Man United vs Chelsea: Chelsea fún Man U lóújẹ àbùkù jè, Cuppy bínú yí jọ̀lọ́ọ̀fù dànù

DJ Cuppy
Àkọlé àwòrán, DJ Cuppy binu fi Arsenal silẹ, o gba Man U lọ laimọ pe, ohun to n bẹ lẹyin Efa....
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

DJ Cuppy binu fi Arsenal silẹ, o gba Man U lọ laimọ pe, ohun to n bẹ lẹyin ẹfa....

Arsenal ti lu Man City wọ FA Cup final, Man United ti DJ Cuppy sa lọ fìdí rẹmi

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ṣe ẹkọ nla kọ ni yii pe nigba miran o san ki eeyan kuku maa faradaa pẹlu eṣu to ti mọ tẹlẹ ju angẹli ti oo tii mọ iwa to maa hu to ba ya lọ.

ati pe awọn miran ni igba miran, ibi ti eeyan wa tẹlẹ maa n san ju ibi tuntun lọ ti eeyan ko ba kiyesara.

Àkọlé fídíò, Human trafficking: Ààrẹ Buhari, ẹ̀yin gómìnà ìpínlẹ̀ Yorùbá, ẹ rántí wa ní Oman, àwọn ọmọ

De Gea y'ẹ́yin, Man United k'àbùkù lọ́wọ́ Chelsea, Cuppy já pa

Man United vs Chelsea: De Gea y'ẹ́yin, Man United k'àbùkù lọ́wọ́ Chelsea, Cuppy já pa!

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ni yoo koju ikọ Arsenal ninu aṣekagba idije FA Cup saa yii ti yoo waye lọjọ Kinni oṣu Kẹjọ ọdun 2020.

Chealse

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Wembly ya!

Inu ifẹsẹwọnsẹ to waye lalẹ ọjọ Isinmi ni ẹkọ ti foju mimu han lẹyin ti Chelsea bo Manschester United lẹgba ami ayo mẹta si ọkan ṣoṣo.

Olivier Giroud lo kọkọ ṣide eto nigba to rẹyin awọn Man United nigba to ku diẹ ki abala akọkọ ifẹsẹwọn ọhun wa sopin.

Ko pe ti abala keji ifẹsẹwọnsẹ ọhun bẹrẹ ti Mason Mount naa tun dana sun ile Manchester United lẹẹkeji.

Goolu kẹta latọwọ Harry Maguire lo mu ko di mẹta.

FA Cup

Oríṣun àwòrán, @YACMediaProd

Nigba to ku iṣẹju marun un ki ifẹsẹwọnsẹ naa wa sopin ni Bruno Fernandes ṣe bi ọkunrin, to si da goolu kan pada sinu awọn Chelsea, ṣugbọn o ti bọ sori.