Christchurch mosque attack: Tarrant tó pàyàn 51 gbà'dájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére

Oríṣun àwòrán, EPA
Ajijagbara oyinbo alawọfunfun to gba ẹmi eeyan mọkanlelaadọta ni mọṣalaṣi meji kan lorilẹede New Zealand yoo lo iyoku aye rẹ lẹwọn.
Iku lere ẹṣẹ bí wọn ti maa n sọ. Eyi lo mu ki ileẹjọ kan lorile-ede New Zealand dajọ ẹwọn gbere titi yoo fi ku fun Brenton Tarrant to ṣeku pa eeyan mọkanlelaadọta..
Tarrant ni ẹni akọkọ ti yoo gba iru idajọ yii ninu itan orile-ede New Zealand.
Araa Australia ọhun, jẹ ẹni ọdun mọkandilọgbọn to si gba wí pe oun jẹbi ẹsun ipaniyan, bakanna lo gba pe oun jẹbi ẹsun igbesẹ lati pa ogoji eniyan mii.
Tarrant tun sọ pe oun jẹbi ẹsun igbesunmọmi onikoko kan.
Ninu idajọ rẹ, adajọ Cameron Mander ni awọn iwa ipa ati ohun buburu ti Tarrant ṣe l'agbara de bi pe ninu ahamọ ni yoo ti lo gbogbo ọjọ aye rẹ to ku titi yoo fi ku.
Adajọ ni awọn ọdaran apayan to buru jai ni wọn maa n gba iru idajọ bẹẹ.
Ko si idajọ yiyẹgi fun ọdaran ninu eto idajọ orile-ede New Zealand.
Olootu orilẹede New Zealand, Jacinda Ardern nigba to gb idajọ ti wọn fun Tareant sọ pe o tumọ si pe ko ni si aaye fun un mọ rara lati huwa labi... "a o si ni ronu rẹ mọ, ri i tabi gbọ nipa rẹ mọ".
"Onii ni mo lero pe yoo jẹ igba ikẹyin ti a o ni idi kankan lati gbọ tabi darukọ adunkukulajamọni yii.
Tarrant to sọrọ latẹnu agbẹjọro kan nile ẹjọ sọ pe oun o lodi si idajọ ti wọn da fun oun ṣugbọn ko fẹ fesi nibi idajọ rẹ.
Ṣe ni oju Tarrant ri bi ẹni ti ko ni imọlara nkankan rara lati bii ọjọ mẹta ti wọn ti wa lori eyi ti nkan bii eeyan aadọrun to fara gba ninu ọsẹ rẹ atawọn mii to n ṣọfọ doju kọ ọ.













