2019 Election: APC ní ẹ̀ka asòfin ló leè tún Nàíjíríà tò, kìí se ààrẹ

Oríṣun àwòrán, @atiku
Awọn ọmọ orilẹede yii ti n sọ ero ọkan wọn lori ikede kan tawọn agbaagba ilẹ Yoruba ati ẹgbẹ Afẹnifẹre se laipẹ yii pe oludije fun ipo aarẹ, labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP< Atiku Abubakar, nilẹ Yoruba yoo pọn lẹyin rẹ ninu ibo ọdun 2019.
Nigba to n fesi lori ikede yii, onimọ kan nipa ọrọ oselu, to tun jẹ eekan kan ninu ẹgbẹ oselu APC ati olori osisẹ ni ọọfisi gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Gbade Ojo ni, awọn agbaagba Yoruba ati ẹgbẹ Afẹnifẹre kii se ẹgbẹ oselu rara.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ojo salaye pe awọn eeyan yii ko lasẹ lati sọrọ nipa ẹni ti Yoruba yoo dibo fun lọdun 2019 nitori ko si gomina ipinlẹ kankan nilẹ Yoruba, ti wọn lee da fi ibo gbe wọle, ka ma sẹsẹ sọ ti aarẹ Naijiria.
Olori osisẹ ni ọọfisi gomina Ọyọ naa ni, ẹru ko bodo ni ọrọ ẹgbẹ oselu APC, ẹni ti yoo wọdo ni ominu n kọ, bẹẹ ni ẹru ko ba APC rara lori ikede awọn agbaagba Yoruba yii.

Oríṣun àwòrán, @Atiku
O sọ "igi kansoso Atiku ko lee da igbo se nidi atunto Naijiria, ileri asan lo si n se fawọn ọmọ ilẹ yii pe oun yoo tun Naijiria to. Sugbọn ko si ohun ti ẹni to ba n wa ibo ko lee sọ, ileri asan ni."
Gbade Ojo fikun pe, lootọ ni ẹya Yoruba n poungbẹ atunto, amọ ojuse awọn asofin ni lati gbe ofin tuntun kalẹ, ti yoo se atunto ẹka gbogbo nilẹ Naijiria, eyi to kọja agbara aarẹ kankan.
Atiku làwa ń báá lọ ní 2019 - Asaájú Yorùbá lahùn
Ilu Eko gbalejo lọjọ Aje nigba ti awọn agbaagba Yoruba, to fi mọ ẹgbẹ Afẹnifẹre korajọpọ lati sepade apero lori eto iselu il wa.
Atẹjade onikoko mejila kan ti wọn fisita lopin ipade wọn ọhun salaye pe, awọn agbaagba Yoruba naa ti fẹnu ọrọ jona lati fontẹ lu oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar gẹgẹ bii oludije ti iran Yoruba yoo to lẹyin rẹ ninu eto idibo to n bọ lọdun 2019.
Atẹjade naa ni ẹya Yoruba n fohun kan soso sọrọ, ti wọn ko si pin yẹlẹ-yẹlẹ, ti igbagbọ wọn si wa ninu igbesẹ atunto orilẹede naijiria lọna ati jẹ ki ibaradọgba ati iwa aparo kan ko ga ju ọkan lọ fidi mulẹ, pẹlu idajọ ododo.
Nigba ti wọn n fidi ipe fun atunto Naijiria mulẹ, atẹjade naa salaye pe ijọba apapọ ti gbooro ju, ti ko si tun ni afojusun to yẹ, ti atunto ba wa ni yoo si rọrun lati pin ọrọ aje ajumọni wa bo se yẹ, eyi ti yoo mu ki irẹpọ, ibaradọgba ati idajọ ododo wa.

Oríṣun àwòrán, @Afenifere_ARG
Atẹjade naa salaye pe " Awa Yoruba n se atilẹyin fun Atiku Abubakar lati di aarẹ orileede yii lọdun 2019 nitori bo se faramọ eto atunto Naijiria eyi ti yoo peses anfaani ọgbọọgba, aisegbe sibikan ati idajọ ododo fun gbogbo awọn eeyan ti ọrọ orilẹede yii kan."














