Èèyàn kan kú, ọ̀pọ̀ há sínú súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ níbi ijàmbá tírélà tó wáyé lórí afárá Otedola níkùú Eko

Aworan sunkẹrẹfakẹrẹ ọkọ pẹlu ẹru iyẹfun ti ọkọ naa danu.

Oríṣun àwòrán, channelstv

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Eeyan kan ti padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọpọlọpọ ọkọ to waye lori afara Otẹdọla nilu Eko ni Ọjọ Ẹti.

Iṣẹlẹ ijamba awọn ọkọ yii ti fa sunkẹrẹ fa kẹrẹ lopopona naa eyi to ja si opopna Eko si ilu Ibadan.

Awọn agbofinro s pe awọn ọkọ tirela meji to ko iyanrin ati eyi to ko okuta lo forigbari nibi ti wọn ti n du ọna mọ ara wọn lọwọ.Ajọ to n ṣe amojuto ọkọ ni ipinlẹ Eko, LASTMA, ṣalaye pe "awakọ tirela to ko iyanrin naa padanu ẹmi rẹ ninu ijamba naa".

Aworan awọn apo iyẹfun to danu.

Oríṣun àwòrán, channelstv

"Wọn doola ẹmi dẹrẹba ọkọ tirela keji, ko si fara pa rara."

Bakannaa ni ajọ amuṣẹya ọrọ abo ni ipinlẹ Eko, RRS pẹlu ṣalaye pe ọkọ akẹru kan to kun dẹdẹ yii ṣubu soju popo naa to si da ẹru inu rẹ danu, eleyi to di ida aadọrun ninuọgọrun opopona naa" eleyii ti ko jẹ ki lilọbibọ ọkọ o lọ dede.

Awọn ileeṣẹ alaabo gbogbo ni ipinlẹ Eko ni wọn ni awọn ti da awọn ẹṣọ alaabo si agbegbe naa lati le mu ki ohun gbogbo o bọ sipo.

Ijamba ọkọ ni akọtun ninu awọn ijamba ọkọ to ti n waye lori afara yii loju opopona to so ilu Eko pọ mọ ẹkun aringbungbun iwọ oorun Naijiria ati ila oorun gusu Naijiria.