CAMA 2020: Falana, SERAP ní CAMA ni òfin tó tíì burú jùlọ nínú ìtàn Nàíjíríà

Ọmọlẹyin Kristi ati awọn musulumi to n gbadura

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọrọ ko tii tan lori ofin ti yoo maa se akoso awọn ileesẹ atawọn ajọ to rọ mọ ti ijọba sẹsẹ gbe jade.

Ofin naa ti adape rẹ n jẹ CAMA, si lo fun awọn asoju ijọba lagbara lati gba akoso awọn ile ijọsin, ki wọn si yọ igbimọ oludari ibẹ lai lọwọ ile ẹjọ ninu.

Akọtun awuyewuye to tun waye lori ọrọ naa ni bi agba amofin Femi Falana se se atupalẹ ofin ọhun, to si ni wọn ko kọ ofin naa daada rara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Mo ti ka ofin naa, wọn ko gbe kalẹ lọna to dara nitori ijọba to ba n san na bi eto idalesẹ silẹ yoo se rọrun, ko ni gbe ofin mẹrinlelẹgbẹta kalẹ lori agbekalẹ ileesẹ aje."

Amofin Femi Falana

Oríṣun àwòrán, Others

Falana fikun pe awọn ofin ti ijọba gbe sita naa kii se tuntun, amọ ohun to yẹ ka tako ninu ofin ọhun ni bi ijọba se fun ajọ rẹ kan lagbara lati gba akoso awọn ileesẹ ti kii ba se tijọba, ti wọn ba kẹẹfin iwa sise magomago nibẹ.

Nigba toun naa n sọ ero rẹ lori ofin yii, ajọ to n dena iwa kotọ ni Naijiria, SERAP ni abala ogoji ninu ofin naa lo n tako ẹtọ ọmọniyan nipa ominira ibakẹgbẹpọ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

SERAP ni "Abala ti ko tọ rara ninu ofin naa ni agbara ti ijọba gbe fun ajọ CAMA lati maa dari awọn ileesẹ ti kii se tijọba naa."

SERAP ni ofin CAMA ni ofin ijẹgaba le ni lori to tii buru julọ ninu itan orilẹede Naijiria, eyi ti wọn yoo tun lo lati tẹ ẹtọ araalu loju mọlẹ.

Bẹẹ ba gbagbe, asaaju ijọ Living Spring, David Oyedepo ti kọkọ koro oju si ofin CAMA naa, ti ijọba si fesi pada fun pe o gbọdọ tẹle ofin Naijiria dandan ni.

Ìpàkọ́ kò gbọ́ sùtì ní ọ̀rọ̀ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń bú mi- Oyedepo

David Oyedepo

Adari ijọ Living Faith Church Worldwide ti ọ̀pọ̀ n pe ni Winners' Chapel, Bisọ̀ọ̀bù agba David Oyedepo ti fun awọn to n bu u lesi pe ko kan oun.

O ni ipakọ ko gbọ́ suti nitori ori ẹ̀lẹ́gan lo ba jẹ.

O ni ninu ariwo ni ijọ Olorun ti n dagba sii nitori pe ariwo ọja ni gbogbo ohun to n sẹlẹ yii.

Bisọ́ọbu ni koda laipe ni ijọ Winners tun da ẹ̀ka okoo le ni ẹẹdẹgbẹta silẹ̀.

Saaju ni Aare Buhari ti buwọlu ofin tuntun lọjọ keje, osu yii nipa abadofin Companines and Allied Matters 2020 ni eyi ti ijọba fi paarọ 1990 CAMA.

Ninu iwaasu ti Bisọọbu Oyedepo se nile ijọsin re lọjọ Isẹgun to pe ni: Titayọ kọja gbedeke ni eyi ti wọn gbe sita lori ayelujara ijọ naa lo ti fesi.

Oyedepo ni ẹ̀rín ni toun lọ́jọ́ gbogbo ati pe ti oun ba waasu ti ko mu ayọ̀ ati ẹ̀rin da ni pe ki awọn eeyan ma gbọ́ oun.

Bisoobu ni lati odun 1976 ni oun ti n rẹrin lati igba ti oun ti sawari ẹ̀sẹ̀ Bibeli Mathew 6: 33 ni eyi to si oju oun si fifi satani se yẹ̀yẹ̀ ki oun si maa rẹrin bi oun se n sin Olorun.

O ni koda, ti o ba bu mi, inu mi maa n dun sii ni nitori n ko ni dẹkun lilọ si ibi isẹ nitori pe o bu mi, gbogbo ẹya ara mi ti awọn eeyan le fi se yẹ̀yẹ̀ lo tẹ́ mi lọ́rùn ni mo si n dupẹ́ fun.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Ki lo kọkọ sẹlẹ?

Oyedepo àti ìjọba ń tahùn síra lórí bí ìjọba ṣe ń gba àkóso àwọn ilé ìjọsìn

Ìjọba àpapọ̀ ní kó lọ dá orilẹ̀èdè tiẹ̀ sílẹ̀, bí kò bá ní tẹ̀ lé òfin

David Oyedepo

Oríṣun àwòrán, @DavidOyedepoMin

Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ aarẹ Muhammadu Buhari Lauretta Onchie ti bẹnu atẹ lu ọrọ kan ti oludasilẹ ati adari ijọ Winners Chapel, Bisọọbu David Oyedepo sọ, lori ofin tuntun ti ijọba gbe kalẹ fun awọn ijọ.

Ofin CAMA naa to ti wa nilẹ tẹlẹ, sugbọn ti wọn ṣẹṣẹ ṣe afikun rẹ, ti o si kan awọn ijọ nlanla lo fa gbọnmisi omi o to laarin adari ijọ ọhun ati agbẹnusọ aarẹ Buhari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ofin naa sọ pe, awọn ile ijọsin lẹyin iforukọ silẹ pẹlu CAC ati ile isẹ to wa fun amojuto rẹ, ni ijọba maa ṣe akoso wọn.

Bakan naa, ile iṣẹ ijọba to n ṣe amojuto yii naa le yọ alaga igbimọ ijọ to ba se aṣemaṣe, to si tun ni agbara lati yan ẹlomiran dipo.

Afikun ofin yin lo fa ibinu yọ, ti Bisọọbu fi fesi pe:

Oyedepo ni: "Ohun ini Ọlọrun ni ijọ jẹ lorilẹ aye. Bi ẹnikẹni ba si ṣe aṣemaṣe pẹlu iyawo eniyan, igba naa ni yoo ri ibinu ọkọ rẹ. Iyawo ni ijọ jẹ si Jesu.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Aṣẹ ti Ọlọrun fun wa ni ki a maa ṣe ikilọ fun awọn olori to n hu iwa buburu, ki ẹjẹ wọn maa ba si lori wa."

Sugbọn nigba ti amugbalẹgbẹ aarẹ Onochie yoo fesi lori ọrọ yii loju opo Twitter rẹ, o fa ibinu yọ.

"Mo nigbagbọ pe ootọ kọ ni ọrọ yii, Oyedepo yoo nilo lati da orilẹ-ede tirẹ silẹ ti yoo si ma da ibẹ gbe pẹlu awọn ofin tirẹ.

Niwọn igba ti o ba ti jẹ pe orilẹ-ede Naijiria naa lo wa, o di dandan ki o tẹle ilana ati ofin ibẹ. Yoo se gẹgẹ bi ofin ṣe sọ ni.

Aibọwọ fun ofin ti to gẹẹ"

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Onochie fi kun un pe, Oyedepo n ti iwa aitẹle ofin lẹyin ni Naijiria, o ni ati ilu Ọba ni wọn ti n fi owo iranwọ ranṣẹ si Oyedepo, sugbọn o n dunkoko mọ ijọba ni Naijiria.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Aarẹ apapọ fun ijọ Winners, Bishọọbu David Oyedepo, ti sọ asọtẹlẹ pe gbogbo agbara okunkun to n jọba lori ilẹ Naijiria ati ni Afrika ni yoo kan abuku ki ọdun yii to pari

Bishọọbu Oyedepo kede bẹẹ lasiko iwaasu rẹ nibi ipade ajọ nla Shiloh, Ogun iru rẹ, to side rẹ ninu gbọngan nla ijọ naa to wa nilu Ọta, nipinlẹ Ogun.

Oyedepo ni "akoko ọtun lo de yii, ti Ọlọrun yoo si gbe agbara asẹ fun awọn ijọ lati dẹkun awọn ilana ofin to mẹhẹ atawọn oloselu ti ko pegede to ni Naijiria."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ìbejì Oníbẹ̀mbẹ́ Òru: Owó, ọmọ àbí aya kò leè yà wá

O fikun pe orilede Naijiria ati il Afrika lapapọ, ni Ọlọrun setan lati gba lọwọ awọn aninilara ati ọrọ aje to mẹhẹ.

Olori ijọ Winners naa ni "ọpọ ẹtan lo wa ninu aye loni, amọ emi duro fun otitọ, agbara nla ti Ọlọrun yoo si gbe wọ ijọ rẹ lọrun yoo pọ to bẹẹ gẹ, ti yoo mu owu jijẹ dani."

Gbọngan ijọ Winners

O ni akoko ti to, to jẹ pe asọtẹlẹ latinu ijọ Ọlọrun yoo maa sẹ, ẹniti wọn ba ni ko ku, yoo ku, ẹni ti wọn ba si ni ko ye, yoo ye.

"Ijọ Ọlọrun yoo maa kọ awọn eeyan ni ẹka kọọkan lọna to pegede lati se amusẹ awn afojusun wọn, ti yoo si mu esi nla jade."