Sunday Igboho Vs Fulani: Igboho yan Olayomi Koiki gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ tuntun

Igboho fesi lori pe yoo jẹ ọga fun ikọ Amotekun

Ajijagbara fun awọn ọmọ Yoruba, Sunday Adeyemo ti gbogbo eniyan mọ si Sunday Igboho ti sọ wi pe oun ti yan ẹni ti yoo ma ba awọn oniroyin sọrọ.

Sunday Igboho ni Olayomi Koiki ni agbẹnusọ tuntun ti yoo maa ba awọn eniyan sọrọ bayii, nitori oun ko ṣetan lati ba awọn akọroyin sọrọ.

Sunday Igboho sọ eyi lasiko to n tako iroyin to sọ wi pe oun pe fun ogun abẹle ni orilẹede Naijiria.

Ọpọlọpọ iroyin lo ti jade to jẹ gbọyi sọyi ti Sunday Igboho sọ fun akọroyin BBC pe inu oun ko dun si.

Àkọlé fídíò, 50 Year old Ajayi Folashade: Mo ti kọ́kọ́ dán an wò ní 80s àmọ́, ó kàn ṣáà ń wù mi náà ni

Igboho ni ko si oun to jọ bẹẹ, nitori awọn Fulani darandaran to n pa awọn ọmọ Yoruba ni awọn n doju ija kọ.

''Orisirisi iroyin ẹlẹjẹ ni mo ma n ri nipa mi ati ija tako awọn ọdaran afurasi Fulani darandaran to n pa awọn ọmọ Yoruba ni ilẹ Yoruba''

''Nitori naa iroyin ti ẹ ko ba ti gbọ lẹnu agbẹnusọ mi, Koiki kii ṣe emi ni mo sọ.''

''Bakan naa ni n ko pe fun ogun abẹle kankan, irọ patapata ni''.

''Ohun gbogbo ti Koiko ba ti sọ fun awọn oniroyin, emi ni mo sọ nitori n ko ni ba awọn oniroyin sọrọ mọ''

''Emi ati Koiko jọ n sun, a jo n ji ni nitori naa otitọ ni ọrọ ti ẹ ba ba lẹnu rẹ nipa mi.''

Àkọlé fídíò, Ṣé o mọ oríkì ìlú ara rẹ tó olùkọ́ yìí tó dántọ́ lẹ́nu rẹ̀ bíi ọmọ ìlú rẹ?

Ohun táa mọ̀ nípa àpò àsùwọ̀n owó Sunday Igboho tí ariwo ta pé ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé

L'ọjọ Aje ni iroyin gbode kan wi pe ijọba apapọ orilẹede yii ti gbẹsẹ le apo asunwọn ti ajafẹtọ Oloye Sunday Igboho n ko owo si.

Ariwo yii gba ilu kan pe gbogbo apo asunwọn owo rẹ nile ifowopamọ nitori awọn eeyan to n ṣe ikowojọ fun un lori ayelujara.

Lasiko ti ẹgbẹ ọmọ Yoruba kan labe asia Yoruba Youth Socio-cultural Association (YYSA) ṣe abẹwo si ajafẹtọmọniyan naa lati fi ami ẹyẹ da a lọla ni ọrọ yii jẹ jade amọ Sunday kọ ami ẹyẹ naa.

Ṣugbọn iṣẹ iwadii BBC Yoruba fi idiẹ rẹ mulẹ wi pe ahesọ ọrọ lasan ni.

Àkọlé fídíò, Ṣé o mọ oríkì ìlú ara rẹ tó olùkọ́ yìí tó dántọ́ lẹ́nu rẹ̀ bíi ọmọ ìlú rẹ?

Ọkan lara awọn alabasiṣẹpọ Sunday Igboho to ni ki a fi orukọ bo oun laṣiri ṣe alaye fun akọroyin wa l'ọjọ Iṣẹgun wipe "gbọyi-sọyi lasan ni iroyin naa.

O ni irọ ni ọrọ naa nitori pe gbogbo apo asunwọn Oloye naa lo n ṣiṣẹ deede titi di owurọ yii".

O ni, "awọn ọmọ ẹgbẹ YYSA naa ko fi ara han gẹgẹ bii oniroyin, bẹẹ si ni Sunday Igboho ko gba ami ẹyẹ ti wọn fẹ fi da a lọla.

"Pupọ ninu awọn eeyan ti wọn pe ara wọn ni oniroyin ni wọn n kọ ohun ti oju wọn ko to nitori ati jẹ".

Saaju ni Igboho fi atẹjade sita lati tako iroyin kan to tun sọ pe ajafẹtọmọniyan naa ṣe ileri lati kọju ikọ alakatakiti Boko Haran laisi iranlọwọ ijọba.

Sunday Igboho ni irọ lasan ni iroyin naa nitori oun ko sọ ohun to jọ bẹẹ.

O ni ominira lọwọ awọn Fulani darandaran to n gbeni pa nikan ni ilepa ti oun ni fun gbogbo ilẹ Yoruba.