Adult Bedwetting: Kí ló ń fa kí àgbàlagbà má a tọ̀ sí ilé?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aisan tabi ipenija lori ki agbalagba ma a tọ sile jẹ ọkan lara awọn aisan ọpọlọ ti o maa n ṣẹlẹ si awọn eniyan lawujọ.
Amọ, idẹyẹsini ti o maa n waye si awọn to ba ni iru ipenija yii kii jẹ ki wọn le ke gbajare sita tabi ki wọn lọ si ileewosan fun itọju.
Idẹyẹsi miran ni bi awọn araale ati ara adugbo ṣe n huwa si ẹni to ba ni ipenija yii nipa sisọ ọrọ ẹgan tabi huwa si wọn bi ẹni pe wọn kii ṣe eniyan ẹlẹran ara bii ti wọn.
- Wo bí èsì ìdìbò ìpínlẹ̀ Edo ṣe ń jáde
- Lẹ́yìn olóògbé Barrister àti Kollington, èmi làgbà kàn nínú iṣẹ́ orin Fuji- Obesere yarí
- Ọkọ̀ méjì jóná ráùráú níbi tí ọkọ̀ tó gbé bẹntiróò ti gbiná
- Wo bí ìfigagbágbá tani yòó di gómìnà Edo láàrin Obaseki àti Ize-Iyamu yóò ṣe lọ
- Yatọ̀ sí pé ó ṣe sọ́jà, tó tún jẹ́ ọkọ Oriṣabunmi, wo àwọn nkan tí o kò mọ̀ nípa Jimoh Aliu
Lati mọ ohun to n fa aisan yii, ileeṣẹ BBC ba Dokita onimọ iṣegun, Henry King to sọ ohun to n fa ipenija yii ati ọna ti a le gba ran ara wa lọwọ lati bori rẹ.
Ohun ti o sọ re e:
Aisan kokoro oju ara
Aisan kokoro oju ara, Urinary Track Infections ma n fa ki agbalagba ma a tọ sile ti wọn ko ba moju to o ni kiakia.
Bẹẹ si ni aisan kokoro oju ara yii le mu ki eniyan to si ara rẹ ni oru tabi ni ọsan paapaa pẹlu.
Isoro pẹlu ọpa ẹyin
Ẹni to ba ni iṣoro pẹlu ọpa ẹyin rẹ, Spine, o ṣeeṣe ko bẹrẹ si ni tọ si ara.
Aisan jejere
Bakan naa ni ẹni to ba ni aisan jẹjẹrẹ to ti tan ka gbogbo ara rẹ lee maa tọ si ara.
Ifiyajẹni lọna aitọ
O ṣeeṣẹ ki ẹni ti wọn ti fi iya jẹ̀ẹ lọna aitọ ma a tọ si ile.
Idi ni wi pe eni naa le fẹ gbagbe iya to jẹ ẹ nipa pipada si awọn iṣesi ti o maa n ṣe ni kekere.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn oloyinbo maa n pe ipenija yii ni Catatonic, eleyii ti o dabi ki eniyan pada si kekere.
Eleyii yoo mu wọn ma a tọ sile bii ọmọde.
Lilo oogun oloro tabi oti mimu
Dokita Henry King ni ẹnikẹni to ba n mu oti amupara ṣeeṣe ki o tọ sile.
Bakan naa ni awọn ọdọ to ba n lo oogun oloro naa le bẹrẹ si ni tọ si ara ati si ori ibusun wọn.

Ohun ti ẹni to ba n tọ sile ko gbọdọ ṣe;
- Ma sọ wi pe o ko ni mu omi nitori ati mase tọ sile, amọ ki ẹni naa ma a mu omi ni owurọ ati ọsan yatọ si aṣalẹ.
- Ẹ masẹ pa ara yin nitori ipenija yii.
- Ki awọn eniyan ye e pe wọn lorukọ mọ tabi dẹyẹsi wọn.
- Bakan naa ni Dokita King ni yoo ṣe wọn ni anfaani ti awọn eniyan ba ran wọn lọwọ nipa sisọrọ iwuri si wọn lai dẹyẹsi wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bawo ni awọn to ni ipenija titọsile ṣe le ran ara wọn lọwọ?
- Ohun akọkọ ni lati lọ si ile iwosan lati gba itọju
- Ki o to sun ni ale, ẹ kọkọ wẹ naa.
- Ẹ fi 'alarm' si ori ẹrọ ilewọ yin ti yoo ma ji yin ni wakati mẹta si ara wọn lati lọ ma a ṣe igbọnṣẹ tabi lọ tọ.
- Ẹ ṣọra fun ọti mimu nitori o ni caffeine ti o ni eroja to n jẹ diuretics to n mu ni tọ ni ọpọ igba.
- Ẹ mu ọkan kuro lori pe boya awọn eeyan a fi yin ṣe yẹyẹ ti ẹ ba ke gbajare sita lasiko.















