Deeper LifeHigh School fèsì lórí akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé wọn tí ìyá rẹ̀ ní àwọn olúkọ́ lù àti fipábálòpọ̀

Aworan ile ẹkọ DLHS

Oríṣun àwòrán, DLHS

Awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga Deeper Life High School ti fi sọ pe gbogbo eni ti igba iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori nitori ọrọ ọmọkunrin akẹkọọ kan ti wọn fiya jẹ lawọn yoo fimu rẹ danrin.

Ni ọsẹ to kọja ni obinrin kan figbe ta lori ayelujara pe awọn ọga ile iwe mu ọmọ oun lọ si aarin awọn akẹkọọ ti wọn si fi iya jẹ ẹ gidi.

Lara ohun to ni wọn fi ṣe ọmọ naa ni pe awọn kan n dẹyẹsi ti wọn si tun ti ika bọ nidi nitori pe o n tọọle.

Àkọlé fídíò, Leke Adeboye: Àwọn aláwáda tó fẹ́ irànlọ́wọ́ iléèwé
Àkọlé fídíò, Toríi "Coro", ẹ wo bí ètò ìsìn ìgbéyàwó orí ayélujára Zoom ṣe lọ
Àkọlé fídíò, Temitope Akinnusi: Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló takú láti gbà mí síṣẹ́ torí mo ní ojú kan

Iṣẹlẹ yi waye ni ilu Akwa Ibom ti arabinrin naa si ni oun ti sọ fun awọn olukọ rẹ ṣaaju pe ọmọ naa n tọ sile ti wọn si ni o tẹ awọn lorun.

Aworan atẹjade ile ẹkọ ile Ijọsin Deeper Life

Oríṣun àwòrán, DLHS

Ṣugbọn o ni ìyàlẹ́nu lo jẹ nigba ti ọga ile iwe gbe ọmọ naa kuro ni ositẹẹli rẹ lọ si aarin awọn to ju u lọ ti wọn si n ṣe iṣekuse pẹlu rẹ.

Ninu atẹjade ile iwe naa DLHS wọn salaye pe, idasile ile iwe naa ni lati fi ọrọ Ọlọ́run tọ awọn ọmọ ati lati jẹ eniyan to ni ibẹrun Ọlọrun.

Bakan naa lawọn alaṣẹ sọ pe iwadii n lọ lọwọ ati pe gbogbo eni ti igba ọrọ naa ba si mọ lori, awọn yoo fi imu rẹ danrin.

Wọn ni tori idi eyi, ki gbogbo ara ilu lo fi ọkan balẹ pe idajọ ododo ni awọn yoo ṣe

Ile ẹkọ Depper Life ni lọwọ lọwọ won ti ni ki ọga ile iwe naa lọ rọọkun nile nigba ti iwadii n tẹsiwaju.