Nollywood: Àwọn òṣèré Yorùbá kan rèé tí kò sí lójú ìwòran mọ́ ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣì wà láyé

Awon agba oṣere

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àwọn gbájúgbajà òṣèré kan jẹ́ ilúmọ́ọ̀ká ni àsìkò kan, pàápàá jùlọ nínú àwọn eré àgbéléwò Yorùbá.

Sùgbọ́n ó jọ bí ẹni pé, ìràn àwọn òṣèré tó n dìde ni lọ́ọ́lọ́ yìí ti fí àwọn àgbà òṣèré náà si ìjòkó ẹ̀yìn nínú ká dáni lara yá.

Èyí si jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ìdí ti a kò fi rí ojú àwọn òṣèré kan mọ́ lójú amóhùnmáwòràn wa.

Lárà àwọn tí o ti tó ojọ́ mẹ́ta ti a ti rí ti wọ́n kópa ninú èré àgbéléwò ni

Abdulsalam Ishola Sanyaolu

Segun Remi

Jimi Solanke

Dejumo Lewis

Àwọn òṣèré Nollywood tí wọ́n ò sí lóri amohumaworan mọ́.

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹni ọdún makànlélọ́gọ́rin ni báyìí, o si le jẹ ntori agba to de ni baba ṣe fi ere agbelewo silẹ.

Guru Maharaj, Gani Adams ati àwọn eekan ilú ló péjú síbi ayẹyẹ ọjọ́ ibi rẹ̀ ni inu oṣu kejila ọdun to kọja.

O ti gba amiẹyẹ to ga julọ mni Naijiria pẹlu "Member of the FederalRepublic of Niger"

Àkọlé fídíò, ‘Tunde Kelani yan mi jẹ lori fiimu ‘Toluwanilẹ’

Abdulsalam Ishola Sanyaolu (Charles Olumo)

Abdulsalam Ishola Sanyaolu ti gbogbo eniyan mọ si Charles Olumọ tabi "Agbako naa jẹ gbajugbaja elere agbelewo. Sugbọn ojiji ni aisan kọlu baba , eyi sọ di ẹni ti ko le gbe apa gbe ẹsẹ mọ.

Lati igba yìí ko si ẹni to gburo rẹ ninu ere agbelewo Nollywood Yoruba mọ.

Àwọn òṣèré Nollywood tí wọ́n ò sí lóri mohumaworan mọ́.

Oríṣun àwòrán, Others

O wọ agbo oṣere lọdun 1953 ni ile ijọsin kan nilu Eko, sugbọn ọmọ Abeokuta ni ipinlẹ Ogun ni

Ni ọdun 2019, Agbako salaye pé aisan to jọ mọ ọkan lo se oun sugbọn oun ti se iṣẹ abẹ.

O ní eyi nikan kọ, nkan to se pataki julọ ti oun ko fi le se ere agbelewo ni pe , oun n tete gbagbe nkan.

Àwọn òṣèré Nollywood marun ti ko si loju iworan mọ sugbọn ti wọn wa laye.

Oríṣun àwòrán, Other

Segun Akinremi

Gbajugbaja osere tiata, Segun Remi, ti ọpọ eeyan mọ si Chief Kanran kesi araye pe nnkan n ṣe oun.

Kanran, ẹni to ke gbajare bẹẹ lori eto redio kan nilu Ibadan, lo n ṣe omije loju poroporo lasiko eto naa.

Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'

Gbogbo eniyan lo mọ pe ka se ere talika kìí ba Chief Kanran lara mu ninu ere ti ọpọ i maa n foju olowo woo.

O ti to bi ọjọ mẹta ti ko si ẹni to ri ninu ere agbelewo Yoruba kankan mọ.

Àkọlé fídíò, Tunde Kelani; Èmi ò jẹ́ Baba Wande ní owó lórí fíímù Tolúwanilẹ̀

Kanran salaye lasiko eto naa pe rẹrẹ ti rún bi ile oun ṣe kọkọ jona lati oke delẹ pẹlu gbogbo dukia ti òun ti fi ọpọ ọdun ṣíṣẹ fun , kò tá síbẹ , o ni ti iyawo ati awọn ọmọ si sa fun oun pẹlú.

O fikun pe, ọpọlọpọ isoro yii ni ko jẹ kawọn eeyan rí oun ninu sinima mọ nitori ohun gbogbo to dagun fun oun.

Bótilẹ jẹ́ pé Kanran ni oun ti di Bisóóbu síbẹ̀ ko di oun lọwọ lati ṣe ere agbelewo ti oun ba ri, nítori, ko fi bẹẹ si iyatọ laarin mejeeji.

Ẹni ọdun mejidinlaadọrin ni "Chief Kanran" a bi ni Keesi,ni ipinlẹ Ogun

Àwọn òṣèré Nollywood marun ti ko si loju iworan mọ sugbọn ti wọn wa laye.

Oríṣun àwòrán, others

Jimi Solanke

Fasiti ọlọgba ẹranko nibi ti sanmọnti gbe dun ilẹ ni ilu Ibadan ni Jimi Solanke ti kẹkọọ gboye imọ ijinle ninu ere dirama.

O da ẹgbẹ The Africa Review sile ni America eyi to n ṣafihan aṣa ilẹ Adulawọ.

Àkọlé fídíò, Oba Adewumi Ogunleye: Nítorí ìfẹ́ ìlú àti ọ̀dọ́ ni mo ṣe padà sílé ẹ̀kọ́- Oba Towulade

O siṣẹ pẹlu ile iṣẹ amohunmwaoran Nigeria Television Authority.

O kopa ninu ere Kongi's Harvest ti Wole Soyinka ko iwe rẹ ati awọn ere mii.