Ibadan Sallah Killing: Àwọn tó ṣojú wọn kòró bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, Ọlọ́pàá fèsì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba ti ikọ iroyin BBC Yoruba kan si ileeṣ Ọlọpaa ilu Ibadan lori iku awọn ti a gbọ pe aṣita ibọn ọlọpaa lo pa wọn, awọn ọlọpaa naa ko alaye wọn ṣe.
"A rii ti awọn janduku kan n ṣe ikọlu si awọn ara ilu ni agbegbe Oke-Are, awn ọlọpaa si gbe igbesẹ kia pẹlu ọkọ wọn ti wọn gbe lọ sibẹ lati koju iṣẹlẹ naa".
Wọn ṣalaye pe ni kete ti awọn adigunjale ọhun ri ọkọ ọlọpaa, wọn ṣina ibọn bolẹ si awọn lọrọ ba di ogun.
Ọlọpaa ni lasiko wahala yii ni wọn yinbọn pa meji ninu wọn ti wọn si gba awọn ibọn ati roolu ọta ibọn lọwọ wọn.
Wọn ti gbe oku awọn mejeeji lọ si ile igbokupamọsi Adeoyo to wa ni Ring Road nIbadan fun ayẹwo ti eeyan kan to ku to fara pa si ti wa ni ile iwosan fun itọju.
Nigba ti akọroyin BBC sọ iha ohun ti awọn ara adugbo sọ fun alukoro ọlọpaa pe jẹjẹ ni awọn meji to ku hun n ṣe faaji ọdun Eid lọwọ, esi ti o fọ ni pe "a n ṣe iwadii lọwọ, a o si fi ọrọ sita bi a ba ṣe tan".ng Salah.
Àṣìta ìbọn àwọn Ọlọ́pàá ló gbẹ̀mí àwọn èèyàn tó kú lọ́jọ́ ọdún Eid n'Ibadan - Ará Àdúgbò
Awọn olugbe agbegbe Oke-Arẹ niluu Ibadan ti ṣe alaye ọrọ wipe aṣita ibọn awọn ọlọpaa to tọ pinpin awọn ọdaran kan wa si gbegbe naa l'Ọjọ Abamẹta lo ṣekupa awọn eeyan meji kan ni bii aago mẹwa owurọ nibi ti wọn ti n ṣe faaji ọdun.
Ikọ BBC Yoruba ṣe abẹwo si agbegbe naa l'owurọ Ọjọ Aiku lati mọ ohun to ṣẹlẹ gaan.

O ṣoju mi koro to ba wa sọrọ ṣe alaye wi pe awọn janduku kan to n yọ awọn ontaja iṣu lẹnu ni agbegbe Bẹẹrẹ ni awọn ọlọpaa lati Mapo le wa si agbegbe Oke-Arẹ ti wọn si n yin ibọn soke.
Iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe "eeyan kan lara awọn to n ṣe faaji ọdun ni aṣita ibọn ti awọn ọlọpaa yin si awọn ọdara naa ba, ti awọn ero to wa nibi ode ariya naa si bẹrẹ sini lẹ oko mọ awọn ọlọpaa naa".

- Ọtí tí wọ́n fi Sanitáísà àti Methanol pò pọ̀ ṣekú pá èèyàn 86
- A ó san ẹ̀san ire fún ẹbí Richard, a ó sí san owó gbogbo ètò ìsìnkú - Iléesẹ́ ọṣẹ tí akẹ́kọ̀ọ́ UI kú sí
- Àgbà òṣèré tíátà míràn tún jáde láyé!
- Àwọn olùdíje ètò ilé Ẹlẹ́gbọ́n Àgbà BBNaija 2020 wo ni wọ́n yóò fọwọ́ òsì júwe ilé fún lòníì?
- Bí a bá gbáa yín mú tí ẹ́ ju Ààdọ́ta olùjọ́sìn lọ pẹ́rẹ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì... - Sanwo-Olu
Eyii lo mu ki awọn ọlọpaa ṣiju lara awọn ọdaran ti wọn le wa gaan ti wọn si bẹrẹ sini dojukọ awọn ero to n lẹ oko mọ wọn nipasẹ ẹni akọkọ ti aṣita ibọn ba.

Ibọn ti awọn ọlọpaa tun yin ninu laasigbo naa lo ṣe akoba fun eeyan meji mii ni agbegbe naa.
Awọn ara adugbo to ba BBC Yoruba sọrọ tọka wa si awọn ikorita ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Wọn ni eeyan meji lo gbẹmi mi loju ẹsẹ ti ẹni ikẹta si wa ni ẹsẹ kan aye - ẹsẹ kan ọrun.
Titi di owurọ oni, apa ibọn ati ẹjẹ awọn oloogbe ṣi wa ni agbegbe naa.
Ohun ti iṣẹ iwadii fi mulẹ ni wi pe mẹta ninu awọn ọlọpaa to wa lati gbegbe Mapo lo le awọn ọdaran wa si agbegbe Oke-Arẹ ti ọrọ si di bamii.
A gbiyanju lati ba alukoro ilẹẹṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ sọrọ lorii ẹsun naa lasiko ti a ṣe akojọpọ iroyin yii, ṣugbọn Arakunrin Olugbenga Fadeyi to n ṣoju ajọ naa ko gbe ipe ago rẹ.














