Breast milk sale: Orí kó obìnrin 115 yọ lọ́wọ́ àwọn tó ń gba omi ọyàn wọn l'Abuja

Awọn obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn alaṣẹ tọrọ kan ti da si ọrọ awọn iyalọmọ marunlelaadọfa nilu Abuja ti awọn kan n gba omi ọmu wọn lojoojumọ ti wọn si n fi ṣe oniruuru nkan afi omi ọmu ṣe bii wara, bọta ati miliiki mimu.

Ọpọlọpọ awọn iyalọmọ ti wọn n lo fun iṣẹ laabi yii lo jẹ ọdọbinrin bii ọmọ ọdun mẹrindinlogun ti eyi to dagba ju ninu wọn si jẹ ẹni ọdun mejilelogun ti iroyin si kan pe poora lawujọ ibi ti wọn n gbe.

Awọn ọlọpaa lo fura pe awọn ajinigbe to ko wọn pamọ n ka fidio gbogbo nkan ti wọn n ṣe fun wọn lati ọdun mẹta sẹyin ti wọ́n si n gbe sori ayelujara awọn onibara wọn.

Àkọlé fídíò, 50 Year old Ajayi Folashade: Mo ti kọ́kọ́ dán an wò ní 80s àmọ́, ó kàn ṣáà ń wù mi náà ni

Iroyin sọ pe awọn alaburu to n kore nibi ti wọn o gbin si yii maa n fipa ba awọn ọmọbinrin naa lopọ, wọn a fun wọn lóyún ni gbangba lori ayelujara idakọnkọ ti wọn ṣi pẹlu awọn onibara wọn.

Bi wọn ba wa bimọ tan, wọn a bẹrẹ si ni fun omi mu wọn lojoojumọ pẹlu awọn irinṣẹ ti awọn ileeṣẹ nla nla n lo lati fi fun waraa maalu.

Lori irọ ni wọn fi gbe maalu Mẹta ti iya n jẹ siwaju ọfiisi wọn nitorii bi ọlọpaa ba fẹ yọju wo nkan to n lọ nibẹ.

Àkọlé fídíò, Kété tí wọ́n bá ti báa yín sùn tàn torí pé ẹ tóbi, ẹ gbà pé ìfẹ́ yẹn ti parí - Auntie Remi Ọlọ́yàn ńlá

Ọpọlọpọ ọja ti wọn maa n ko jade latinu ile iṣiṣẹ wọn ni wọn maa n ko lọ oke okun pẹlu fidio ilana ti wọn n gba fun omi ọmu lara wọn ati bi wọn ṣe n sọ ọ di odidi.

Ninu ẹrọ kọmputa atawọn iwe ti wọn gba lọwọ wn ni aṣiri ti tu pe lara awọn ololufẹ wọn to maa n wo wọn lo da iléeṣẹ́ fífún omi ọyàn silẹ fun wọn.

Awọn oludasilẹ wọn yii lo n san owo fun wọn pẹlu cryptocurrency. Wọn maa n san owo lati ni fidio ti wọn yoo da fi ranṣẹ si eeyan kan ṣoṣo lati wo ati bi wọn ṣe n fun omi ọmu awọn ọmọbinrin.

Iroyin sọ pe nigba mii awọn eeeyan kan a diidi bere fun pe ki wọn fun ọmọbinrin kan lara wọn ni irufẹ ounjẹ kan pato jẹ looto ki wọn to fun omi ọmu rẹ bi ẹni to f ra a ṣe fẹ ati pe ninu fidio, ki ọmọbinrin naa sọ pe "omi ọmu yio, tirẹ Mr A tabi Mrs B ni".