Grace Oshiagwu: Afurasí ní abọ́ oúnjẹ kan, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náíra lòun ń gbà lóri àwọn tó pa l'Akinyele

Awọn afunrasi mejeeji

Oríṣun àwòrán, oyo nsight.com

Ọkan lara awọn afunrasi mẹta ti ọwọ ọlọpaa ba fun ipaniyan ọwọọwọ to n waye lagbegbe Akinyẹle nilu Ibadan, ni ipinlẹ Oyo ti sọrọ sita.

O ṣalaye pe abọ ounjẹ kan ati ẹẹdẹgbẹta naira ni oun n gba lori ọkọọkan awọn eeyan mẹfa to pa lagbegbe naa.

Laarin oṣu kan, ko din leeyan marun un, ninu eyi ti alaboyun kan ati awọn akẹkọọ meji wa, ti wọn ti ṣa pa lagbegbe ọhun.

Ni ọjọ Ẹti nileeṣẹ ọlọpaa fi oju awọn afurasi kan han lolu ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ to wa lagbegbe Ẹlẹyẹle.

Arakunrin ẹni ọdun mọkandinlogun naa ṣalaye pe babalawo kan ti o jẹ ẹni aadọta ọdun lo n ran oun ni iṣẹ ibi naa.

O fi kun un pe ni gbogbo igba ti oun ba ti fẹ jade lọ paniyan ni babalawo naa maa n fun oun ni oogun ati ajẹsara ibilẹ gbogbo pẹlu ọfọ ati ayajọ ti oun yoo pe lati di afẹẹri ni ibi ti oun ti fẹ lọ ṣe ọṣẹ naa.

Barakat Bello

Oríṣun àwòrán, other

O ni, "ohun eelo ibulẹ ṣọfẹli ni mo maa fi n pa awọn eeyan ti mo ba fẹ pa, maa si ka ayajọ naa si ori onitọhun ni kete ti mo ba ti rii ti ẹjẹ n jade lara rẹ"

O ni aṣẹ ti baba fun oun ni lati maa rin yi awọn agbegbe ti oku naa ba wa ka ki oun to kọ ẹyin si wọn.

Àkọlé fídíò, Ẹ wo adúrú ǹkan tí Softface ma ń tò pọ̀ láti sín àwọn òṣèré, gbajúgbajà jẹ

Afurasi naa ni ẹmi awọn eeyan naa yoo lọ ba babalawo ti o sọ pe o n ran oun yii, ṣugbọn ti baba ko si sọ idi ti o fẹ fi mu ki oun maa pa awọn eeyan naa.

Ati pe a maa ra ounjẹ fun oun yoo si tun fun oun ni ẹẹdẹgbẹta naira pẹlu.

Amọṣa, babalawo to n fẹsun kan naa ṣalaye pe irọ patapata lo n pa mọ oun.

O ni iṣẹ ni wọn mu u wa kọ lọdọ oun ti oun si ti kọkọ kọ ọ silẹ fun awọn iya rẹ to mu u wa ki oun to tun da ọrọ naa ro lati gba a si ẹkọṣẹ ifa ni ọdọ oun lọdun 2016.

Gẹgẹ bii kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Nwachukwu Ewonwu ṣe sọ, awọn afurasi naa ni wọn gbẹmi Barakat Bello ni ọjọ kinni oṣu kẹfa.

Nigba ti wọn pa Grace Oshiagwu ni ọjọ kẹtala, oṣu kẹfa, ti wọn si tun pa ọmọ ọdun marun un kan, Mojeed Tirimisiyu ni ọjọ kejilelogun, oṣu kẹfa ni agbegbe akinyẹle.

Àkọlé fídíò, Ọmọ Yahoo tú àṣírí ara rẹ̀ fún, bí wọ́n ṣe ń ṣe é BBC Yorùbá