Lagos APC Primaries: Gómìnà Ambode gbà pé òun fìdí rẹmi

Oríṣun àwòrán, Ambode
Gómìnà Akinwumi Ambode ti ìpínlẹ̀ Eko ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún ìrẹ́pọ̀ wọn láti yan olùdíje wọn.
Ninú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó bá gbogbo aráàlú sọ lọ́jọ́rú ọjọ́ kẹta oṣù kẹ́wàá ọdún 2018 ló ti wí fún àwọn ará ìpínlẹ̀ Eko wí pé àkókò ti tó fún ìpínlẹ̀ Eko láti tẹ̀ síwájú.
Ó ní èyí ṣe pàtàkì kí àwọn mùdùnmúdùn àtọdún mẹ́ta àbọ̀ má baà forí ṣánpọ́n.
Ìgbìmọ̀ p'ohùn dà, wọ́n kéde Sanwo-Olu ní APC Eko

Oríṣun àwòrán, @jide_sanwoolu
Ìgbìmọ̀ p'ohùn dà, wọ́n kéde Sanwo-Olu ní APC EkoAlága ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Clement Ebris ti kéde Babajide Sanwo-Olu gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí láti dupò gómìnà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ́dún tó mbọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbẹ́ni Ebris ṣe sọ ọ́, iye ìbò tí Babajide Sanwo-Olu ní ni 970,851 nígbà tí gómìnà Akinwumi Ambode ní ìbò 72,901.

Àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò sún kí wọ́n jọ kọrí síbì kan

Oríṣun àwòrán, @Ambode
Saaju eyi, igbimọ amusẹya fun ẹgbẹ oselu APC ti fagile idibo abẹle to waye ni ipinlẹ Eko lati yan ẹni ti yoo soju ẹgbẹ APC.
Alaga Ẹgbẹ Igbimo Amuseya (NWC), Ọgbẹni Clement Ebri nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ wi pe awọn sẹsẹ n gbaradi fun idibo abẹlẹ naa ni.
Ebri fikun wi pe awọn fẹ duro de gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lati le tẹsiwaju ninu idibo naa.
Alaga naa wa rọ awọn eniyan lati gba alaafia laaye ki idibo ti awọn fẹ se le lọ ni irọwọrọsẹ.
Lagos APC Primaries: Ambode kò dìbò, ìgbákejì rẹ̀ Adebule dìbò fún Sanwoolu

Oríṣun àwòrán, Ambode
Omowe Idiat Adebule to jẹ igbakeji Gómìnà Akinwumi Ambode ti fi atilẹyin han fun alatakò ọga rẹ̀ nínú ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Babatunde Sanwoolu.
Adebulẹ to ba awọn oniroyin sọrọ nibi idibo ni Ward A ati D ni ijọba ibilẹ Iba ni ẹgbẹ ti yan oludije ti wọn fẹ ati wipe oun ni oun yoo ti lẹyin.
Ambode kò dìbò
Iroyin lati ọwọ ikọ BBC to wa ni Epe Ward A5 ati A6 nibi ti Ambode ti yẹ ko dibo fi han pe kó wá díbò títí tí ibò fi parí.
Nigba ti akọroyin BBC kan si agbẹnusọ Ambode, Lanre Olagunju, o ni gomina ko fẹ sọrọ bayii ṣugbọn yoo gbe atẹjade sita ni wakati ranpẹ.

Ṣáájú, alátakò gómínà náà Babajide Sanwoolu ti dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó tú jáde láti dìbò fún un.
Ó sọ èyì nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú akọ̀ròyìn BBC Yorùbá tó wà ní ibùdó ìdìbò rẹ̀ lẹ́yìn tí òun fúnra rẹ̀ dìbò tan.
Ni wọ́ọ́dù ti Sanwoolu ti dibo ni E3, oludije naa ni ibo 4,530 ninu 4,920, ṣugbọn Ambode ko ni ẹyọkan.
Òni lònìí ń jẹ́ ẹni a bẹ̀ lọwẹ̀ ló gbòde gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n sún ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Eko síwájú sí ṣe ti pé.
Láàrin gómìnà tó wà lórí àléfà báyìí, Akinwumi Ambode àti olùdíje fún ìgbà àkọ́kọ́, Babajide Sanwoolu ni ìfigagbága yóò ti wáyé.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Àjọ́ elétò ìdìbò tí yóò mójútó bí gbogbo ètò náà yóò ṣe lọ ti wà níkàlẹ̀.

Ní ibùdó ìdìbò àwọn méjèèjì yìí, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti wà níkàlẹ̀ láti dìbò yan ẹni tí wọ́n fẹ́.
Ibùdó tó wà ní St. Stephens Primary School, Adeniji Adele ni Babajide Olusola Sanwoolu yóò ti dìbò.

Akinwumi Ambode yóò sì dìbò ní Epe Wọ́ọ̀dù A5 àti A6.

Ẹ̀wẹ̀, ní Ikeja Wọ́ọ̀dù C, ibùdó ìdìbò kẹta ní Bola Ahmed Tinubu tó jẹ́ Baba ìsàlẹ̀ fún ẹgbẹ́ yóò ti dìbò.

















