Death: Ìlú tí wọ́n ti ń fi ọ̀kadà gbé òku lọ mọ́súárì

Oríṣun àwòrán, Pk Kasirim
- Author, Yemisi Oyedepo
- Role, Broadcast Journalist
Ipele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọ̀rọ̀ òsì wà láti ibikan si ibòmíràn bí ọ̀pọ̀ bá ri bi òṣì àti ìṣẹ́ se mú ẹlòmíràn, ojoojúmọ́ ni yóò má fi dúpẹ̀ lọ́wọ́ Elédùà fún ipò tó wà.
Láìpẹ́ yìí ni àwòràn kan jẹyọ lórí ayélujára nípa bi àwọn abúlè kan ni DR Congo ṣe máa n gbé òkú wọ́n lọ sí mọ́súárì tàbí gbé e wá sí abúlé láti Mọ́súárì.
Gẹ́gẹ́ bi ìwé ìròyìn Zambia kan ṣe sọ, àti fọ́tò kan ti PK Kasirim fi léde lóri ayélura lo tí ni tí òkú bá kú ni àbúlé wọ́n yóò pé àwọn bọda bọda èyí ti à n pé ni ọ̀kada ni ihà ibí láti bá wọn gbé òkú náà lọ mọ́súárì.
- Orí kó obìnrin 115 yọ lọ́wọ́ àwọn tó ń gba omi ọyàn wọn l'Abuja
- Láti 110kg ni mo ti já sí 87kg báyìí, ṣùgbọ́n mí ò ṣáàro ọyàn mi ńla tó dínkù - Ronke Oshodi Oke
- 'Sunday Igboho dáná sun àwòrán bàbá wà kódà ó tún yìnbọn sókè nígbà tó wà sí ilé wà ní Eggua'
- Oba Yesufu Asanike I, Olubadan tó fi èèyàn joyè jùlọ̀ láì fi ẹ̀yà ṣe
O ní ni ọ̀pọ̀ ìgbà, ìrìnàjò yìí má n tó wákàtí márún si mẹ́wàá, kò sí ẹbi òkú ti yóò si ni ànfàni láti tèlé òkú náà tori kada kan pere ni wọn yoo lo eyi to si ti gba oku ati ẹni to n wa a.
Ìròyìn sọ pé, àwọn ẹbí yóò ti wé òkú náà ni asọ láti orí délẹ̀, wọ́n yóò wá mú àsọ láti so òkú náà àti ọlọ́kadà papọ̀ kó má baa ré jábọ lójú ọ̀nà.
Ọ̀pọ̀ lo lérò pé gbogbo ǹkan to níṣe pẹ̀lú òṣì àti ìṣẹ ni àwọn mọ̀, ṣùgbọ́n èyí fi hàn pé òṣì àti iṣẹ́ kò mọ̀ nínú àìrí oúnjẹ jẹ tàbi ri aṣọ wọ nìkàn.
Àworan òkè yìí fí ibi ti iṣẹ́ àti òsì mú àwọn míràn dé ni àwọn àbúlẹ̀ ilẹ̀ Adúláwọ̀ lágbàyé.

Oríṣun àwòrán, PK Kasirim











