Ibadan Sallah Killing: Ẹbí ọmọ tí wọ́n rí òkú rẹ̀ nínú odò ní Ibadan ní ikú rẹ̀ kìí ṣe ojú lásán

Inu odo ti wọn ti ri oku ọmọ naa
Àkọlé fídíò, Ẹbí ọmọ ọdún méjì tí wọ́n rí òkú rẹ̀ nínú odò ní Ibadan sọ pé ikú rẹ̀ kìí ṣe ojú lásán

Ẹbi ọmọ ọdun meji to di awati ni ọjọ ọdun Ileya ku ọla, Sukurat Arowolo, ti wọn si pada ri oku rẹ ninu odo kan ni adugbo Olodo ni Ibadan ti kẹdun iku rẹ.

Ẹgbọn baba rẹ to ba BBC sọrọ, Arakunrin Sarafa Arowolo, sọ pe okuta kan ninu odo naa lo da oku ọmọ naa duro lati ibi ti omi ti n gbe bọ.

Bakan naa ni alagbatọ rẹ, to tun jẹ iyawo ẹgbọn baba rẹ, Arabinrin Arowolo sọ pe, iku ọmọ naa dun oun pupọ, nitori pe "inu kan ni oun fi gba a lati ma a tọju pẹlu awọn ọmọ oun."

O ṣalaye pe eroja ọbẹ̀ ọdun ni oun lọ ọ ra, ti ọmọ si ti di awati ki oun o to o de, botilẹjẹ pe oun ati awọn ọmọ miran lo jọ n ṣere niwaju ile.

Ni nkan bi aago mẹjọ alẹ ọgbọnjọ, oṣu Keje, ọdun 2020 ni ọmọ naa di awati, ni ile wọn to wa ni adugbo Ahoyaya ni agbegbe Olodo niluu Ibadan.

Gbogbo awọn aladugbo ati alagbatọ lo fọn sita lati ṣe awari ọmọ naa titi di oru ọdun Ileya ti igbiyanju wọn si ja si pabo.

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di owuro ọjọ ọdun ileya ni ariwo sọ lasiko ti ọmọde kan fẹ lọ ṣe igbọnsẹ nibi odo nla kan to n bẹ ni adugbo naa.

Nibẹ lo ti kan oku Sukurat to lefo sinu omi. Igbe ọmọde yii ni awọn ara adugbo gbọ ti wọn si fi mọ pe ọfọ ti ṣẹ.

Ikọ BBC Yoruba ṣe abẹwo si agbegbe naa l'ọjọ Iṣegun, ohun ti a fi oju ri si ba ni lọkan jẹ pupọ.

Àkọlé fídíò, Ibadan Death: Àwọn ará àdúgbò Akinyele ké sita lórí iṣékúpani tó ń wáyé ní ìlú Ibadan.
Ilu Ahoyaya

Ohun akọkọ ti a le fi idi ẹ mulẹ ni pe ọmọde naa ko gbe ọdọ awọn obi rẹ.

Ọdọ ẹgbọn baba rẹ lo n gbe ti onitọun si n tọju rẹ pẹluu awọn ọmọ tirẹ naa.

Ohun ti wọn tun sọ fun wa ni pe lati igba ti wọn ti bi ọmọ naa ni iya rẹ ti n ṣaisan, ilu Ondo, Ọrẹ si ni o n gbe. Eyii lo si mu ọmọ naa di ero ile ẹgbọn baba rẹ.

Iyale iya ọmọ naa ti o ba wa sọrọ, Arabinrin Arowolo ṣe alaye wi pe ọmọ naa ati awọn ọmọ oun ni wọn jọ n ṣere ni iwaju ṣọọbu wọn ni ọjọ ọdun ileya ku ọla ki o to di wi pe wọn ko dede rii mọ laarin awọn ọmọ to ku.

Ẹni ti Sukurat n gbe lọdọ rẹ

O tẹsiwaju wi pe ata ọdun ni ohun lọ ra lasiko ti ọmọ naa ati awọn ọmọ oun jọ n ṣere ni iwaju ita, bẹẹ sini oun sọ fun aburo ọkọ oun kan lati mojuto wọn.

O ni, " Ibi ti mo joko si naa niyẹn pe ọla ni ọjọ Aje, gbogbo nnkan le lọju pọ ni ibi alata. Mo wa lọ ba iya ti wọn n ta ata ni adugbo wa, mo ṣaa lọ ra ata ẹgbẹrun meji o le lẹẹdẹgbẹta naira".

"Ki n to wa lọ ra ata yẹn mo mu ọmọ yẹn da ni mo fun ẹni to jẹ aburo ọkọ mi pe ki wọn maa ba mi wo ọmọ yii, kii ṣe oun nikan lo wa nibẹ wọn pọ ati awọn ọmọ temi naa ti gbogbo wọn n jo. Ṣugbọn bi ọmọ yẹn ṣe sọnu o ye Ọlọrun ọba to jọ ṣẹda emi ati ẹ".

Ẹgbọn baba ọmọ naa to ba wa sọrọ, Arakunrin Sarafa Arowolo sọ fun wa pe aṣọ ọdun mẹta ọtọọtọ ni wọn ran fun ọmọ naa lọjọ ọdun ku ọla. Gbogbo rẹ lo si wọ wo.

O ni o jẹ nnkan ibanujẹ wi pe awọn olubi ẹda naa ko jẹ ki Sukura wọn aṣọ ọdun rẹ.

Inu odo ti wọn ti ri oku ọmọ naa

Arowolo fi kun ọrọ rẹ wi pe nigba ti ariwo sọ ni awọn to mọ pe ninu odo kan to n bẹ ni adugbo naa ni wọn sọ oku ọmọ naa si.

O ni awọn ba ẹjẹ lẹnu rẹ nibi ti o lefo si ninu omi.

Leyin ọrẹyin ni wọn sinku ọmọ naa si ẹba ọdọ ti wọn ti ri oku rẹ.

Nibayii ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti tẹ afurasi kan, bẹẹ sini iṣe iwadii ti n ọ lọwọ lorii ẹsun naa.

Àkọlé fídíò, 'A ò tíì rí omi mu, ẹ ní ká máa fọwọ́ tóríi Coronavirus'