Olórin, Small Doctor, gba ìtúsílẹ̀ nínú àhámọ́

small doctor

Oríṣun àwòrán, Small doctor

Gbajugbaja olorin Adekunle Temitọpẹ ti gbogbo eniyan mọ si Small Doctor to tun jẹ aṣoju olorin fun ileeṣẹ ọlọpaa ti gba itusilẹ bayii.

Ile ẹjọ da Olorin Small Doctor silẹ lẹyin ti wọn mu u lopopona kan l'Eko to n fi ibọn dẹru ba awọn ọlọpaa to da ọkọ rẹ duro. Wọn fi ẹsun pe o ni ohun ija oloro lọna aitọ.

Iroyin to n tẹwa leti ni wi pe wọn da a silẹ pẹlu ikilọ pe ko ma ṣe kopa ninu iwa ipa kankan titi ọdun kan gbako.

Ẹwẹ, ninu ifọrọwanilẹnuwo BBC Yoruba pẹlu agbnu sọ rẹ, o fi aridaju han pe wn ti daa silẹ sugbọn ohun ko ni le sọrọ pupọ fun oniroyin lasiko ti a ko iroyin yii jọ.

Ahamọ ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Eko (SCID) ni olorin takasufe Small Doctor ti orukọ rẹ gangan n jẹ Michael Owusu Addo, sùn lati ọjọ Aje tí àwọn ọlọ́paa ti mu.

Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Edgal Imohimi lo fi afunrasi olorin naa han awọn oniroyin ni ọjọ Aje lori ẹsun nini ibọn lọwọ lai bá òfinmu ati gbigbimọran lati yinbọn lu ọlọpaa.

Ni ọjọ Isegun ni agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa ni Eko Chike Oti sọ fun akoroyin BBC Yoruba wipe, oun kò tíì mọ ọjọ́ tí olorin naa yoo foju ba ile ẹjọ.

Small Doctor bẹ BBC Yoruba wo ni oṣu keje nibi to ti sọrọ nipa igbesi aye rẹ

Àkọlé fídíò, Small Doctor: Mo kórira igbó, ọtí àti sìgá nítorí màmá mi lòdì si

Oti ṣalaye pe wọn ba ibọn lọwọ gbajugbaja olorin naa ti iwadi si ti bẹrẹ lori ẹsun naa ati pe ni kete ti ọrọ ba yanju, wọn yoo gbe lọ si ile ẹjọ.

Iroyin sọ pe ọlọpaa aṣọna kan ti o n ṣiṣẹ rẹ lagbegbe Oshodi ni ilu Eko ni Small Doctor yọ ibọn si.

Small doctor

Oríṣun àwòrán, Small doctor

Àkọlé àwòrán, Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Eko ní èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí wọn yóò mú Small Doctor fún ẹ̀sùn tó níí ṣe pẹ̀lú ìbọn

" Wọn ni awọn ọkunrin mẹrin kan ninu ọkọ ti wọn ko gba nọmba idanimọ si fa ibọn kan yọ ti wọn si leri ati yiiin in ms ọlọpaa naa bi ko ba kuro ni oju ọna fun wọn."

Pẹlu ero pe adigunjale ni awọn eeyan wọnyii ni mo fi ni ki awọn ọlọpaa o gba tẹle wọn ti wọn si mu wọn."

Ibọn gigun kan ati ọta ibọn ni wọn ba lọwọ awọn eeyan naa ninu eyi ti wọn ni olorin naa, Small Doctor wa.

Gẹgẹ bi ọga ọlọpaa naa ti ṣe wi, olorin naa ti wa ninu irufẹ ẹsun yii ri ti wọn ni o yin ibọn eyi to ṣe awọn eeyan mẹrin lẹṣe ti wọn si di ero ileewosan.

Small Doctor wà lára àwọn ọ̀dọ́ olókìkí tí ileeṣẹ ọlọpaa yàn gẹgẹ bii awokọṣe nilu Eko.

Akẹgbẹ rẹ to jẹ olorin takasufe Korede Bello naa wa lara awọn ti ileeṣẹ ọlọpaa yan gẹgẹ bii awokọṣẹ ati aṣoju laarin awọn ọdọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Ìyá Tíṣà lòdì sí kí n mutí, fagbó tàbí sìgá'
Àkọlé fídíò, Tọkọ-taya Aràrá: Àwọn èèyàn máa ń wò wá, ta bá fa ọwọ́ ara wa ní títì

.