Ìjàmbá iná l'Eko: Ọkọ̀ aképo gbiná ní òpópónà Eko sí Badagry

Oríṣun àwòrán, lagos state police command
Ọkọ̀ aképo kan ti bú gbàmù ní òpópónà Eko sí ìlú Badagry lówurọ̀ ọjọ́ ìṣẹ́gun.
Ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni wí pé ó mú ẹ̀mí ènìyàn lọ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì jóná.
A kò tíì rí àrídájú tó tó sùgbọ́n a ó máa mú ìròyìn bó ṣe ń lọ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wá fún un yín.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Agbẹnusọ fún àjọ tó ń kojú ìṣẹ̀lẹẹ̀ pàjáwírì ní Ipinlẹ Eko (LASEMA) Ọgbẹni Adebayo Kehinde, ni ọkọ̀ akérò mẹ́ta, àti àjàgbé mẹ́fa ni ó jóná nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Ìjàmbá afárá Ọ̀tẹ́dọlá: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọlọ́kọ̀ epo tó fa ìjàmbá iná

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ǹkan bí oṣù díẹ̀ sẹ́yìn ni irú ìṣẹ̀lẹ̀ aburú yìí ṣẹlẹ̀ ní orí afárá Ọtẹdọla ní ìpínlẹ̀ Eko.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọwọ awọn ti tẹ arakunrin ti o ni ọkọ agbepo to ṣokunfa ijamba ina to waye lori afara Ọtẹdọla nilu Eko.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko fi sita, ọwọ awọn ọtọlẹmuyẹ tẹ ọgbẹni Hassan Maiwake ni ilu Kano ṣugbọn awakọ ajagbe elepo naa ṣi na papa bora.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹfa ni ọkọ ajagbe elepo kan to gbe jala epo ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn gbina lẹyin ti o ṣubu ti o si da epo silẹ kaakiri ori afara naa.
Ki ato wi, ki a to fọ, eeyan mẹsan ati ọkọ mẹrinlelaadọta lo ti jona ninu ijamba naa.

Oríṣun àwòrán, ỌLLABỌ̀DÉ AKAMỌ
Gẹgẹ bii ọgbẹni Chike Oti to jẹ alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣe sọ, 'oju kẹrindinlogun, opopona Hitoro Limawa ni wọn ti mu arakunrin Hassan Maiwake ni ipinlẹ Kano, o si ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadi wọn lati ṣawari awakọ to wa ọkọ ajagbe yii lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹ.'
O ni Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko yoo sa gbogbo ipa rẹ lati rii daju pe awọn to padanu ẹbi ati dukia wọn sinu iṣẹlẹ naa gba idajọ ododo.














