Yoruba people: Sunday Igboho sọ̀rọ̀ lórí ohun tó kan fún ilẹ̀ Yorùbá lọ́dún 2021

Oríṣun àwòrán, Facebook/Sunday Igboho
Bi ọpọ pasitọ ati aafa ṣe n sọ asọtẹlẹ lori ohun ti yoo ṣẹlẹ lọdun tuntun ọdun 2021 yii, ajafẹtọ Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Ighoho ti sọrọ akin lori ohun to kan fun ilẹ Yoruba.
Sunday Ighoho sọrọ yii lori ẹrọ amohunmaworan pẹlu awọn ọdọ kan ti wọn kan si nile rẹ.
Ọgbẹni Adeyemo sọrọ o fa komookun rẹ yọ pe ọdun ominira ni ọdun 2021 yii jẹ fun ilẹ Yoruba.
- Pásítọ̀ Adeboye bú ẹnu àtẹ́ lú ìjọba tó fofin dé ìsìn ìrékọjá sí ọdún tuntun
- Bá wo ni òrékelẹ́wà Adedoja tó gbàmì ẹ̀yẹ ''Miss Oyo 2020'' ṣe jẹ́ sí Alaafin?
- Mí ò gba àbẹ́tẹ́lẹ̀ rí ní ọgbọ̀n ọdún ti mo fi ṣíṣẹ́ ọlọ́pàá- CSP Francis Osagie
- Iléẹ̀kọ́ Deeper Life, ẹ san N100m owó gbà má bínú fún ọmọ mi, kẹ sì tọrọ àforíjìn - Òbí akẹ́kọ̀ọ́
- Gbogbo ẹ̀yin tí 'SIM Card' yín tí sọ̀nú, ẹ wo ọ̀nà tí ẹ lè fi gbà á padà!
- Aláìnímọ̀ ló ní kò sí àsọtẹ́lẹ̀ nínú Islam - Sabitu Olagoke
Sunday Igboho ni awọn ọdọ lo n jiya ju ni Naijiria, nitori diẹ ni tawọn agbalagba nibẹ.
''Abọwaaba lọrọ awọn agbaagba ilẹ Yoruba, awọn ọdọ lo yẹ ki a ṣe ara wa lọkan,'' ọgbẹni Adeyemo lo sọ bẹẹ.
Sunday Ighoho ni o ti wa ninu akọọlẹ pe ọdun ayọ ati ọdun ominira ni ọdun 2021 jẹ fun ilẹ kaarọ o jiire.
O ṣalaye oun atawọn mii to fẹ ki Yoruba gbaye gbadun ko ni ohun kan ṣe pẹlu awọn ọlọpaa ati sọja.
Sunday Igboho ni ọpọ ọdọ lo ti ka iwe gboye ni ile ẹgọ giga fasiti tan lai ri iṣẹ ṣe.
O gbadura pe gbogbo awọn to ba ṣe abosi tabi da ilẹ Yoruba, ilẹ Yoruba yoo da fun wọn.
Sunday ṣalaye pe ọpọ lo ro pe oun kan ṣadedee dakẹ lori ọrọ ilẹ Yoruba.
Amọ, o sọ pe agbo oun to fẹyin rin, agbara lo lọ mu wa.
Ọgbẹni Adeyemo rọ awọn ọdọ pe ki wọn maa ṣojo, ki wọn si mura lati ja fun ẹtọ wọn.
O ni awọn ọdọ ti wọn maa n ran lati tako awọn ọdọ ilẹ Yoruba to n beere fun ẹtọ wọn ni ori wọn ko pe.












