Dúkìá àti ọjà jóná ráúráú lásìkò tí iná sọ ní ọjà Mushin ní ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, lasema
Ina sọ lapakan ọja awọn to n ta ibusun ni agbegbe Ladipo ni Mushin ni ilu Eko lọjọ Abamẹta.
Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ ajalu ati pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA ṣalaye pe ṣọọbu ti wọn ti n ta ibusun kan nibẹ ni ina naa ti kọkọ sọ ki o to ran de awọn ṣọọbu itaja miran to sun mọ ọ.

Oríṣun àwòrán, Lasema
Amọṣa ajọ LASEMA ni awọn oṣiṣẹ alaabo ati adoola ẹmi tete de ibẹ lati pana naa ki o to ṣe ọṣẹ ju bo ṣe yẹ lọ.
Oludari agba ajọ LASEMA, Olufẹmi Oke- Ọsanyintolu ṣalaye pe ipenija nla ni ọrọ ilekanle, orule-kan-orule n mu ba ilakaka ati koju ijamba ina ni ipinlẹ Eko.
Ajọ naa fi kun un pe ko si ẹnikẹni to padanu ẹmi sinu ijamba ina naa.









