Olamide Wonma nurse video: Nọ́ọ̀sì kan ní lóòótọ́ làwọn aláìsàn ń dẹnu ìfẹ́ kọ àwọn

Olamide Baddo/Akintayo Blessing

Oríṣun àwòrán, Olamide/Akintayo Blessing

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Olutọju alaisan kan to n ṣiṣẹ loke okun ti foju laifi wo oju aṣẹwo ti ọpọ eeyan fi n wo awọn nọọsi.

Akintayo Blessing Christiana safihan ero rẹ naa lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori fidio Wonma ti Olamide Baddo ṣẹṣẹ ṣe sita.

Àkọlé fídíò, Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀

Ninu fidio naa si ni o ti ṣe afihan awọn olutọju alaisan bii oninabi, to n ni ibalopọ lẹnu iṣẹ pẹlu awọn alaisan ti wọn n tọju.

Ninu ọrọ rẹ, Akintayo salaye pe lootọ ni awọn kanda kan wa laarin awọn nọọsi sugbọn eyi ko ni ki wọn tabuku gbogbo olutọju alaissn bii aṣẹwo.

"Ibi gbogbo ni awọn kanda inu irẹsi wa, kii ṣe ọdọ awọn nọọsi nikan ni, koda ko si iṣẹ oojọ ti ko ni iriri bayii."

Àkọlé fídíò, Ohun tẹ́ẹ gbúdọ mọ nípa kókó orí ọyàn yín lásìkò fífọ́mọlọ́yàn

"Ṣugbọn eyi ko tumọ si pe gbogbo awa nọọsi ta n ṣíṣẹ kara lo yẹ ki wọn maa tabuku, bi wọn ba ṣe n bu awọn ti ko ṣe daadaa, lo yẹ ki wọn gboriyin fun awa ta n ṣe daadaa lẹ́nu iṣẹ."

Bakan naa ni oṣiṣẹ nọọsi naa fidi rẹ mulẹ pe lootọ làwọn alaisan maa n nawọ ifẹ sáwọn Nọọsi sugbọn eyi ko sọ gbogbo Nọọsi di aṣẹwo.

Nigba to n salaye iyatọ to wa laarin ṣíṣe isẹ Nọọsi ni Naijiria ati loke okun, Akintayo ni iyatọ nla lo wa laarin awọn oṣiṣẹ mejeeji.

"Ilana ta n gba ṣíṣẹ yatọ pupọ, to fi mọ owo osu ati ajẹmonu wa, bakan naa ni ipese irinsẹ fun iṣẹ wa ni Naijiria yatọ si ti oke okun, ti itọju nla si wa fun Nọọsi loke okun."

Akintayo wa gba awọn eeyan nimọran lati dẹkun bíbu ẹnu atẹ lu gbogbo Nọọsi, tori awọn n ṣiṣẹ kara lati doola ẹmi awọn alaisan ni.

Àkọlé fídíò, Kìí ṣe ọmọbìnrin nìkan ni Ọlọ́run pàṣẹ fún láti pa ìbálé mọ́

Àgbáríjọ àwọn nọ́ọ̀sì fẹ́ gbé Olamide Baddo lọ sílé ẹjọ́ fún ìbanilórúkọjẹ́

Olamide Baddo

Oríṣun àwòrán, @Olamide/Instagram/others

Ẹgbẹ awọn nọọsi l'orilẹ-ede Naijiria ti koro oju si fidio orin ti gbajugbaja olorin takasufe, Olamide Adedeji, ti awọn eeyan tun mọ si Baddo, gbe sita ninu eyi to ti fihan pe awọn oṣiṣẹ olutọju alaisan maa n ṣere ifẹ pẹlu awọn alaisan ti wọn n tọju.

O pe akọle orin naa ni Wonma.

Ninu fidio orin ọhun to fi bintin ninu rẹ sori ayelujara lọjọ Iṣẹgun, a ri awọn obinrin to wọ aṣọ nọọsi, wọn n jo ninu yara itọju awọn alaisan, ti awọn kan si n fi ọwọ pa awọn alaisan to jẹ ọkunrin lara lọna ati ni ibalopọ pẹlu wọn.

Skip YouTube post
Allow Google YouTube content?

This article contains content provided by Google YouTube. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Google YouTube cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of YouTube post

Ọpọlọpọ eniyan ati awọn nọọsi lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti Olamide gbe lori ayelujara, ni kete to jade sita, pẹlu #NursesAreNotSexualObjects.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ṣugbọn awọn kan faramọ fidio orin naa, ti wọn si n kan saara si Olamide.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, Aarẹ ẹgbẹ nọọsi, Abdrafiu Adeniji sọ pe isẹ Oluwa ni isẹ awọn olutọju alaisan ati igbẹbi.

"Olamide ba wa l'orukọ jẹ ni, o si ta epo si aṣọ ala iṣẹ wa".

O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe iru awọn iwa bẹ ẹ jẹ ọkan lara awọn nkan ti ofin iṣẹ nọọsi ko faaye gba.

Àkọlé fídíò, Mo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen

"Ijiya si wa fun olutọju alaisan kankan to ba lo ipo rẹ gẹgẹ bi olutọju lati gbiyanju tabi ni ibalopọ pẹlu alaisan to n tọju."

Nibi ti nkan de duro bayii, sọ pe awọn agbaagba ẹgbẹ awọn nọọi ti n ṣé ipade lori orin ti Olamide kọ, lati mọ igbesẹ to yẹ lati gbe.

O fi kun pe Olamide yoo f'oju ba ile ẹjọ lori orin naa.

Igba akọkọ kọ niyii ti ẹnu ti kun Olamide Baddo lori awọn orin rẹ.

Lasiko to gbe awọn orin Pata ni Logo Benz jade, ọpọ eeeyan lo bu ẹnu atẹ lu u pe orin rẹ lo fa bi awọn kan ṣe bẹrẹ si ni ji pata obinrin lati fi ṣe aajo owo.