BOWEN: Àwọn adarí ti fásitì Bowen pa lẹ́yìn wàhálà àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, @Bowen University
Wọn ti gbe fasiti Bowen nipinlẹ Ọṣun ti pa.
Awọn alaṣẹ fasiti naa ni wọn kede titi pa ileewe naa ni ọsan ọjọ aje lẹyin wahala to waye lori bi wọn ṣe le awọn akẹkọ kan nileewe naa lọ sile lori lilo ogun oloro.
Akọwe agba ile ẹkọ fasiti naa, Kayode Ogunleye ni wọn fun awọn akẹkọọ naa di aago mẹrin ọsan ọjọ Aje lati kuro ninu ọgba ile iwe naa, bi bẹẹ kọọ, wọn o da ṣeria fun ẹni tọwọ ba tẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Iroyin to n tan kalẹ loju opo ayelujara ni pe, ile ẹkọ fasiti Bowen le awọn akẹkọ to to igba lọ sile lori ẹsun pe wọn kọ lati kopa ninu ayewo ti yoo safihan boya wọn n lo ogun oloro.
Fásitì Bowen ní kí akẹ́kọ̀ọ́ 50 lọ rọọ́kún nílé torí ìpáǹle
Akọwe agba fun ile ẹkọ fasiti Bowen nipinlẹ Ọsun, Ọmọwe Kayode Ogunleye ni ko si ootọ ninu ọrọ to n ja rain rain wi pe wọn ti ti ile ẹkọ na pa.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu ile isẹ iroyin BBC Yoruba lọjọ Aje, ọmọwe Ogunleye sọ pe, lootọ lawọn akẹkọ kan ṣi iwa hu ṣugbọn eto ẹkọ si n lọ lọwọlọwọ ni ile ẹkọ naa.
O salaye pe ''ninu ogba ile iwe ni mo wa bayi. Ko si iyọnu kankan. Ohun gbogbo n lọ leto leto.''
''Ni ijẹta la sọ fun awọn to siwahu pe ki wọn ma lọ sile lati lọ rọkun nile. A si ti fi to awọn obi wọn leti ''
Iroyin to n tan kalẹ loju opo ayelujara ni pe, ile ẹkọ fasiti Bowen le awọn akẹkọ to to igba lọ sile lori ẹsun pe wọn kọ lati kopa ninu ayewo ti yoo safihan boya wọn n lo ogun oloro.
Ṣugbọn nigba ti a beere lọwọ Ogunleye iye awọn akẹkọ ti wọn le, o ni ''wọn ko ju aadọta lọ''
''Mi o fẹ sọ iye ti yoo wa yatọ si eleyi ti o le jade lẹyin wa ṣugbọn mo mọ daju wi pe wọn ko to aadọta.''
''Awọn perete lo ṣi iwa hu lara awọn akẹkọ wa, ti a si gbe igbesẹ gẹgẹ bi ile iwe ti kii gba iwa kiwa laaye lati ba wọn wi.''
Lori aworan ile ibusun ti awọn kan n pin lori ẹrọ ayelujara wi pe awọn akẹkọ kan dana sun, Ogunleye so pe oun ko mọ nipa rẹ.
Awọn akẹkọ ati alaṣẹ ko ṣẹṣẹ fa wahala
Eyi kii ṣe igba akọkọ ti gbọnmisi omi ooto yoo ma waye laarin awọn akẹkọ Bowen ati awọn alasẹ ile ẹkọ naa ti ajọ nla onitẹbọmi da silẹ.
Lọdun 2014 lawọn alaṣe ti ile iwe naa pa nitori bi awọn akẹkọ ti ṣe fariga lori akoko ti ile ẹkọ naa la kalẹ fun wọn lati ma jeun.
Ninu wahala to bẹ silẹ nigba naa, awọn akẹkọ ba awọn ọkọ kan ti wọn gbe kalẹ sinu ile ẹkọ naa jẹ.
A beere lọwọ ọmọwe Ogunleye wi pe ki lo le mu ki awọn akẹkọ ma wu iru iwa janduku bayi.
Alaye to ṣe ni pe ''awọn ọmọ ode oni ko fẹ ibawi mọ. Awa nikan si kọ ni ọrọ naa kan gẹgẹ bi ile ẹkọ. Ọrọ to gbode nii.''














