BBNaija: Terry Waya sọ oun tó fojú Kiddwaya rí nílé nígbà tó ń bẹ̀bẹ̀ láti lọ BBNaija

Kiddwaya ati Baba rẹ Terry Waya

Oríṣun àwòrán, @TERRYWAYA/@KIDDWAYA/INSTAGRAM

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 16

Baba ọkan lara awọn akopa ninu eto agbelewo Big Brother Naija Kiddwaya ton jẹ Terry Waya ti sọrọ lori bi ọmọ rẹ ṣe n ṣe ninu ilee ẹlẹgbọn agba.

O sọrọ ninu eto ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu oludasilẹ Ovation Dele Momodu nibi to ti sọ pe oun ko tilẹ mọ nipa eto agbelewo yii tẹlẹ oun ko si tete fi atilẹyin oun hannigba ti ọmọ oun fẹ lọ kopa.

"Tẹlẹ, oun naa lo maa n ṣe ọpọlọpọ nkan nile, oun lo n san owo ileewe awọn aburo rẹ. Ilu London ni mo ran an ko lọ afi ti mo ji ti lọjọ kan ti mo n wa a ni wọn ni o ti lọ si Eko, ọrẹ mi lo ṣeto baalu to gbe e lọ ti mi o si mọ".

"Nigba to pada de, mo ni ko lọ ya ara rẹ sọtọ fun ọjọ mẹwaa tabi sẹ meji". Terry Waya ni igba ti Kiddwaya wa ba oun pe o fẹ lọ kopa nilee ẹlẹgbọn agba, oju ti oun fi wo o gan, ṣe lo pa ẹnu mọ.

O ni gbogbo awọn ọrẹ oun wa n pe oun pe nkan to fẹ ṣe niyẹn ṣugbọn ti emi o fẹ ki ẹnikẹni ba mi sọrọ nipa rẹ.

Dele Momodu

Oríṣun àwòrán, Dele Momodu

Waya ni ṣe ni Kiddwaya bẹrẹ si ni fi ọrọ ran awọn aburo ati ẹgbọn oun lati ibi to ti ya ara rẹ sọtọ ki wọn to wọ ilee Biggie ki wọn ba a bẹ baba rẹ.

"Awọn aburo pe mi lori foonu pe o ni ọkan oun daru nibi to ti ya ara rẹ sọtọ to si ni bi oun ko ba gba ibukun lẹnu mi, oun ko ni lọ, ni wọn ba n bẹ mi pe ki n fi aṣẹ sii".

O fi kun un wipe awọn kan n rojọ kiri pe oun n ra ibo fun ọmọ oun ṣugbọn irọ ni wọn n pa. O ni ibo awọn ọmọ Naijiria lo ṣi jẹ ko wa nibẹ.

O ni nkan meji loun mọ pe ọmọ oun nifẹ si gan, ọrọ oun ti awọn obinrin n la kọ́ja atawọn ọdọ ti wọn n fipa ba lopọ.

"Mo fẹ ki o jawe olubori ko lee ṣamulo owo to ba ri daadaa. Ṣugbọn bi ko ba si bori, gbogbo atilẹyin ti awọn ọmọ Naijiria n fun un wu mi lori jọjọ".

Àkọlé fídíò, Bí rere ni àbí búburú, wo ohun tí Covid-19 leè ṣe sí àgọ́ ara rẹ

Nigba ti Dele Momodu bi i nipa Erica, o rẹrin o ni:

"Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ mi, ilumọọka ni mi ni Naijiria, gbogbo ibi ti mo ba wọ ni ile mi, ko si si ibi ti mi o ti ni ọrẹ timọtimọ ni Naijiria torinaa ko si ibi ti awọn ọmọ mi ba yan lati tẹdo si ti wọn o ni ri ibukun mi ko si ni fi ṣe ede, ẹya. Ohunkohun to ba yan, ki n kan ṣaa ti fun un ni ibukun baba ni".

Ohun tó ṣẹlẹ̀ láàrin Ozo àti Nengi olórí àti igbákejì nílé BBNaija rèé

Awọn ololufẹ eto ile ẹlẹgbọn agba, BBNaija ti n sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ laarin olori ile, Ozo ati igbakeji rẹ, Nengi lalẹ Ọjọru mọju Ọjọbọ.

Awọn kan tiẹ n binu tẹlẹ pe BBNaija ko ri fọnran ohun to ṣẹlẹ laarin Ozo ati Nengi wo.

Ọpọ lo fẹ ri bawọn mejeeji ti jọ sun pọ ninu ile Ozo to jẹ olori ile.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ṣugbọn ẹrọ ayaworan kamẹra ko ṣafihan ohun to n lọ laarin awọn mejeeji.

Amọ, laarọ Ọjọbọ lawọn eeyan ri fidio kan ninu eyi ti Nengi ti gbagbe irọri rẹ to fi ṣami aye rẹ lori ibusun pẹlu Ozo.

Ki Ozo to di olori ile ati Nengi di igbakeji, awọn mejeeji ko tii jọ sun papọ ri lori ibusun kan naa, bi o tilẹ jẹ pe wọn sun mọ ara wọn.

Ṣugbọn ohun to jẹ ki ọpọ ololufẹ eto BBNaija nipa awọn mejeeji ni pe Ozo nífẹẹ Nengi, amọ Nẹngi ni oun ko fẹ ni ololufẹ ninu ile ẹlẹgbọn agba BBNaija.

Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'

Kíákíá lọ daṣọ bo igbá àyà rẹ to ṣí kalẹ̀! -Big Brother sọ fún Dorathy

Dorathy fẹ́ da orí Big Brother rú pẹ̀lú ẹrù àyà rẹ̀, ló bá yáa ní kó lọ pàrọ̀ aṣọ

Okun ọrun ko yẹ adiẹ, ohun ti a ba si gbe pamọ lo n niyi.

Idi ree ti Big Brother ninu eto ile ẹlẹgbọn ọn agba ti ṣe ni ki ọkan lara awọn oludije, Dorothy wọle lati lọ paarọ asọ to wọ.

Aṣọ to wọ fi igba aya Dorothy han pupọ ti gbogbo awọn ohun to fi n ṣe oge si n han kedere fawọn oluworan.

Kaakiri oju opo ayelujara paapaa ni Instagram lawọn eeyan ti n ṣe alabapin fidio ibi ti Big Brother ti paṣẹ ki Dorothy lọ parọ aṣọ fun yi.

Iṣẹlẹ yi waye lasiko to pe Dorathy wa si inu iyara ijiroro ''Diary Room''

Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Iná sọ nínú ilé Big Brother tó ń lọ lọ́wọ́ ní Cameroon

Ina kan ṣẹyọ ninu ile ti wọn ti ṣe eto Biggy 237 ni Cameroun, ṣugbọn ẹnikẹni ko ṣeṣe.

Alẹ Ọjọbọ ni ina ọhun deede ṣeyọ ni yara idana, ṣugbọn awọn olukopa ninu eto naa korajọ lati tete pa a.

Adari eto Biggy 237, Cyril Akonteh sọ fun BBC pe ina ọhun bẹrẹ lati inu apoti amu-ounjẹ gbona makirowefu ti wọn lo ni ilokulo.

O ni "Ibẹrubojo kọkọ gba ọkan awọn olukopa to wa ninu ile naa, ṣugbọn wọn pa ina ọhun, ohun gbogbo si pada bọ sipo."

Wo bi ina naa ṣe bẹrẹ:

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Orilẹ-ede Cameroun bẹrẹ idije Biggy 237 lọjọ Kejilelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Teach your children Yoruba: Wo àwọn òyìnbó tó ń kẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ní Michigan, America

Eto naa da lori bi awọn ọmọ orilẹ-ede Cameroun to n sọ ede Gẹẹsi ati ede Faranse ṣe le gbe papọ.

Eto Biggy 237 farajọ eto Big Brother Naija to n lọ lọwọ ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Lilo sọ òtítọ́ fún Ebuka lórí ìbáṣepọ̀ òun àti Eric:

Ọkan lara awọn olukopa ninu idije BBNaija 2020, Boluwatife Aderogba, ti ọpọ eeyan mọ si Lilo ti sọ pe oun kabamọ ibaṣepọ oun ati Eric lori eto agbelewo naa.

Lilo lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu atukọ eto ọhun, Ebuka, lẹyin ti wọn fi ọwọ osi juwe ile fun un lori eto naa.

Lilo Aderogba

Oríṣun àwòrán, Lilo Aderogba/Instagram

O ni ifẹ ti oun ni si Eric ti oun ṣalabapade lori eto naa jẹ ki oun sọ afojusun oun nu.

Ẹni ọdun mẹtelogun ọhun ni "Ninu iwoye mi, o dabi ẹni pe mo jẹ ki ifẹ ọkan mi bori idi Pataki ti mo fi lọ sori eto naa mọlẹ."

Àkọlé fídíò, Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀
Ile Ẹlẹgbọn Agba

Oríṣun àwòrán, BBNaija

O ni oun tete yofẹẹ Eric lori eto, ati pe oun lo kọkọ fi ẹnu ko o lẹnu nigba ti ere ifẹ wọn bẹrẹ.

Bo tilẹ jẹ pe o wu lati wa lori eto naa sibẹ, Lilo ni inu oun dun lati fi ori ọhun silẹ ni kiakia, nitori oun ko mọ oun ti oun n ṣemọ latari ibadọrẹ oun ati arakunrin Eric naa, ọrọ si ti n kọja oju ẹ.

Nigba ti Ebuka bere lọwọ rẹ boya o kabamọ ere ifẹ rẹ ati Eric, Lilo sọ pe "ehmm… a ko lee pe ni ikabamọ naa… ṣugbọ mo mọ pe mo ṣu saga."

Lilo ni oun ko ni ya oun lẹnu ti Eric ba bẹrẹ ere ifẹ pẹlu ẹlomiran lẹyin ti oun kuro lori eto BBNaija 2020, ṣugbọn yoo dun oun.

Lẹyin naa lo ni kii ṣe ohun toju ko ri ri nitori aye n ṣe iru ẹ, o sit un tọrọ aforiji lọwọ awọn ololufẹ rẹ.

Lilo ati Ka3na ni wọn kọkọ le danu lori eto BBNaija 2020 lẹyin ti awọn ololufe eto naa atawọn akẹgbẹ wọn lori eto ọhun fawọn kalẹ gẹgẹ bi awọn ti asiko ti to fun lati pada sile.

Àkọlé fídíò, 'A ò tíì rí omi mu, ẹ ní ká máa fọwọ́ tóríi Coronavirus'

Wò àpapọ̀ àwọn tó ti ní ibalopo lórí ètò BBNaija to ń lọ lọ́wọ́

Eica ati Kiddwaya

Oríṣun àwòrán, @BBNaija/twitter

Ariwo Erica ati Kiddwaya ni awọn eeyan tun n pa lori ayelujara bayii.

Eyi ko ṣẹyin fidio kan ti awọn ololufẹ eto naa fi sita loru oni mọju, to si ṣafihan awọn 'ololufẹ' mejeeji nibi ti wọn ti n 'fun ara wọn ni eso ifẹ jẹ'.

Lẹyin eto ti wọn ti le Lilo ati Ka3na pada sile lalẹ ọjọ Aiku, ni iṣẹlẹ naa waye.

Ori aga ijoko ni awọn mejeeji ti kọkọ bẹrẹ, ti wọn si n fi ọwọ pa ara wọn lara. Koda, idi Erica ṣi silẹ ya-n-ya, ti ọwọ Kidd si bu idi naa so.

Lẹyin naa, ti gbogbo awọn olukopa to wa nile wọle lọ ọ sun, ni awọn mejeeji jọ wa pọ lori ibusun kan naa.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Bi awọn kan ṣe n sọ pe niṣe ni Kidd n ki ika si oju ara Erica, ni awọn kan sọ pe ibalopọ taara ni wọn n ni.

Ko tan sibẹ o, ninu fidio naa lo ti han bi Erica paapa n ke ha, yu, bi ẹni n gbadun nkan to dun.

Ṣugbọn ṣa, kii ṣe awọn mejeeji nikan lo ti jẹ ẹran ifẹ ni ori eto Big Brother Naija 2020.

Praise ati Ka3na lo kọkọ jẹ jẹ eso ifẹ.

Ọjọ Ẹti ni eyi waye lẹyin ariya alẹ ti wọn ṣe.

Ninu fidio to gba ori ayelujara, abẹ aṣọ ibora ni awọn mejeeji naa wa, to si jẹ pe bi ara wọn ṣe n lọ si ọtun, ati osi, lo fihan pe 'wọn n dan nkan wo'.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Iyalẹnu lo jẹ fun awọn ololufẹ wọn, nitori pe ko si adehun ifẹ laarin awọn mejeeji.

Ọpọ eeyan to si ti n ro pe 'tọkọtaya' naa yoo tun pada da wọn laraya ti ni ijakulẹ bayii, nitori pe Ka3na ti ja kuro ninu eto naa.

Ọrọ ibalopọ ko ṣẹṣẹ ma a waye laarin awọn olukopa ninu eto naa lati igba to ti bẹrẹ.

Idi ti Aisha Umaru ọmọ Hausa obinrin kan soso to wa ni BBNaija se fọ sẹkun.

Keisha

Oríṣun àwòrán, others

Ọkan ninu awọn akopa ninu idijẹ Big Brother tọdun 2020 to n lọ lọwọ̀, Aisha Umaru thi gbogbo eniyan mọ si Kaisha lo fọ sẹkun lasiko ifọrọwerọ pẹ ẹlẹgbọn agba ninu yara.

Fun nkan to da bi ẹni pe akopa yii ko ni le farada iṣẹlẹ to ba gbona janyinnjanyin nile ẹlẹgbọn ọn agba oo, lẹyin ọjọ meji pere Kaisha ni awọn alabosi lo pọ ju ninu ile.

Nigba ti ohun ẹlẹgbọn ọn agba fọ si i pe kini ero rẹ nipa awọn ọmọ ile to ku ati pe bawo lo se n ṣe pẹlu wọn.

Aisha ni: "Alabosi ni gbogbo wọn, ẹgbọn agba, lonii awọn kan o ṣe daadaa si ọ, to ba di ọla eni naa a tun maa huwa baami."

Ọsẹ mẹwaa gbako ni wọn o lo ninu ile Big Brother ẹlẹkaarun yii, se Kaisha yoo le farada lato duro bayii lati gba ife ẹyẹ eto yii.

Àkọlé fídíò, Oronpoto Animation: Akin Alabi ní kò dára bí eré aláwòrán fáwọn ọmọdé ṣe jẹ́ aláwọ̀ funfun

Tani Kaisha ọmọbìnrin Hausa yii?

Aisha Umar jẹ ẹni ọdun marunlelogun, onisowo ni lati ipinlẹ Sokoto.

O ri ara rẹ bi ajumọ bani ṣiṣẹpọ to se e gbọkanle to si le ba ẹnikẹni ṣe.

O nigbagbọ ninu ki eniyan jẹ ounjẹ to se ara loore.

O ni oun le jẹ ẹni to ni lọwọ sugbọn nkan maa n tete dun oun lọkan.

O fẹran lati maa kọrin, ko maa jade, ko si maa gbadun ara rẹ.

Kini awon eniyan n sọ nipa ẹkun rẹ:

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Bi awon kan se n kii, ni awọn mii n buu pe ki lo muu.

Bi awọn kan se n sọ pe o dara bo se jẹ Hausa to jade sita niru eto bẹẹ ni awọn mii ni ko si ninu asa ọmọbinrin Hausa lati kopa ninu iru eto bii BB Naija yii.

Alẹ́ ọjọ́ Aiku ní a o mọ ẹni ti yóò fi ilé ẹlẹ́gbọ́n ọn àgbà sílẹ̀

Kiddwaya, Lilo, Wathoni, Eric, Tolanibaj jètè àrà awọn lásìkò àríyá àkọ́kọ́

Oríṣun àwòrán, Bigbrother

Kiddwaya, Lilo, Wathoni, Eric, Tolanibaj ṣe bẹbẹ lásìkò àríyá Sátide àkọ́kọ́ ní Big Brother Naija 2020

Kiddwaya, Lilo, Wathoni, Eric, Tolanibaj jètè àrà awọn lásìkò àríyá àkọ́kọ́

Àwọn akópa nínú Ilé Ẹlẹ́gbọ́n Agbà ti ọdún 2020 ti ṣe ìfẹnukónu fún ìgbà àkọ́kọ́ lásìkò àríyá ti o má n wáye ni alẹ́ ọjọ sátide.

Kiddwaya, Lilo, Wathoni, Eric àti Tolanibaj ló ń jètè àra wọ́n lásìkò àríya sátide àkọ́kọ́ lórí móghùmáwòràn ti gbogbo ènìyàn si ń ni ànfani láti maa wò wọ́n bí wọ́n ṣe.

Àwon wọnyi ni ẹni àkọ́kọ́ ti yóò maa fi ìfẹ́ han si ara wọ́n láàrin ọjọ́ mẹ́fà ti wọ́n bẹ̀rẹ̀ ètò ọlọ́sẹ̀ mẹ́wàá ni a ti rí Kiddwaya, ọmọ baba olówó Terry Waya àti ìgbákeji olórí ilé Wathoni ti orúkọ rẹ̀ gan n jẹ́ Florence Wathoni Anyansi.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Kìí wá ṣe Wathoni àti Kiddwaya nikan lo fẹnukẹnu, Tolanibaj àti Kiddwaya náà tun ṣe bẹ́ẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ kan náà.

Skip X post, 7
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 7

Lilo àti Eric náà o gbẹ́yìn, kódà ìfẹnukẹnu ti wọ́n ni ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ wọ́n ń rojọ́ le lórí jùlọ lálẹ́ ọjọ́ sátide, èyí kò ṣẹ̀yìn bi àwọn méjèèjì yìí ṣe ti bẹ̀rẹ̀ eré ìfẹ́ wọ́n ni kété ti wọ́n ti wọ ilé ẹlẹ́gbọ̀n àgbá lọ́sẹ̀ tó kọ́já

Skip X post, 8
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 8

Lẹ́yìn àríyá alẹ́ ọjọ́ sátida àwọn ọmọ ilé elẹ́gbọ̀n àgbà ko pari fàájì wọ́n síbẹ̀, sùgbọ́n alẹ́ ọjọ́ Aiku ní a o mọ ẹni àkọ́kọ́ ti yóò fi ilé ẹlẹ́gbọ́n àgbà sílẹ̀.

Skip X post, 9
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 9

Big Brother Naija 2020 housemates: Ọlọ́lá jù lọ Terry Waya ni Bàbá Terseer Kiddwaya tó ń kópa nínú BBNaija 2020

Terseer

Oríṣun àwòrán, Others

Ọmọ Terry Waya to jẹ ọkan lara olowo to gbajumọ lorilẹ-ede Naijiria n kopa ninu Big Brother Naija 2020 ti ọtẹ yii ti wọn pe akọle rẹ ni 'Lockdown Season'.

Terseer Kiddwaya ni orukọ rẹ, o si jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn

Kiddwaya to wa lati ipinlẹ Benue jẹ oniṣẹ ara rẹ, to si juwe ara rẹ gẹgẹ bi ẹni to ni igboya, to rẹwa lọkunrin, to si n lakaka lati jẹ eniyan laye.

Amọ, o fikun un pe oun ni igberaga, bẹẹ si ni oun fẹran lati ma a rin irinajo.

Ẹni to ba bori ninu idije Big Brother Naija ti ọdun yii fi biliọnu marundinlaadọrun fi ṣe ara rindin.

Lasiko ifọrọwanilẹnuwo ni Kiddwaya sọ wi pe idaniloju ati ijọraẹniloju lo gbe oun de Big Brother Naija .

Ni bayii to wa ni Big brother Naija naa, afojusun rẹ ni lati gbadun ara rẹ ni ti ọdun 2020 yii.

O ni: 'Eniyan ko mọ igba ti ọlọjọ yoo de, nitori naa ṣe oun to yẹ, nitori ọjọ n lọ'

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

'Ohun ti mo ṣe to wu mi lori ni bi mọ ṣe ṣe ere idaraya to mu adinku ba bi mo ṣe sanra tẹlẹ.

Eyi dun mọ mi ninu, mo si fẹ ri pe mi o pada si ti tẹlẹ mọ'.

Baba Kidwaya, Terry Waya to jẹ gbajugbaja gbajumọ lawujọ, n gbe ilu London ni Ilẹ Gẹẹsi ni ibi to ti n ṣe kara-kata.

Ẹni ọdun marundinlọgọta ni Baba Kiddwaya, amọ o ti fi igba kan ko si panpẹ awọn agbofinro ni Ilẹ Gẹẹsi, ni ọdun 2006 si 2008.

Terry Waya wa lati ipinlẹ Benue ati ẹya Tiv to wa ni aarin gbungun orilẹ-ede Naijiria.

Laycon

Oríṣun àwòrán, Bigbrother Naija/Africa Magic

Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Laycon, akẹ́kọ̀ọ́jáde UNILAG tó ń kópa nínú BBNaija 2020

Laycon BBNaija 2020: Olamilekan ló pegedé jùlọ ni ẹ̀ka ìmọ̀ Phyilosophy ní fásitì UNILAG lọ́dún 2016

Ọkan lara awọn olukopa ninu idije BBNaija 2020, Olamilekan Agbeleshe ti inagijẹ rẹ n jẹ Laycon ni ẹni to pegede julọ ni ẹka imọ Phyilosophy ni fasiti ijọba apapọ to wa ni ipinlẹ Eko, UNILAG, lọdun 2016.

Iṣe orin takasufe ni ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn naa yan laayo, ilu Elko lo si fi n ṣe ibugbe.

Laycon sọ pe awọn eeyan ma n ṣi oun tumọ lọpọ igba, ṣugbọn ou kii ni ẹnikẹni ninu nitori oninu ire ni oun jẹ.

Lara awọn aṣeyọri ti Laycon ti ṣe sẹyin ni orin rẹ "Fierce," eyii to wa loke tente ninu awọn orin mẹwaa to lamilaaka ju lori ikanni MTV BASE fun oṣu mẹfa gbako.

Ọjọ kọkandinlogun oṣu Keje ọdun 2020 ni idije BBNaija 2020 bẹrẹ, ọpọ awọn ololufẹ eto ọhun lo si ti n reti iru awọn sinimna orita ti yoo ṣelẹ ninu ile naa lọdun yii.

Awọn olukopa ogun lo wọ inu ile naa nigba kan naa, ṣugbọn ẹnikan sọṣo ni yoo jaweolubori.

Dorothy

Oríṣun àwòrán, @Dorathy

Àkọlé àwòrán, Ta ni Dorathy Bachor?

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ojú òpó Instagram Dorathy Bachor gbaná lẹ́yìn tí ètò àgbéléwò BBNaija bẹ̀rẹ̀

Eto agbelewo ori amohunmaworan ti a mọ si BBNaija ti gbinaya bayii awọn ọmọ Naijiria si ti n fi ero wọn han lori awọn olukopa kọọkan.

Amọṣa Dorothy Bachor, ọkan lara awọn olukopa eto agbelewo naa laye n jẹ lẹnu bi iṣu bayii.

Oju opo intagram Dorathy ti gbina jẹ bayii pẹlu bi awọn to n tẹ lee loju opo naa ti gbera sọ lati igba to ti wọ inu ile ẹlẹgbọn agba fun eto agbelewo BBNaija.

Ọmọ ipinlẹ Delta ni Dorathy, o si ti jẹ ko di mimọ fun olugbalejo eto agbelewo naa pe, oun wa lati jaye ori oun lori eto naa ni.

Ni bi a ṣe n sọrọ yii, erongba yii ti n ni ipa lori oju opo rẹ to jẹ pe o le ni ẹgbẹrun mẹfa ati ẹgbẹta eeyan lo n tẹlee.

Nigba ti yoo fi di agogo meje alẹ ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje ti Dorathy farahan lori eto agbelewo BBNaija si agogo marun un owurọ Ogunjọ, oṣu keje, iye awọn eeyan to n tẹlee loju opo Instagram rẹ ti le ni ẹgbẹrun mọkandinlogoji.

Dorathy Bachor

Oríṣun àwòrán, dorathy bachor

Ta ni Dorathy Bachor?

Ọmọ ọdun mẹrinlelogn ni Dorathy Bachor ti o si jẹ agbanisiṣẹ ni ipinlẹ Delta.

O ni ileeṣẹ abaniraja SHOPFORME to da silẹ ni aṣeyọri to ga julọ ti oun ti ṣe.

aworan bbnaija saa karun

Oríṣun àwòrán, Instagram/africanmagic

Bawo ni ile BBNaija saa karun un yoo ṣe ri?

Ogun olukopa lo wọ inu ile ẹlẹgbọn agba fun eto agbelewo BBNaija lalẹ ọjọ kọkandinlogun oṣu keje.

Amọṣa wọn ko ni ijinasiraẹni. idi si ni pe wọn ti ṣe ayẹwo iṣegun fun wọn ti wọn si ti fi han pe wọn wẹ mọ lọwọ arun COVID-19.

Laarin ọsẹ mẹwaa ti wọn yoo lo ni ile naa, ẹgbẹgbọn agba, iyẹn Big Brother yoo maa fun wọn ni iṣẹ kan tabi omiran lati ṣe.

Lara awọn ofin to wa nilẹ fawọn olukopa lati igba ti eto naa ti bẹrẹ wa ni pe wọn ko lee ni ajọṣepọ kankan pẹlu awọn to wa ni ita ile naa.

Àkọlé fídíò, Lockdown updates: Naira Marley gbóríyìn fún Jude Chukwuka pẹ̀lú #1 míliọnù

Iyẹn ni pe ko saye ipe lori foonu tabi wiwo mohunmaworan.

Ni saa yii ko ni si aye fun akoko iwẹ apapọ, ti wọn da pe ni "Shower hour"

Dorathy Bachor

Oríṣun àwòrán, Bigbrother naija/africa magic

Bakan naa ni wọn tun wọgile eto apejọpọ awọn araalu fun iworan ati ifọrọwerọ pẹlawọn olukopa ti wọn ba fẹ gbọn ys kuro lori eto naa.

Ebuka ni yoo ṣi gbalejo eto apejọpọ ọjọ Aiku naa ni ile ẹlẹgbọn agba BBNaija naa

BBNaija

Oríṣun àwòrán, others

Wo díẹ̀ lára àwọn tí yóò kópa nínú ìdíje BBNaija ọdún yìí

Idije BBNaija ọdun 2020 ti gberasọ, oriṣiriṣi oju tuntun ti awọn ololufẹ BBNaija ko tii ri ri ni yoo si pe jọ sinu ile BBNaija lọdun yi.

Lara awọn oju tuntun naa ni:

Ozoemena "Ozo" Chukwu

Ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn ni Ozo lati ipinlẹ Imo.

Lara awọn aṣeyọri rẹ ni bo ṣe ba ajọ UEFA Federation ṣiṣẹ nilẹ Yuroopu.

Igbagbọ Ozo ni pe ko si ohun ti eeyan ko lee ṣe to ba ti ni igbagbọ.

Victoria "Vee" Adeyele

Olorin ni Vee, ipinlẹ Eko lo si fi n ṣebugbe ko to darapọ ile BBNaijia ọdun 2020.

Bo tilẹ jẹ pe ilu London ni wọn bi Vee si, ọdun 2019 lo tẹkọ leti lọ si lati tẹpa mọṣẹ orin to yan laayo.

Nelson Enwerem Prince

Oniṣowo ni Prince lati ipinlẹ Abia ilu Eko lo si fi n ṣebugbe.

Lara awọn ohun to n ṣe ni ẹṣọ ile, ṣiṣe iṣẹ ọna sara aṣọ atawọn nnkan miran to jọ mọ ṣiṣe ara lọṣọ.

Ẹni ọdun mẹrinlelogun ni Prince, igbagbọ rẹ si ni pe orukọ rere san ju wura ati fadaka lọ.

Àkọlé fídíò, Human trafficking: Ààrẹ Buhari, ẹ̀yin gómìnà ìpínlẹ̀ Yorùbá, ẹ rántí wa ní Oman, àwọn ọmọ

Wo ǹkan mẹ́fà tó lágbára nípa Ebuka Obi-Uchendu tó ń gbàlejò Big Brother Naija season 5

Igba kérin ree ti Ebuka Obi-Uchendu yoo gbalejo eto Big Brother Naija.

Ebuka jẹ agbohunsafẹfẹ lori ẹrọ amohunmaworan to ni awọn ololufẹ to pọ pupọ.

Ebuka BBNaija

Oríṣun àwòrán, @Ebuka

Àkọlé àwòrán, Ta ni Ebuka Obi-Uchendu tó ń gbàlejò BBNaija 2020?

Lọdun 2006 ni Ebuka kọkọ kopa ninu eto BB Naija fun igba akọkọ.

Ọmọ olowo jalumọ biliọnia ni, iyẹn Oloye Vincent Obianodo to ni ileṣẹ Young Shall Grow Transpot ni Ebuka fẹ.

Cynthia Obianodo ti Ebuka gbe sile ni iyawo lo sọ ọ di ana gbajugbaja oniṣowo oloko owo nla naa.

Ọlọpọlọ pipe ni Ebuka jẹ ni eyi to fi ṣe idanwo igbanisile iwe girama lati ipele iwe alakọbẹrẹ kẹrin.

Ebuka ko duro ka iwe alakọbẹrẹ de ipele iwe kẹfa rara ko to bọ si ti girama nitori pe o jafafa pupọ.

BBNaijia

Oríṣun àwòrán, @BBNaija

Àkọlé àwòrán, Awon omo inu ile ni season 5 n gbaradi

Agbofinro to dantọ ni Ebuka jẹ. Fasiti Abuja to jẹ ti olu ilu Naijiria ni Ebuka ti kọ ẹkọ nipa amofin to si tun lọ sile iwe awọn akọṣẹmọṣẹ lori ofin ni Bwari ni Abuja kan naa.

Lọdun 2010 ni Ebuka morile Washignton College of Law lati gba ipele oye keji ninu imọ ofin ni America.

aworan bbnaija saa karun

Oríṣun àwòrán, BBnaija

BBNaija tọdún 2020 gbéra sọ, wo ohun tó fi yàtọ̀ sí tọdún tó kù!

BBNaija 2020 ń bẹ̀rẹ̀ lónìí, wo gbogbo bí ètò Big Brother Naija yóò ṣe lọ àti ẹ̀bùn #85 mílíọ̀nù tó wà fún jíjẹ

Ẹlẹẹkarun eto Big Brother Naija lo n bẹrẹ lonii, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, ọdun 2020.

Ebuka Obi- Uchendu naa ni yoo ṣagbatẹru eto naa ṣugbọn lọtẹ yii, Ebuka ati ọkan ninu awọn olukopa miran ni wón yoo jọ dari ẹ.

Odun 2006 ni ebuka funra rẹ kopa ninu eto BB Naijia. ko to di oludari lati ọdun mẹta sẹyin ninu eyi ti wọn pe ni Gobbe, Double Wahala ati Pepper Dem.

Awọn ileeṣẹ Multi choice to n ṣe BBNaija ti ni ninu ifilọlẹ iṣide eto naa ni wọn yoo ti kede orukó ti BBNaija 2020 yoo jẹ .

Lara awọn ohun to sodo sinu ẹbun miliọnu marundinlaadọrin, N85m.

N85m ni olubori eto agbelewo naa yoo ko lọ sile lọdun 2020 yii pẹlu awọn nkan wọnyii.

  • Irinajo lọ si ilu Dubai fun eeyan meji
  • Ile filaati oniyara meji (2 bedroom apartment)
  • Irinajo lati lọ wo aṣekagba idije ife ẹyẹ Champions league, gbigba ohun mimu Pepsi fun ọdun kan, ohun amohuntutu Branded Chiller
  • Foonu igbalode OPPO RENO
  • Ọkọ ayọkẹlẹ Innoson G40
  • Irinajo afẹ lọ si ilu Dublin lorilẹede Germany
  • Ẹrọ mohunmaworan ati amohuntutu
  • Pẹlu omilẹgbẹ ẹbun miran.
Àkọlé fídíò, Kloe: Èmi kìí mu òògùn olóró, àmọ́ mo fẹ́ràn láti máa wà lẹ́bà omi

Bawo lo ṣe le dibo ninu ti eto BB Naija 2020?

O di dandan ki awọn ololufẹ awọn olukopa dibo lasiko ti eto yii n lọ lọwọ.

Eyi yoo fun awọn ololufẹ awọn ero iworan loore ọfẹ lati gbegba oroke ninu ile ẹlẹgbọn agba naa.

Wọn le lo ọna mẹrin yii lati kopa ninu idibo naa:

  • Fifi atẹjiṣẹ ranṣẹ lati ori ẹrọ foonu alagbeka.
  • Didibo lori itakun agbaye BBNaija 2020 lati ori ẹrọ kọmputa lori tabili
  • Didibo lori itakun agbaye BBNaija 2020 lati ori foonu alagbeka
  • Didibo lẹyin ti o ba ti san owo to yẹ lati ma wo eto naa lori aapu MyDSTV ati MyGOTV App

Bawo lo ṣe le wo eto BBNaija?

Ori ẹrọ amohunmaworan ati lori ayelujara ni ot i le wo eto naa bo ṣe n bẹrẹ.

DSTV ati GOTv ni wọn yoo maa gbee sita.

Alaalẹ ọjọ Aiku lọsọọsẹ ni wọn yoo si maa yọ ẹni kan kuro ninu ile ẹlẹgbọn agba naa.

Oriṣiriṣi iran fun oju ni yoo ṣẹlẹ ninu eto naa nitori sinima awootunwo ni o maa n ṣẹlẹ nibẹ bii ọrọ ifẹ, ija, asọ, ere, ẹrin pẹlu ayẹyẹ.

Ǹjẹ́ o mọ iye ẹ̀bùn owó tí olúborí BBNaija yóò gbà lọ́dún yìí?

N85mílíọnù àtàwọn ẹ̀bùn míràn ni olúborí BBNaija yóò gbà lọ́dún yìí

Eto agbelewo ile ẹlẹgbọn agba ti a mọ si Bbnaijia ti ọdun 2020 yoo bẹrẹ ni ọjọ Aje to n bọ yii, iyẹn ọjọ kọkandinlogun oṣu keje.

Gẹgẹ bi wọn si ti sọ, ẹbun ti iye owo rẹ to miliọnu marundinlaadọrun naira, N85m ni olubori nibi eto naa yoo fi ṣara rindin.

Amọṣa gẹgẹ bi awọn to n ṣagbatẹeru eto agbelewo BBNaija ṣe sọ, eto ti ọdun yii yoo wa ni ibamu pẹlu gbogbo ilakalẹ ti ijọba ba gbe kalẹ lori gbigbogun ti arun coronavirus eleyi to ti da họwuhọwu silẹ lagbaye.

Eto ayẹwo ọlọjọ mẹwaa ni wọn ti kọkọ ṣe fun awọn olukopa laarin ogunjọ oṣu karun un si ọgbọn ọjọ oṣu karun un kan naa.

Ebuka, olugbalejo eto agbelewo bbnaija

Oríṣun àwòrán, Bigbrother

Ni bi a ṣe n sọrọ yii, wọn ko tii fun saa karun un eto naa ni orukọ apejẹ kankan. Orukọ apejọ ti wọn fun saa ti ọdun to kọja ni Big brother "perpperdem".eji

Ebuka Obi Uchendu to ti n gbalejo eto agbelewo yii fun ọdun diẹ sẹyin naa ni yoo tun gbalejo rẹ lọdun yii.

Àkọlé fídíò, Black women live matters: Ọdún 2015 ní àwọn ọlọ́pàá pa India Kager láìní ìdí- Gina Best