LASEMA Lagos: Ọkọ̀ méjì jóná ráùráú níbi tí ọkọ̀ tó gbé bẹntiróò ti gbiná

Ijamba ina

Ilẹeṣẹ to n risi ọrọ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA ti ni ọkọ meji lo jona raurau ni agbegbe Anthony lọ si Gbagada, nipinlẹ Eko lẹyin ti ijamba ọkọ waye.

Ọkọ agbepo nla ni ijanu ọkọ rẹ da iṣẹ silẹ to si yi danu le ori ọkọ meji ti awọn ọkọ naa si jona raurau lẹsẹkẹsẹ.

Ijamba ina

Ninu atẹjade ti Ajọ LASEMA fi lede ni wọn ti sọ wi pe ajọ naa tete de ibẹ lati pa ina naa ki o tọ fa ijamba miran ni ibi iṣẹlẹ naa.

LASEMA ni awọn ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ to n risi ijamba ina ni ipinlẹ Eko, LASG ati ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadii kunkun awọn ijamba ọkọ naa ṣe ipalara fun.

BBC

Bakan naa ni wọn fikun wi pe awọn ko le e sọ lọwọlọwọ iye eniyan to ba ijamba ọkọ naa lọ.

Amọ, wọn ni awọn doola ẹmi ati dukia awọn eniyan nigba ti wọn de ibẹ.