Deeper Life Scandal: Iléẹjọ́ ní kí òbí akẹ́kọ̀ọ́ tó ní wọ́n fipá bóun lòpọ̀ yé sọ̀rọ̀ mọ́ lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, /Deeper Life High SchoolDeborah Okezie
Ileẹjọ majisireeti to wa niluu Uyo, nipinlẹ Akwa Ibom ti tun kilọ fun iya akẹkọọkunrin girama Deeper Life nilu Uyo ọmọ ọdun mọkanla, Deborah Archibong to fi ẹsun kan awọn akọ ẹlẹgbẹ rẹ pe wọn n fi tipa ba oun lopọ pe ko ye sọrọ lori ayelujara mọ.
Ti ẹ o ba gbagbe, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom ṣafihan eeyan meje tawọn ọmọ kekere wa ninu wọn lori ẹsun ifipabanilopọ pẹlu Don-Davis Archibong akẹkọọ ileewe DLHS niluu Uyo.
Ẹsun onikoko mẹrin ni wọn fi kan awọn eeyan naa eleyi to lodi si ofin ipinlẹ Akwa Ibom lori ẹsun iwa ọdaran nipinlẹ naa.
- Igboho vs Fulani: Makinde ní ẹnikẹ́ni tó bá dúnkokò mọ́ Fulani láti kúró lórí ilẹ̀ Oyo yóò fojú winá òfin
- Àwọn Ọba ló rànṣẹ́ pè mi pé ìyá ìjínigbé àti ìpànìyàn yì tó gẹ́- Sunday Igboho
- Ẹ wo ohun tí Seriki Fulani sọ fún gómìnà Makinde nípa Sunday Igboho
- Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu
- Covid-19 ti ṣekúpa èèyàn 1,478 báyìí ní Nàìjíríà, 92,336 ti jàjàbọ́
Agbẹjọro Arabinrin Archibong, David Okokon sọ fawọn akọroyin lọjọ kẹfa oṣu kinni ọdun 2021 ti igbẹjọ waye kẹyin lori ọrọ naa pe ileẹjọ kilọ fun obinrin naa pe ko maa sọrọ lori ẹrọ ayelujara mọ.
Ṣaaju akoko yii, Arabinrin Archibong maa n sọrọ loore koore lori ayelujara lori ẹsun ifapabanilopọ pẹlu ọmọkunrin rẹ, Don-Davis.
Ẹwẹ, ileẹjọ ko fawọn akọroyin ni anfaani lati wọle lasiko igbẹjọ naa.
Iléẹ̀kọ́ Deeper Life, ẹ san N100m owó gbà má bínú fún ọmọ mi, kẹ sì tọrọ àforíjìn - Òbí akẹ́kọ̀ọ́
Yoruba ni ti ọrọ ba se n pẹ nilẹ, yoo maa gbọn si ni.
Ọrọ akẹkọkunrin kan to fi ẹsun kan awọn akọ ẹlẹgbẹ rẹ pe wọn n fi tipa ba oun lopọ, nilegbe awọn akẹkọọ girama Deeper Life nilu Uyo, to ti n ja rainrain nilẹ fun bii ọjọ melo kan, ti wa n gbọn si bayii.
Idi ni pe awọn obi akẹkọkunrin ọmọ ọdun mọkanla naa ti kọwe sile ẹkọ ọhun lati beere ọgọrun miliọnu naira owo gba ma binu.
Iwe naa, ti wọn kọ si ọga ileẹkọ girama naa ni wọn pe akori rẹ ni 'Asilo, ọyaju, idẹyẹsini, ifiebipani, ifiyajẹni ati iwa agabagebe si ọmọ awọn'.
Agbẹjọro awọn obi akẹkọkunrin naa, David Okokon, lo fi iwe naa sọwọ sile ẹkọ Deeper Life ọhun, lọjọ kejilelogun osu kejila ọdun 2020.
Okokon wa n fun ileewe naa ni ọjọ mọkanlelogun pere lati san ọgọrun miliọnu naira yii, ko si tun tẹ iwe itọrọ aforiji sita ninu iwe iroyin ilẹ wa meji, ti wọn n ri ka nilu Uyo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn òṣèré Yorùbá t'Élédùwà gbà fún àmọ́ tí wọn kìí ṣe ọmọ ilẹ̀ Yorùbá
- Dangote já mi kulẹ̀ lóri ọ̀rọ̀ ìfẹ́ àmọ́ ó kọ́ mi bá a ṣé lówó - Ọ̀rẹ́bìnrin Dangote lahùn
- Ẹ sunkún mọ níwọ̀n lórí àríwísí yín sí Buhari lọ́dún 2021 - Femi Adesina
- Mọ̀ si nípa Samuel Ajayi Crowther, bó ṣe pé àádóje ọdún tó jáye láyé
- Ọ̀lẹ adàrí, tí kò lóye, ló fìyà jẹ wá ní 2020 yàtọ̀ sí Coronavirus - Atiku Abubakar
Agbẹjọro naa ni "iru iwa bayii n bi ni ninu, o le seku pani , to si tun jẹ iwa agabagebe ẹsin wipe wọn fiya jẹ ọmọ onibara mi nipa biba eeyan rere rẹ jẹ ni kekere.
A wa n fi tọwọ-tọwọ beere ọgọrun miliọnu naira bii owo gba ma binu fun iwa idojutini, ifiyajẹni ati ailọwọ tẹ hu si ọmọ onibara mi, eyi ti yoo fi setọju ara rẹ."
Nibayii, ijọba ipinlẹ Akwa Ibom ti yọwọ-yọsẹ kuro ninu iwadii to n se nipa ẹsun ifipa ba akẹkọkunrin naa lo pọ.
- Bí ẹ bá tó bẹ́ẹ̀ ẹ pàdé mi l'Òjé- Makinde; Wọ́n ń tàn Ẹ́ bí àbẹ́là- APC
- Lere Paimo ṣàlàyé bí fíìmù "Ogbori Elémosho" ṣe sọ ọ̀ di Olóyè MFR pẹ̀lú Dangote àti Adenuga
- "Adájọ́, ẹ má tú wa ká, mo sì nífẹ̀ẹ́ ọkọ mi bó tilẹ̀ jẹ́ pé alágbèrè pásítọ̀ ni"
- Wo ọnà tí olè gbà jàǹfàní ọkọ́ lọ́wọ́ ìjọba Eko kí ilẹ̀ ò í tó ṣú
- Ẹgbẹ́ Afenifere bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu Aárẹ Buhari lórí gbèńdéke tí Akeredolu fún àwọn darandaran Fulani




















