Aso Rock: Aò mọ bí obìnrin náà ṣe wolé

Obìnrin tó máà ń lo onírúurú ọ̀nà alùmọkọ́rọ́yín wọ ilé ààrẹ l'Abuja láti lo gbájúẹ pẹ̀lú àwọn ayédèrú òwò ṣíṣe ti kábamọ̀ ìwà rẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ sọ pé Amina Muhammed tí kọ́kọ́ sọ pé oun ní aya gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi lójúnà àti rí ààyè wọ Aso Rock ní ìlú Abuja.
Ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ sọ pé Amina Muhammed tí kọ́kọ́ sọ pé oun ní aya gómìnà Kogi lójúnà àti rí ààyè wọ Aso Rock ní ìlú Abuja.
Lẹ́yìn èyí ló bẹ̀rẹ̀ sí ní ráńṣẹ́ sí àwọn ènìyàn lórúkọ ayá ààrẹ Muhammadu Buhari.
Níbi ìpàdé àwọn oníròyìn tí wọn ti sàlàyé ọ̀nà tí wọn gba mú arábìnrin Mohammed ṣe ló kígbe pé "irọ́ ní''

Oríṣun àwòrán, Iconway
Peter Afunanya, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àjọ DSS sọ fún BBC pé ìbanilórúkọ jẹ́ ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ nígbà tí aya ààrẹ Buhari rìnrìn ààjò kúrò ní orílẹ̀-èdè yìí ní nínú oṣù kọkànlá ọdún 2017.
Gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ DSS ṣe sọ, ọ̀kàn lára àwọn tó ti bọ́ sọ́wọ́ àyínìke obìnrìn ọ̀hún ní ọkùrín onísòwò ńlá kàn Chika Okafor, tí Amina Mohammed ránṣẹ́ pè wá sí Aso Rock náá nàka sí i pé ó ja ohun lólè ààdọ́jọ mílíọ̀nù ó lé díẹ̀ náírà lórí òrọ̀ ohun ìní kan nílùú Eko.
Ó fí kún-ún pé Amina ló ànfàní pé àwọn aya gómìnà , mínísítà àti àwọn èèkàn míràn nínú ìjọba kìí kójú ìsòrò àyẹ̀wò ọlọ́pàá tí wọn bá fẹ́ wọ ilé ìjọba.
Wọ́n ní ìyàlẹ́nu ló sì jẹ́ bí obìnrin náà ṣe láa gbogbo àyẹ̀wò kọjá bí àwọn ọ̀tẹ̀lẹ̀múyẹ́ àtí àwọn agbófinro ṣe pọ̀ tó, àti pé gbogbo àwọ òṣìṣẹ́ Aso Rock ló ní káàdì tí wọn fí ń wole sí ié ìjọba.












