Sanwo-Olu: Kò ní sí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ mọ́ l‘Eko tí mo bá dé ipò

Oríṣun àwòrán, Jide Sanwo-Olu Campaign
Olùdíje fún ipò Gómínà Ipinlẹ Eko lábẹ́ àṣíá ẹgbẹ́ oṣèlú APC, Jide Sanwo-Olu gbé ìgbésẹ̀ láti dáhùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibéérè tí awọn ará ìlu Eko ni fún loju opo Twitter rẹ lọ́jọ́ Àìkú.
Sanwo-Olu, nigba to n sọrọ lórí bó ṣe di olùdíje ati awọn ọ̀rọ̀ míràn tí ayé ti ń mẹ́nu bà láti ìgba tí ìdìbò abẹ́lé APC ti waye, O ni awọn isẹlẹ to n waye lo safihàn pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà kò fẹ́ Gomina Akinwúnmí Ambode fun sáà kejì.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Àwọn kókó mẹ́wàátí Sanwo-Olu sọ:
- Lórí ìbéère nípa àìní òye tó nípa ìṣèjọba, Sanwo-Olu dáhùn wípé, òun kìí ṣe aláìlóye ènìyàn nítòrí òun ti wà nínú iṣèjọba lati ọdun 2002, àti pé òun ti ṣe kọmíṣọ́nà lẹ́ẹ̀méjì, olùrànlọ́wọ́ fún gómínà àti olórí iléeṣẹ́ ìjọba ri
- Sanwọ-Olú dáhùn ìbéèrè nípa ayédèrú owó dọ́là tí wọ́n fi ẹ̀sùn kan an pé ó ná nílu Amẹrika. Ó ni bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ti gbọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn náà, kò sí òtítọ́ kankan níbẹ̀
- Oludije naa ni òun yóò fi òpin sí bí àwọn ọkọ́ agbépo ṣe ń dá wàhálà sílẹ̀ lójú pópó Ìpínlẹ̀ Eko àtí wípé òun yóò fi iná oju popo sí gbógbó kọ́lọ́fín ìlu tí ǹkan búburú ti ń ṣẹlẹ̀

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI
- Ó ní àwọn iléeṣẹ́ ìjọba tí ọ̀rọ̀ kàn yóò ṣe agbéyẹ̀wò owó gọbọi tí àwọn ayálégbé ń san fún onílé ní Ìpìnlẹ̀ Eko
- Lórí ẹ̀sun pé àwọn ará ìlú kò mọ oun tó ń wà nínú ìṣúná owó Ipinlẹ Eko, Sanwo-Olu ní òun yóò gbíyànjú láti fi ojú ọ̀rọ̀ iṣúná owo ìpínlẹ̀ náá síta, tí ará ìlú yóò sì mọ̀ bí ìjọba ṣe ń ná owó wọn

Oríṣun àwòrán, Sanwo Olu Campaign
- O gbìyànjú láti dáhùn ìbéère nípa agbára tí olórí ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Oloye Bola Tinubu ní lórí ìṣèjọba Ìpinlẹ Eko. Sanwo-Olu ni irọ ni ẹ̀sùn àwọn alátakò òun (PDP) wípé, ìgbèkun ni àwọn ará Eko wà. Ó ni ẹgbẹ́ alátakò náà ló dúró fún oko ẹrú tí ará ìlú kò gbódọ̀ padà sí
- Oludije náà ní òun yòó yanjú ọ̀rọ̀ ojú gọ́tà àtí ojú àgbàrá tó ti bàjẹ́

- Sanwo-Olu ní òun ti ṣe ìwádìí àwọn oríkò àádọ́tà tó ń fa súnkẹrẹ-gbákẹrẹ ọkọ̀ nilú Eko. Ó ní òun yóò ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀nà tí àwọn ará ìlú kò ní fi máà pẹ́ lójú ọ̀nà

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI
- Sanwo-Olu ṣe ilérí láti parí ọ̀na ojú irin tí gómínà àná, Babatunde Fasola bẹ̀rẹ̀ ní pópónà Eko si Badagry, èyi tí ìjọba ti pa ti láti ọdún mélòó kan sẹ́yìn

Oríṣun àwòrán, Lago State Government
- Ó ní òun yóò fún àwọn obinrin láàyé nínú ìjọba òun










