Ondo nurse protest: Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ bá wa bẹ àwọn mọ̀lẹ́bí àti aláìsàn ní FMC Owo, kí wọ́n yé fìyà jẹ àwa nọ́ọ̀sì.

Oríṣun àwòrán, Facebook/max.collinsjnr
Awọn oṣiṣẹ ilera nọọsi ni ile iwosan ijọba apapọ FMC Ọwọ, ni ipinlẹ Ondo, ti ke gbajare lori bawọn alaisan ati mọlẹbi wọn ṣe n fiya jẹ wọn.
Ọrọ yi mu ki wọn ṣe iwọde alalaafia lati fi ifẹhonu wọn han lori ọrọ yi.
Ifiyajẹni ti wọn lawọn koju kẹyin leleyi to ni ṣe pẹlu bi awọn mọlẹbi arakunrin kan to gbẹmi mi se lu awọn nọọsi meji kan laludaku lọjọ Aiku.
A gbọ pe ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun larakunrin naa wa nigba ti wọn fi gbe de ile iwosan ti gbogbo igbiyanju awọn oṣiṣẹ ilera lati doola ẹmi rẹ si ja si pabo.
Awọn mọlẹbi arakunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Mojoyinoluwa Adelu lati Ilara Mokin fa ibinu yọ nitori iku rẹ ti wọn si lu awọn nọọsi meji yi lalaubami.
Ọkan lara awọn nọọsi yi, Olayinka Bankole, to ba akọroyin sọrọ lati ori ibusun rẹ ni ile iwosan ni iya to jẹ awọn kii ṣe kekere,
O ni pẹlu pe awọn sa asala fẹmi awọn wọ inu ile igbọnsẹ, niṣe ni awọn mọlẹbia oloogbe naa wọ awọn jade ti wọn si da bantẹ iya fawọn.
Olayinka ni awọn eeyan meji kan gbe oun soke ti wọn si jan oun mọlẹ ki awọn to ku si fọwọ kun wọn lati maa na oun.
''Niṣe la sa wọ ile igbọnsẹ,wọn tẹle wa debẹ, wọn si wọ wa sita.Awọn obinrin meji kan ninu wọn fọ mi mọlẹ, wọn si bẹrẹ si ni lumi''
Lasiko iwọde awọn nọọsi yi ọga agba ile iwosan naa dokita Liasu Ahmed sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ yi ati pe awọn yoo fawọn to ba mọ nipa iṣẹlẹ yi le ọlọpaa lọwọ.













