọn bẹrẹ si ni yin ibọn, ti wọn si dana sun ile laisi idiwọ kankan.
Ninu ọrọ rẹ o ni Sunday Igboho ko lẹbi iṣẹlẹ naa, bi ki ṣe pe awọn ijọba ati ọlọpaa kọ lati pese aabo to peye fawọn.

''Ijọba ati awọn ọlọpaa tan wa pe ko ni si nkankan sugbọn nigba ti awọn janduku de, nise ni wọn sa lọ.''
Ọkọ mọkanla, ile ainiye ati aimọye maalu lo ni awọn janduku bajẹ nigba ti wọn kọlu awọn.
O ni ẹsun ti wọn fi n kan awọn Fulani yii ko ri bẹẹ nitori bi awọn ajinigbe ṣe n gbe Yoruba, naa ni wọn n ji Fulani naa gbe.
Nipa ẹsun pe Seriki lo n gba owo lọwọ awọn ajinigbe o sọ pe irọ nla ni.

''Gbogbo ọrọ ti wọn n sọ yii, ọna ati da Oduduwa Republic wọn silẹ ni wọn n ba kaakiri.''
Ọmọ Seriki naa tun ni mọsalasi, aaye ti wọn ti n pese wara maalu ati awọn dukia mii ni awọn janduku naa baje ni Igangan.
Inu yara mi ni yanduku ti sa mi lọgbẹ - Aya Seriki Fulani
BBC se alabapade iyawo akọkọ Seriki Fulani, arabinrin Mariam ti wọn ṣe leṣe, to si n gba omi sara.
Lasiko ti BBC bẹ obinrin naa wo nijọba ibilẹ Odeda nilu Abeokuta, apa kan ori rẹ la ri ti wọn lẹ pilasita mọ oju ọgbẹ to wa lori rẹ.
Mariam ni inu yara oun ni awọn janduku kan to jẹ ẹya Yoruba wa ka oun mọ, ti wọn si sa oun ni ọbẹ lori.
Bi o tilẹ jẹ pe a gbiyanju lati ba Mariam, aya Seriki Fulani naa sọrọ, amọ ko le e sọrọ daadaa ju pe o darukọ rẹ fun wa lọ.

Bakan naa la ri okun ti wọn ti sẹsẹ fa omi si ara obinrin naa lara.
Ṣaaju ni BBC Yoruba ti laanfaani lati ba Seriki sọrọ lẹyin ikọlu to waye si Gaa wọn ni Igangan.
Ninu alaye to ṣe, Seriki ni oun naa sa kuro ni ati pe ibudo ifarapamọ si lohun ati awọn eeyan oun wa, tawọn ti n ba wa sọrọ.
Igbesẹ ileesẹ ọlọpaa ree lori wahala Igangan:
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, tan imọlẹ sohun to ṣẹlẹ ni Igangan.
Atẹjade naa ti Fadeyi Olugbenga fọwọ si lorukọ Kọmisana ṣalaye pe, omi alaafia ilu daru lẹyin ti Sunday Igboho lọ si Igangan lọsan ọjọ Kejilelogun oṣu Kini.
Fadeyi ni lẹyin ti Igboho lọ tan lawọn janduku yabo aaye ibugbe awọn Fulani pẹlu nkan ija orisirisi ti wọn si dana sun ile.
''Nibi ikọlu yii, wọn ṣe awọn eeyan leṣe, to fi mọ ọlọpaa kan nibi to ti n ṣe iṣẹ rẹ''
''Nitori bi nkan ti ṣe ri yii, Kọmisana ọlọpaa n parọwa si awọn araalu lati faaye gba alaafia, kawọn ọdọ si ma ṣe jẹ ki wọn lo wọn fi da ogun ẹlẹyamẹya silẹ''





















