Anambra Killing: Ojú oorun ni ìyá àtàwọn ọmọ méjèèjì wà nígbà tí ọkùnrin náà fi àdá pa wọ́n

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Orisirisi iwa isekupani lo n waye ni Naijiria to kọja oye ọpọ eeyan.
Laipẹ yii la mu iroyin Kayeefi wa fun yin nipa iya kan to pa ọmọ bibi inu rẹ, to si fi pata sẹnu.
Iroyin kasiara miran to tun wa n tẹ wa lọwọ ni ti ọkùnrin kan, Emeka Ezimadu to sa ọmọ bibi inu rẹ meji ati iya to bi ni ada pa.
Ileesẹ ọlọpaa ẹkun Nnewi nipinlẹ Anambra, nigba to n fìdi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan ti oṣiṣẹ alukoro Haruna Muhammed fisita, salaye pe ọwọ oun ti tẹ ọkùnrin naa, tii ṣe ẹni ọdun mẹtadinlaadọta.
Atẹjade naa ni abule Okpuneze Uruagu nijọba ibilẹ Ariwa Nnewi nipinlẹ Anambra ni iṣẹlẹ laabi ọhun ti waye.
Atẹjade naa ni ko ye ẹnikẹni bi iṣẹlẹ naa ti waye nitori sadede ni ọkùnrin naa fa ada yọ, to si sa ọmọ rẹ meji, Ifechukwu ati Mmeso Ezimadu pa loju oorun.
Ileesẹ ọlọpaa ni ọmọ ọdun mẹsan ni Ifechukwu nigba ti Mmeso jẹ ọmọ ọdun meji.
Bakan naa nileesẹ ọlọpaa fikun pe, ọkùnrin naa tun fi ada sa iya to bi lọmọ, Agnes Ezimadu, tii ṣe ẹni ọdun marundinlaadọwa, ni ada pa lati oju oorun.
Ko tan sibẹ o, Ileesẹ ọlọpaa tun ni ọkùnrin naa tun fi sa ọmọ rẹ mẹta mii ni ada, eyi to da ọgbẹ nla si wọn lara.
Orúkọ awọn ọmọ mẹtẹẹta ti wọn fara gbọgbẹ ni Nonzo, ẹni ọdun mejila, Chinaemerem, ẹni ọdun mọkanla ati Ngozi, ọmọ ọdun mẹjọ.
Ileesẹ ọlọpaa ni oun ti gbe awọn ọmọ to fara gbọgbẹ naa lọ sile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju.
Bakan naa ni wọn ti gbe oku awọn alaisi lọ sibudo igbokusi fun ayẹwo to yẹ.












