FA CUP FINAL 2020: Lacazette ṣàlàyé ìdí tí Arsenal ṣé gbọ́dọ̀ fìdí Chelsea rẹmi ní àṣekágbá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Idojuti nla ni yoo jẹ ti a ko ba le gba ife ẹyẹ FA Cup tori naa, tọkan tọkan laa fi n reti ifẹsẹwọnsẹ wa pẹlu Chelsea ninu aṣekagba idije FA Cup ti yoo waye loni.
Atamataṣe ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Alexander Lacazzette lo sọ bẹẹ, to si ni awọn ko fẹ ki ife yi bọ mọ awọn lọwọ.
O ni ohun nikan lọna kan to ku, tawọn ko fi ni di ẹni yẹyẹ ni saa bọọlu ọdun yi.
Bi Arsenal ba kọ lati fidi Chelsea rẹmi, wọn ko ni le tẹsiwaju lati kopa ninu idije Europa League ọdun yii.
Lọwọlọwọ, ipo Kẹjọ ti wọn wa lori afara ti ja wọn ni ireti ṣugbọn ti wọn ba fi le na Chelsea ni Wembley, wọn yoo lanfaani lati kopa ninu idije Europa.
Lacazette sọ pe ''A padanu awọn anfaani kan to yẹ ki a fi gbegba oroke''

Oríṣun àwòrán, Reuters
''Saa bọọlu yii ko rọgbọ, a ti paarọ akọni-mọọgba wa, a ni isinmi ọlọjọ-gbọọrọ, a tun parọ awọn agbabọọlu wa kan''
O ni toun ti pe saa bọọlu yii jẹ ọkan lara awọn to gbomi mu fun oun, oun wa gbegba oroke ni Arsenal n,i nitori naa, ''ife FA Cup ṣe pataki gan ni gbigba''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọnimọọgba ikọ Chelsea Frank Lampard ati akẹgbẹ rẹ Mikel Arteta jijọ n gbiyanju lati gba ife yii ni igba akọkọ wọn, bi akọnimọọgba.
Arsenal ti gba ife ẹyẹ FA Cup ni igba mẹtala sẹyin.












