Yoruba Nollywood: Àgbà òṣèré tíátà, Musiliat Arikeusola 'Osuntoun' jáde láyé

Oríṣun àwòrán, OTHER
Iku tun ti mu ọkan gboogi laarin awọn agba oṣere tiata Yoruba lorilẹede Naijiria, Alhaja Musiliat Arikeuọọla ti ọpọ mọ si Ọṣuntoun lọ.
Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ, opin ọsẹ yii naa ni Alaaja Ọṣuntoun jade laye lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.
- Àwọn olùdíje ètò ilé Ẹlẹ́gbọ́n Àgbà BBNaija 2020 wo ni wọ́n yóò fọwọ́ òsì júwe ilé fún lòníì?
- Bí a bá gbáa yín mú tí ẹ́ ju Ààdọ́ta olùjọ́sìn lọ pẹ́rẹ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì... - Sanwo-Olu
- Ọtí tí wọ́n fi Sanitáísà àti Methanol pò pọ̀ ṣekú pá èèyàn 86
- Láti 462 sí 386, àwọn tó ní àrùn Covid-19 já wálẹ̀ ní Nàìjíríà lọ́jọ́ Àbámẹ́ta
- Dúkìá àti ọjà jóná ráúráú lásìkò tí iná sọ ní ọjà Mushin ní Eko
Ko si ẹni to ba n wo awọn ere ibilẹ Yoruba to kun fun aṣa, iṣe ati igbagbọ ẹya Yoruba ti ko ni mọ mama, Ọṣuntoun paapaa julọ nitori awọn ipa awọn "ẹlẹmi agba" to ko ninu awọn ere oloogbe Yẹkini Ajilẹyẹ.
Ile rẹ lagbegbe Ijẹtu nilu Osogbo ni Mama dakẹ si.
Akọwe fun ẹgbẹ awọn onitiata ni ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adedokun fi idi iroyin iku rẹ mulẹ fun awọn oniroyin.
Lara awọn ere ti oloogbe Osuntoun ti kopa ni Koto Orun, Aye Akamara, Koto Aye, ti gbogbo rẹ jẹ latọwọ oloogbe Ajilẹyẹ.
Oloogbe Ọṣuntoun funrarẹ naa gbe awọn ere kan jade bii 'Omi Ipin,' 'Imi Esin' ati 'Ogun Omo Iya le', to jẹ ere ti o ṣe gbẹyin, gẹgẹ bi ọgbẹni Adedokun ṣe sọ.









