Election 2019: Atiku Abubakar bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ àti di ààrẹ Nàìjíríà pẹ̀lú ìpolongo ní Sokoto

Atiku ni ibi ipolongo ibo rẹ

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀ èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló péjú pésẹ̀ síbi ìpolongo ìbò náà nílúù Sokoto.

Oludije fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria ni ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ti tu kẹkẹ ipolongo idibo rẹ silẹ bayii nibi ipolongo idibo to waye ni ilu Sokoto ni ọjọ aje.

Atiku Abubakar ni ọpọ n fi oju wo gẹgẹ bi ẹni ti yoo ba aarẹ Buhari ta kangbọn julọ lasiko idibo apapọ ọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Tọkọ-taya Aràrá: Àwọn èèyàn máa ń wò wá, ta bá fa ọwọ́ ara wa ní títì

Ọpọ ero ni wọn peju si ibi ipolongo naa, bẹẹni awọn eekan ẹgbẹ oṣelu PDP bii aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan, aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki, olori ile aṣoju-ṣofin Yakubu Dogara, gomina Aminu Tambuwal wa nibi ipolongo naa pẹlu.

Ninu ọrọ rẹ, aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan ni ẹgbẹ oṣelu PDP ni ẹgbẹ oṣelu akọkọ lorilẹede Naijiria ati pe Atiku Abubakar ni ẹni naa ti o lee yọ orilẹede Naijiria ni ọdun 2019.