Justice For Uwaila: Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo fojú àwọn aṣebi tó pa Uwaila Omozuwa hàn

Uwa

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karùn-ún, ọdun 2020 ni àwọn kan fipá bá ọmọbìnrin ẹni ọdún 22 lopọ̀ nínú sọ́ọ́sì.

Ọkan lara awọn afurasi ti ọwọ ọlọpaa tẹ lori iku ọdọmọbinrin, to jẹ akẹkọọ Fasiti ilu Benin, ti wọn pa laipẹ yii, sọ pe obinrin kan to jẹ ọmọ ijọ kan naa pẹlu rẹ lo ni ki awọn pa a.

Inu ijọ 'Redeemed' kan ni wọn pa Uwaila Vera Omozuwa si, nitosi ile awọn obi rẹ.

Afurasi naa, Collins Uligbe, sọ lasiko ti ọlọpaa fi oju wọn han ni gbangba pe "Iya onile oun, Mary Ade, lo fun oun ati awọn isọmọgbe rẹ ni miliọnu kan Naira, lati pa ọmọbinrin naa.

"O tun sọ fun wa pe ka fi aṣọ pelebe nu ẹjẹ rẹ, ka si mu u wa fun oun."

O fikun ọrọ rẹ pe Arabinrin Ade sọ fun oun pe gule-gule ọmọ naa ti pọju ninu ṣọọṣi. Uwa lọtun, Uwa l'osi, bi ẹni pe oun nikan ni ọmọ to wa ninu ṣọọṣi.

Kọmiṣọna ipinlẹ Edo, Ọgbẹni Johnson Kokumo lo fi oju awọn afurasi mẹfa naa han lọjọru ọsẹ.

Ṣaaju, ọga agba Ọlọpaa lorilẹede Niajiria, Mohammaed Adamu ti seleri wi pe awọn yoo se awari awọn to sekupa arabinrin Vera Omosuwa ni ipinlẹ Edo.

Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karùn-ún, ọdun 2020 ni àwọn kan fipá bá ọmọbìnrin ẹni ọdún 22 yii lopọ̀ nínú sọ́ọ́sì.

Àkọlé fídíò, JusticeforUwa:Awọn àkẹkọ̀ọ́ Uniben wọ́de ìfẹ̀hónú hàn nítórí Uwa tí wọ́n fipa bálòpọ̀
Àkọlé fídíò, Justice for Uwa: Bàbá Uwa, akẹ́kọ̀ọ́ fásitì tí wọ́n fipábálòpọ̀ ní Benin bá BBC sọ̀rọ̀

Uwaila jẹ akẹkọọ ipele ikini ninu imọ ẹkọ Microbiology ni fasiti Uniben ti awọn obi rẹ si ni ọmọ to da yatọ ni laarin gbogbo ọmọ ti Ọlọrun fun wọn.

Uwa

Oríṣun àwòrán, others

Awọn afurasi ti wọn foju wọn han naa ni Nelson Ogbebor, Akato Valentine, Arabinrin Tina Samuel, Arabinrin Mary Ade, Nosa Osabohien ati Collins Ulegbe.

Kọmiṣọna ni '"ọrọ naa jẹ ọrọ to mumu layaa ọga agba awọn ọlọpaa, Muhammed Adamu to si ran ikọ akọṣẹmọṣẹ lọ si ilu Benin lati lọ ṣiṣẹ pẹlu awọn ọlọpaa wa"

"Ohun taa n ri lonii jẹ abajade akitiyan awọn ọlọpaa lati de kulẹkulẹ ọrọ yii".

Kokumo jẹ ko di mimọ pe esi ayẹwo ti wọn ṣe fi han pe lootọ wọn fipa ba Uwaila lo pọ ni.

Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'