Tolulope Arotile death: Afurasí tó wa ọkọ̀ pa Tolulope Arotile ti ń jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìgbìmọ̀pọ̀ ṣekúpani

Tolulope Arotile

Oríṣun àwòrán, NAF

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 15

Afurasi to wa ọkọ to pa Tolulọpẹ Arotilẹ, obinrin akọkọ ti yoo jẹ awabaluu ijagun lorilẹede Naijiria ti foju ba ile ẹjọ loni.

Ẹsun ti wọn n fi kan an da lori igbimọpọ ṣeku pani, ati igbimọpọ huwa ọdaran.

Amọṣa ẹsun mejeeji yii ko ni idajọ iku ninu.

Awọn afurasi meji yooku ti gba itusilẹ wọn.

Ni ọjọ kẹrinla, oṣu keje ọdun 2020 ni Arotilẹ ṣalapade iku ojiji ni ibudo awọn ọmọogun ofurufu to wa ni ilu Kaduna.

Iku rẹ si da jinnijinni bo ọpọlọpọ eeyan.

Ẹ̀gbọ́n àti àbúrò wà ní ilé ẹ̀jọ́ lórí ikú Tolulope Arotile

Tolulope Arotile

Oríṣun àwòrán, NAF

Ẹgbọn ati Aburo, Nehemiah ati David Adejo lo ti lọ kawọ pọnyin rojọ bayii o lori iku to pa obinrin akọkọ ologun to wa ọkọ baalu awọn ajagun ofurufu, Tolulope Arotile.

Ileẹjọ ibilẹ, magisreti to wa ni ipinlẹ Kaduna ni awọn mejeeji ti n jẹjọ ẹsun onigun-mẹrin to rọ mọ ipaniyan.

Nehemiah n jẹjọ wiwa ọkọ ni iwakuwa lai ṣe akiyesi, aini iwe awakọ gẹgẹ bi dirẹba, ati aigba aṣẹ lọwọ ọlọkọ ko to wa a.

David ni tirẹ n jẹjọ ẹsun aibikitita to fa ijamba si ohun ini ati eniyan.

Amọ, awọn mejeeji ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn ki kan wọn.

Agbẹjọrọ fun ijọba to fi ẹsun naa kan wọn, Martins Leo ni ki wọn ti Nehemiah mọ atimọle, ki iwadii fi pari lori ẹsun iṣekupa Tolulope Arotile ti wọn fi kan an.

Amọ, agbẹjọrọ awọn ti wọn fi ẹsun kan naa, Ibrahim Omachi, ni awọn mejeeji ti wa ni ọgba ẹwọn fun ọsẹ mẹrin ati wi pe igba akọkọ ni yii ti wọn yoo jẹjọ ẹsun kankan.

Tolulope Arotile

Oríṣun àwòrán, Others

Lẹyin ti Adajọ gbọ ẹjọ awọn agbẹjọrọ mejeeji, Adajọ Benjamin Hassan gba beeli wọn pẹlu miliọnu kan naira pẹlu onidurọ to n gbe ni agbegbe naa.

Adajọ ti sun igbẹjọ naa si Ọjọ Kẹrindinlogun ati ikarundinlọgbọn, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2020.

Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Kẹjọ ni Tolulope Arotilẹ jade laye lẹyin ti awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ lọ sile iwe girama pẹlu wọn ni Air Force Secondary School ni Kaduna, wa ọkọ pa a.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

'Kìí ṣe pé ìjánu Ọkọ̀ tó pa Tolulope Arotile já tàbí kò já, ìwádìí wà lọ́wọ́ ọlọ́pàá'

Nileeṣẹ ologun ofurufu to wa ni Kaduna ni gbogbo ọrọ yii ti ṣẹlẹ.

Ọgagun Ibikunle Daramọla to jẹ alukoro ileeṣẹ ologun ofurufu ni Naijiria ti kede bi wọn ṣe fa awọn mẹtẹẹta to wa ninu ọkọ to pa Tolulope Arotile le agbofinro lọwọ.

O ṣalaye ni kikun lori bi ijamba ọkọ naa ṣe waye nigba ti o n fa abajade wọn le Ogagaun Hadi Ahmed to jẹ Commander 453 Base Services Grioup (453 BSG) ni Kaduna.

Lọjọ kerinla, oṣu keje ni irọlẹ bii aago mẹrin abo ni iṣẹlẹ buruku yii ṣẹlẹ.

Ọkọ Sienna to ni nọmba AZ 478 MKA (Kaduna) ni Adejoh wa to si kọlu Tolulope lasiko to n rin ni opopona Air Marshal Ibrahim Alfa ní NAF Base ni Kaduna ko to di pe ẹlẹmii gbaa.

Bi àwọn kan ṣe n bè[rè pé abi ijanu ọkọ ti awọn ọmọ ile iwe Tolulope wa ja ni naa ni awọn miran ni ko ri bẹẹ nitori pe ohun to daju ni pe kii ṣe pe ijanu ọkọ Sienna naa ja rara.

Ko si ẹni to ri oogun iku ṣe lọjọ ti ọlọjọ ba de ni

Tolulope Arotile

Oríṣun àwòrán, NAF

Iléeṣẹ́ ológun òfurufú Nàìjíríà fa àwọn mẹ́ta tí ọwọ́ tẹ̀ lórí ikú Tolulope Arotile lé Ọlọ́pàá lọ́wọ́

Iléeṣẹ́ ológun òfúrufú àti ẹbí Tolulope Arotile ti ṣe ètò ìdágbére ìkẹyìn fun-un.

Pẹlu omije loju ọpọ eniyan ni ọdọmọde ajagun ọmọ ogun ofurufu ni, Tolulọpẹ Arotilẹ wọ kaa ilẹ lọ lọjọbọ ni itẹ isinku awọn akọni loju ogun ni ile Abuja.

Tolulope Arotile

Oríṣun àwòrán, @NigAirforce

Ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu ti fa awọn mẹta to wa ninu ọkọ to pa Tolulọpẹ Arotile le awọn agbofinro lọwọ bayii.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu fi sita bayii ni wọn ti kede pe igbesẹ yii di dandan lasiko yii.

Ogagun Ibikunle Daramola to jẹ alukoro ileeṣẹ yii ni Nehemiah Adejoh, Igbekele Folorunsho ati Festus Gbayegun lo wa ninu ọkọ ti o pa Tolulọpẹ Arotile.

Ileeṣẹ ologun ofurufu ni Naijiria ni ọrọ gbogbo wa lọwọ awọn agbofinro bayii lati ṣe ohun to tọ lẹyin iwadii gbogbo.

Tolulope Arotile

Oríṣun àwòrán, NAF

Ogagaun agba naa ṣalaye pe awọn mẹtẹẹta ti wọn fa le agbofinro lọwọ yii jẹ awọn ti Tolulope lọ sile iwe girama pẹlu wọn ni Air Force Secondary School ni Kaduna.

Ati pe awọn mẹtẹẹta fẹ lọ ki iyawo ọga wọn ninu ọgba ologun naa ni lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Tolulope Arotile

Oríṣun àwòrán, NAF

Tolulope wo kaa ile

Wo bí ètò ìsìnkú Tolulope Arotile ṣe lọ nílùú Abuja

Báyìí ni ètò ìsìnkú ọmọ ogun òfurufú náà ṣe lọ ní ìlú Abuja

Eto ayẹyẹ ikẹyin ati isinku awakọ-ofurufu jagun obinrin akọkọ ni Naijiria, Tolulope Arotile, ti lọ nilu Abuja.

Ko si ẹni ti ko nii ku.....

Tolulope Arotile lo ti wọ iyara ikẹyin ni itẹ́ awọn ologun ni Abuja laarọ yii.

Tolulope Arotile

Opolopo awọn ero lo ya wa fun Tolulope Arotile ni ẹyẹ ikẹyin lasiko eto isinku rẹ lai yọ awọn Oluṣọagutan silẹ.

Tolulope Arotile

Pẹlu orin. ilu ati agogo lai yọ ohun gooro pipe iṣẹ ni ilana ti ologun ni wọn fi sin Tolulope Arotilẹ de itẹ ikẹyin rẹ.

Oku Tolulope Arotile

Ọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2020 ni Tolulope kú, lẹyin ti ẹnikan fi ọkọ gba a ninu ọgba ileeṣẹ ologun naa nilu Kaduna.

Awọn ọmọ ologun nibi isinku

Ilẹ isinku apapọ fun awọn ọmọ ologun to wa nilu Abuja ni eto isinku naa ti waye.

Ni nkan bi aago mẹwaa owurọ Ọjọbọ ni eto isinku naa bẹrẹ.

Ẹ wo bi eto isinku naa ṣe lọ ninu fidio yii:

Skip Facebook post, 1

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 1

Lara awọn to si kopa nibẹ ni gomina ipinlẹ Kogi, to jẹ ilẹ abinibi Tolulope, Yahaya Bello.

Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello naa kopa nibi eto isinku naa.
Àkọlé àwòrán, Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello naa kopa nibi eto isinku naa.

Ibẹrẹ ọsẹ yii ni awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun ofurufu fi orukọ ẹni to fi ọkọ gba Tolulope sita.

Awọn ẹbi oloogbe

Tilu tifọn pẹlu awọn orin onigbagbọ nibi eto isinku ọmọ lẹyin Kristi ati tologun ni wọn kọ nibi eto isinku akọni obinrin naa.

Awọn ọga ologun

Tolulope Arotile: Wo àbájáde ìwaádìí iléeṣẹ́ ológun òfúrufú lórí ikú awakọ̀-òfúrufú jagun obìnrin àkọ́kọ́ ní Naijiria

Wọn ni awakọ ọhun, Nehemiah Adejoh ko ni iwe aṣẹ lati wa ọkọ loju popo.

Lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, Tolulope n lọ si ọja Mammy ninu ọgba ileeṣẹ naa to wa ni Kaduna ni nkan bi aago mẹrin abọ irọlẹ ko to pade awọn akẹgbẹ tẹlẹ nile ileeṣẹ ologun, Air Force Comprehensive School.

Awọn akẹgbẹ rẹ ọhun, Nehemiah Adejoh, Igbekele Folorunsho ati Festus Gbayegun wa ọkọ ayọkẹlẹ Kia Sorento to ni nọmba idanimọ AZ 478 MKA kọja lẹgbẹ rẹ.

Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ologun ofurufu sọ, igba ti Adejoh n wa ọkọ naa pada sẹyin lati ki Tolulope lo kọlu u, eyi to yọri si iku rẹ.

Àkọlé fídíò, Black women live matters: Ọdún 2015 ní àwọn ọlọ́pàá pa India Kager láìní ìdí- Gina Best

Iwadii fi han pe Adejoh ti wọn fẹsun kan pe o ṣekupa Tolulope kii ṣe jagunjagun.

Ileeṣẹ ologun ofurufu Naijiria ti sọ abajade iwadii rẹ lori iku to pa awakọ-ofurufu jagun obinrin akọkọ ni Naijiria, Tolulope Arotile.

Tolulope Arotile

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Airforce

Ileeṣẹ naa sọ nibi ipade oniroyin kan nilu Abuja pe iwadii ti wọn ṣe fihan pe Arotile ku nitori ọkọ to kọlu u lojiji ati pe o padanu ẹjẹ to pọ lẹyin iṣelẹ naa.

Ileeṣẹ naa wa sọ pe ọrọ naa kii ṣe eyi ti ileeṣẹ ologun le sedajọ rẹ, nitori naa ni wọn ṣe faa le ileeṣẹ ọlọpa lọwọ lati gbe ẹni to fi ọkọ gba Arotile lọ sile ẹjọ.

Ipade oniroyin naa lo waye lẹyin ti awọn ọmọ Naijiria kan n bere pe ki ijọba ṣe iwadii kikun lori iku jagun jagun na.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun 2020 ni Arotile jade laye ninu ọgba ileeṣẹ ologun ofurufu to wa ni Kaduna.

Ọpọ eeyan lo si ti bẹrẹ si n woye bi ọrọ iku naa ṣe jẹ lẹyin ti akẹgbẹ rẹ nigba kan nileewe girama fi ọkọ gba a, to si gbabẹ dero ọrun.

Ki lo ti ṣelẹ sẹyin?

Tolulope Arotile: Lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ ni awakọ̀-òfurufú jagun yóò wọ káà ilẹ̀ lọ l'Abuja

Tolulope Arotile

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Airforce

Ileeṣẹ ologun ofurufu ti kede pe Ọjọbọ ọsẹ to n bọ tii ṣe ọjọ kẹtalelogun oṣu keje ni awakọ-ofurufu jagun, Tolulope Arotile yoo wọ kaa ilẹ lọ.

Lọjọ ẹti ni ileeṣẹ ologun ofurufu kede ọrọ naa loju opo Facebook rẹ.

Skip Facebook post, 2

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 2

Ọjọ kẹrinla oṣu keje ọdun 2020 yii ni akọni awakọ-ofurufu jagun Tolu ṣagbako iku ojiji ninu ijamba ọkọ niluu Kaduna.

Ayẹyẹ ti wọn maa n ṣe fawọn ologun ni wọn yoo ṣe fun oloogbe Tolulọpe ẹni ọdun mẹrinlelogun.

Ni Mọsuari ileeṣẹ ologun to wa niluu Abuja ni wọn yoo sin Tolu si.

Ẹbí Tolulope Arotilẹ ń bèrè fún iwadii lórí ìkú tó pa á!

Ẹbi Arabinrin Tolulope Arotile ti ni wọn gbọdọ ṣe iwadii iku to pa ọmọbinrin akọkọ ti yoo wa ọkọ ẹlikọpta awọn ọmọogun ofurufu ni Naijiria.

Ẹgbọn Tolulope, Damilola Adegboye ni awọn ko gba iroyin pe ọkọ to rin wa ṣẹyin lo pa a.

Tolulope Arotile

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Airforce

Adegboye ni awọn fẹ ki ikọ ọmọogun Naijiria ṣe iwadii finifini nitori ki awọn le gba wi pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye.

O ni ọjọ ti oloogbe naa ku, awọn jọ wa ninu yara ni ni ibi ti o sun si, ki o to di pe o gba ipe lori ẹrọ rẹ, ti o si dide.

‘Mo gbo ti o gba ipe lori ẹrọ ilewọ rẹ, pẹlu bi o ṣe sọrọ, o fihan pe ọga rẹ kan lo pe e lati wa si ile igbe awọn ajagun(Airforce base).

‘Amọ, Tolulope rora lati dide, ni mo ṣe pinnu lati gbe e lọ si ibẹ.’

‘Wakati kan lẹyin rẹ ni mọ gbọ pe nkan buruku ti ṣẹlẹ si. ’

‘Mi o le gbagbọ pe ẹni ti mo gbe lọ ni wakati kan ṣẹyin ti ku.’

Bakan naa ni iya Tolulope ṣe apẹjuwe ọmọ rẹ gẹgẹ bi ẹni ti o fẹran lati gbadura ati awe.

Tolulope

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Airforce

A fura pé ejò lọ́wọ́ nínú ikú Tolu Arotile, ẹ ṣe ìwádìí ikú rẹ̀ - Afenifere, Gani Adams, Huriwa

Yoruba ni bi ọrọ ba ru ni loju, a bi ilẹ leere ni.

Eyi si lo mu ki awọn eeyan kan maa pe fun iwadi lori iku to pa obinrin ologun akọkọ ti yoo wa baalu ni Naijiria, Tolulope Arotile.

Aarọ Ọjọru ni ariwo ta pe ọkọ ọrẹ Tolulope kan lo sadede kọ lu ọmọbinrin naa, nigba to n tara lati ki i.

Amọ nigba ti wọn n tara lori iku ọmọbinrin naa, akọwe fun ẹgbẹ Afenifere, Yinka Odumakin pẹlu Aarẹ ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Gani Adams ati ẹgbẹ onkọwe to jẹ ajafẹtọ ẹni, Huriwa ni ọrọ iku Tolulope naa mu ifura lọwọ.

Atẹjade kan ti ẹgbẹ Afenifere fisita ni awọn alaye ti wọn n ṣe nipa iku to pa awakọ baalu ologun naa tako ara wọn, to si nilo ẹkunrẹrẹ iwadii.

"Ki lo de to jẹ pe ẹnikan ti iṣẹlẹ naa soju rẹ lo tu asiri pe ọrẹ rẹ atijọ kan lo fi ọkọ kọlu ọmọbìnrin naa, amọ tile iṣẹ ologun ofurufu kan kede iku rẹ lasan, lai salaye ọna to gba ku fun araye."

Aarẹ Gani Adams, ninu atẹjade kan to fisita lati ba mọlẹbi Arotile kẹdun, wa kesi gbogbo awujọ agbaye lati tanna wadi ohun to ṣe okunfa iku ojiji fun obinrin naa nitori o mu ifura lọwọ.

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....

" Bawo ni ọkọ to n fi ẹyin rin yoo kan ṣe pa ọmọ ologo bayii ninu ọgba ologun? Ta lo wa ọkọ ọhun? Ki ni orukọ rẹ, nibo si ni onitọun wa lọwọ lọwọ?"

Aarẹ Gani Adams ni ọpọ ibeere lo n ru jade lati ipasẹ iku ojiji to pa Arotile, ti ko tii si idahun fun rara.

Ẹgbẹ onkọwe ajafẹtọ ẹni HURIWA n tiẹ n kesi ile asofin apapọ ilẹ wa lati tọpinpin awọn iṣẹlẹ to rọ mọ iku Tolulope Arotile.

Huriwa ni bii igba ti wọn n pa Aalọ lasan ni wọn ṣe tu ọfọ iku akọni obinrin naa, eyi ti ko tẹ ọpọ ọmọ Naijiria lọrun.

Gbogbo awọn eeyan yii wa ba mọlẹbi Tolulope kẹdun, ti wọn si gbadura pe Ọba oke yoo fun wọn ni ọkan akin lati gba adanu nla naa mọra.

Tolulope Arotile: Ẹ wo ọgbọ́n tí wọ́n lò láti túfọ̀ ikú Tolu fún bàbá àti ìyá rẹ̀

'Lẹ́yìn wákàtí mẹ́rin tí mo bá Tolulope sọ̀rọ̀ ni mo gbọ́ pé ó ti wà ní ilé ìgbókùú sí'

Awọn obi ọmọ ogun oju ofurufu Naijiria to kú laipẹ yii, Tolulope Arotile, ti sọ pe iku rẹ ju ibanujẹ lọ fun awọn.

"Ní kékere, Tolulope rí ọkọ̀ bàálù kékeré kan ó sì sọ fún mi pé lọ́jọ́ kan, òun á wa bàálù yẹn mo si ṣe Amin nla".

Arotile

Oríṣun àwòrán, Arotile

Lasiko to n ba àwọn akọroyin sọrọ, baba rẹ, Onimọ ẹ̀rọ Akintunde Arotile, sọ pe oun ba ọmọ òun sọrọ ni ọsan ọjọ to kú, ki oun to pada gbọ iroyin ikú rẹ.

"Mo pe e ni nkan bi aago kan ọsan ọjọ naa lati ki i, nitori pe o ṣẹṣẹ dee lati ipinlẹ Katsina pada si Kaduna, nibi ti wọn ti lọ kọjú ija si awọn agbebọn ni.

Amojuẹrọ Arotilẹ ni ọdọ akọbi ọmọ awọn obinrin ni Tolulope n gbe Ni Kaduna.

"O sọ fun mi pe oun n sinmi lọwọ, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun mi pe o ti di eero mọsuari nigba ti yoo fi di aago marun irọlẹ."

Ni nkan bii ago marun, eeyan kan pe mi pe ṣe mo ti gburo rẹ, mo si ni bẹẹ ni, lo ba ni ki n tun un pe mo si ṣe bẹẹ ṣugbọn mi o gbọ esi".

"Mo ba pe awọn akẹgbẹ rẹ lẹnu iṣẹ, gbogbo wọn n sọkun - kii lode, wọn o dahun, ẹkun ni wọn n sun. Mo ba tun pe ọga wọn lẹnu iṣẹ...Haaa!

"O sọ fun mi pe ọmọ mi ti wa ni Mọ́ṣúárì"

Tolulope

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Airforce

Baba rẹ ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi ọlọpọlọ pipe ati akikanju ọmọ, to si jẹ pe lati igba to wa ni èwe lo ti ni afojusun lati di ọmọ ogun oju ofurufu.

"Mo ni lati wa ọkọ funraami lati Abuja lọ si Lokoja lati lọ sọ fun iya rẹ tori iru ọr yii ko ṣee sọ lorii foonu".

Baba Tolu ni nigba ti oun de ile, iya rẹ lọ gbadura lori oke.

Àkọlé fídíò, Funmi Adewara: Tele Medicine' ní a fi ń ṣàyẹ̀wò èèyàn ìdá ọgọtá láti dènà ìtànkálẹ̀ Covid

'Ọkọ̀ ọ̀rẹ́ àtijọ́ rẹ̀ kan tó fẹ́ tàdímẹ́yìn láti kì í, ló kọ lù ú tó pa á'

'Tolu rín ẹ̀rín múṣẹ́ kí ẹ̀mí tó bọ́ lára rẹ̀'

Ọmọluabi ni Tolu, ẹni to sun mọ Ọlọrun lo jẹ, ọmọ to mu inu obi, ara, ọrẹ ati gbogbo eeyan dun si ni o jẹ.

Ọrẹ awakọ ofurufu jagun to padanu ẹmi rẹ ninu ijamba niluu Kaduna lo sọ bẹẹ nipa ọmọ ọdun mẹrinlelogun to di oloogbe.

Ọrẹ Tolu to sọ fun BBC Yoruba pe oun ko fẹ darukọ oun ṣalaye pe ọrẹ Tolu nileewe girama lo ri i loju titi, nibi ti ọrẹ rẹ ọun ti n rifaasi sẹyin pẹlu ọkọ lo ti kọlu Tolu.

Wọn gbe Tolu digbadigba lọ si ile iwosan ṣugbọn ọwọ ti bọ sori, ẹlẹmi ti gba a.

Ọrẹ Tolu sọ pe, ti a ba sọrọ iwe mimọ, Tolu ko gba ipo mii ri yatọ si ipo kinni.

O ni ko si ohun ti ẹnikan le ṣe mọ bayii ju ki wọn maa adupẹ lọwọ Ọlọrun lọ nitori igbe aye ti Tolu gbe.

Tolulope Arotile

Oríṣun àwòrán, NAF/Twitter

Ọrẹ Tolu ni kii gbohun soke ti o ba ẹnikẹni n sọrọ, jẹjẹ rẹ ni o maa n lọ.

O fikun ọrọ rẹ pe Tolu ko banu jẹ nigba to fẹ ku, o ni ẹrin wa loju Tolu nigba ti o dakẹ.

'Mo máa ń ta sí Tolu pé "ọjọ́ wo ni wàá tó gà'- Musa, Ọ̀rẹ́ àti kékeré

'Mó sábà maa ń fi Tolu ṣe yẹ̀yẹ́ nítori bi ó ṣe kúrú'

Ọ̀kàn nínú àwọn ọ̀rẹ́ Tolu ti wọ́n jọ lọ si ilé iwé ti wọ́n si tún jọ kọ ẹ̀kọ́ ojú omi ni ilé iṣẹ́ ọmọogun afẹ́fẹ́ Muhammed Musa ló sàlàyé fun BBC pé ǹkan ìbànújẹ́ gbáà ni ikú tó Tolu jẹ́.

O ní ọjọ́ ìwájú rẹ̀ nínú iṣẹ́ ọmọ ogun dára gidi sùgbọ́n ikú ṣi lọ́wọ́ iṣẹ́..

Ilé iwé kan náà ni Musa àti Tolu jọ lọ, ìyẹn ilé iwé alákọbẹ̀rẹ̀ Nigeria Airforce ní ìlú Kaduna ti wọn sì ti n ṣe ọ̀rẹ́ láti ìgbà náà titi wọ́n fi dàgbà, Tolu gbà láti ṣe iṣẹ́ ọmọ ogun ofurufu nígbà ti Musa lọ fún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Chemistry ni fasiti Uthman Dan fodio ni Sokoto, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ wan kò yà títí di ọjọ́ ikú.

" Ikú Tolu jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn fún mi, o ní ọjọ́ iwáju tó dára nínú iṣẹ́ tó yàn láàyò, ó jẹ́ ọmọ tó ṣe ṣamu-ṣámú láti ìgbà tí a ti wà nílé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. ó ni àfojúsùn, ó sì níwà.

" Mó máá ń fi bí o ṣe kúrú ṣe yẹ̀yẹ́, ní àìpẹ́ yìí ti a fi àtẹ̀jíṣẹ́ rànṣẹ́ si ara wa, mo ṣì fí ṣe yẹ̀yẹ́ pé ṣe o ti ga síi, o fi fèsì pé dúró di ìgbà ti o bá rí mi."

Músá ni ọ̀rọ̀ ti àwọn sọ kẹ́yìn ni ìgbà tí òun kọ apìlẹ kan nípa ààrùn Coronavirus ni Kano ti Tolu si fẹesi si ǹkan ti òun kọ.

O ní lati ìgbà ti àwọn ti wà ní ilé ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ ni Tolu ti fi hàn pé òun fẹ́ràn iṣẹ́ ọmọogun ojú òfurufú, ti ó si lọ si girama ọmọ ojú òfurufú bákan náà"

Musa gbadúrà pé ki ọlọrun dẹlẹ̀ fún Tolu ki o sì ran ẹbí rẹ̀ lọ́wọ́ ni àsìkò ìnira yìí.

Ohun táa wádìí nípa Tolulope Arotile, Ajagun-wakọ̀ òfurufú tó d'olóògbé lẹ́ni ọdún 24

Tolulope

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigerian Airforce

O fẹrẹẹ sunmọ oru ọjọ iṣẹgun ọjọ kẹrinla oṣu keje ọdun 2020 ti ileeṣẹ ogun oju ofurufu Naijiria tufọ iku ọdọbinrin Tolulope Arotile.

Fun gbogbo ileeṣẹ ogun ofurufu Naijiria, iku to wọ ni lara, kan ni leegun ni iru iku to mu Ajagun-wakọ ofurufu Tolulope lo.

Ohun mẹwaa taa mọ nipa oloogbe naa ree:

  • Ọmọ bibi ipinlẹ Kogi ni Tolulope ni agbegbe Iffe ni ijọba ibilẹ Ijumu ni ipinlẹ Kogi.
  • Tolulope dagaba ni ilu Kaduna nibi to ti bẹrẹ irinajo rẹ sinu iṣẹ ọmọ ogun ni ileewe alakọbẹrẹ ti awọn ologun ofurufu ni Kaduna to si tẹsiwaju lọ ileewe girama awọn ologun ofurufu bakan naa. Lẹyin eyi, o dara pọ mọ ikọ afara jọ ologun CADET lati ṣaa fihan pe gbogbo ọkan oun, ọdọ awọn ologun lo wa.
  • Tolulope ṣẹṣẹ pari akanṣe ẹkọ to lọ kọ ni Starlite International Training Academy, ni orilẹede South Africa to si jẹ akẹkọ to fakọyọ ju.
  • Tolulope tun kẹkọgboye gẹgẹ bii akẹkọọ imọ ogun ofurufu to fakọyọ ju nileewe giga tawọn ologun ofurufu lọdun 2017. Ko tii pe ọdun kan ti o gba Ami ẹyẹ akọkọ gẹgẹ bi Ajagun-wakọ obinrin akọkọ ti ikọ ọmọogun Naijiria, ti o fi fi aye silẹ.
Tolulope

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Airforce

  • Wọ́n ṣe iburawọle fun un gẹgẹ bi Ajagun oju ofurufu ninu oṣu kẹsan ọdun 2017 oun si lo jẹ Obìnrin àkọ́kọ́ tò wa ẹlikọpita Iléesẹ́ ọmọogun òfúrufú Naijiria.
  • Gẹgẹ bi ileeṣẹ ologun ṣe fi atẹjade kan sita, , o kopa pataki ninu kikoju awọn adigunjale ni iha aarin gbungbun orilẹede Naijiria labẹ akoso ikọ "Operation Gama Aiki" ni Minna, ipinlẹ Niger.
  • Lọdun 2019 ni ileeṣẹ ogun oju ofurufu ṣẹṣẹ fi ami ẹyẹ da Tolulope Arotile lọla gẹgẹ bi Ajagun-awakọ ofurufu obinrin akọkọ ti wọn ni.
  • Ọga awọn ọmọ ogun ofurufu, Ọgagun Sadik Abubakar, Minisita fun ọrọ awọn obinrin ati idagbasoke awujọ, Dame Paulline Tallen ati ologun obinrin kan, Grace Garba lo mura ẹyẹ fun un lọjọ naa.
  • Ajagun-wakọ Tolulope Arotile jẹ apọn, ko tii fẹ ọkọ ko to di ọj to ku lọjọ iṣẹgun ọjọ kẹrinla oṣu keje ọdun 2020.
  • Ẹni ọdun merinlelogun ni Tolulope lasiko to dagbere fun aye.

Ikú dóró! Kí ló pa obìnrin àkọ́kọ́ tí ó wa ẹlikọ́pítà Iléesẹ́ ọmọogun òfúrufú ní Nàìjíríà?

Ikọ Ọmọogun orilẹede Naijiria lo fi lede pe ijamba ọkọ to waye ninu ile igbe awọn ikọ ọmọogun Naijiria lo ṣekupa a.

Skip Facebook post, 3

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 3

Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni Adari ikọ ọmọogun ofurufu Naijiria, Ọgagun Sadique Abubakar ni iku arabinrin naa jẹ manigbagbe.

Tolulope

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigerian Airforce

Wọn fikun pe ori ti o fi gba lasiko ti ijamba ọkọ naa waye lo fa iku rẹ.

Arotile ti o wa lati agbegbe Iffe ni ijọba ibilẹ Ijumu ni ipinlẹ Kogi, lo ṣẹṣẹ pari akanṣe ẹkọ to lọ kọ ni Starlite International Training Academy, ni South Africa.

Tolulope

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Airforce

Amọ, ko i tii pe ọdun kan ti o gba Ami ẹyẹ akọkọ gẹgẹ bi Ajagun obinrin akọkọ ti ikọ ọmọgun Naijiria, ti o fi fi aye silẹ.

Kí ló ṣẹlẹ̀ tí àwọn ọmọogun Nàìjíríà tó lé ní 350 fẹ́ kọ̀we fi iṣẹ́ sílẹ̀?

Iroyin to n ja rain lori ayelujara ni pe o ṣeeṣe ki awọn ọmọogun ikọ Naijiria to le ni ọọdunrunlelaadọta(350) kọ iwe fi ipo wọn silẹ.

Iroyin naa ni aisan owo oṣu wọn deede ati aisi ohun ijagun fun awọn ọmọ ọmọgun naa wa lara idi ti wọn fi fẹ fi iṣẹ silẹ.

Boko Haram

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajafẹtọ ọmọniyan ati onimọ ijinlẹ nipa ik Boko Haram, Bulama Bukarti sọ fun BBC pe awọn ọmọogun miran tilẹ wa ni ibẹ ti wọn fẹ fi oju ogun silẹ, amọ ti wọn ko tii gba fun wọn.

Amọ, Ikọ ọmọogun orilẹede Naijiria fi si oju opo Twitter wọn wi pe ko si otitọ ninu iroyin to sọ wi pe awọn ọmọogun naa ti fi ipo silẹ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ki o to di asiko yii, iroyin sọ wi pe adari ikọ awọn ọmọogun Naijiria kii jẹ ki awọn ọmọogun Naijiria fẹyinti lai ti to asiko.

Igba miran, wọn ni wọn ma n fi ẹsun kan wọn pe wọn n ṣe ojo ni oju ogun, abi wọn fẹ tu aṣiri ikọ ọmọogun Naijiria.

Ẹwẹ, niṣe lawọn ọm Naijiria to fi mọ awọn to n gbe lẹyin awọn ologun yii fun gbogbo ohun ti wọn n la kọja tu sori ayelujara lati wu aworan iwe ti ileeṣ ologun fi sita fun orukọ awn to fẹ fi silẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ni ọpọ igba ni ikọ ọmọogun Naijiria ma n fi lede wi pe awọn ti ṣẹgun ikọ Boko Haram ti awọn si ti rẹyin wọn.

Amọ, ikọ Boko Haram naa ṣi n ṣọṣẹ ti wọn si n pa awọn araalu ati awọn ọmọgun Naijiria.

Ni ọsẹ to kọja, ọmọogun ikọ Naijiria to le ni ọgbọn ni awọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram fi ẹmi wọn sọfo, lẹyin ti wọn wa sigun ba wọn ni ibi ti wọn wa.