Akinwumi Adesina: Ọdún márùn ún ní Adesina yóò lò ní sáà kejì ipò adarí Báńkì AFDB

Akinwumi Adesina

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọmọwe Akinwunmi Adesina ti da Aarẹ Banki Ilẹ Afrika, AfDB lẹyin ti wọn bura wọle fun un ni Ọjọ Kinni, Oṣu Kẹsan an, ọdun 2020.

Ori ẹrọ ayelujara ni iburawọle naa ti waye ni Ọjọ Iṣẹgun.

Ọdun marun un ni Adesina yoo lo lori oye gẹgẹ bi aarẹ Banki ilẹ Afrika, AFDB lẹyin iburawọle fun saa keji naa.

Laipẹ yii ni Adesina jawe olubori ninu iwadii ẹsun magomago ti wọn fi kan an.

Ni Abidjan ni orilẹ-ede Cote D'Ivore ni eto ibura naa ti waye.

Oṣu Kinni, ọdun 2020 ni wọn fi ẹsun ibajẹ onigun mẹrindinlogun kan Adesina, amọ awọn alakoso banki naa fi ọwọ osi da ẹjọ naa nu wi pe ko si otitọ kankan nibẹ.

Akinwumi Adeṣina ti jẹ minisita eto ọgbin fun orilẹ-ede Naijiria ri.

Akinwunmi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Músò Músò! Akinwumi Adesina jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bí adarí Báńkì AFDB

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni wipe wọn ti tun Akinwumi Adeshina yan gẹgẹ bii adari Banki Idagbasoke ilẹ Afrika, AFDB.

Oun ni yoo maa tukọ idari banki naa fun saa ọlọdun marun miran lẹyin ti iwadii ti fihan pe ko si kọnu n kọhọ kankan ninu saa iṣejọba rẹ akọkọ.

Akinwumi Adeṣina ti jẹ minisita eto ọgbin fun orilẹede Naijiria ri.

Atunyan rẹ kan jẹ ko ma da bii pe wọn ko tẹle ilana ni tori oun nikan ṣoṣo naa ni oludije to wa nibi eto idibo naa eyi to waye lori ayelujara nibi ipade banki naa to waye lọjọbọ.

Ninu ọrọ rẹ to sọ lati pe fun ki wọn dibo yan an fun saa keji, Adesina ni oun n lo oun gbogbo ti oun ni lati sin ilẹ Afirika lai lẹ́ja n bákàn ninu.

Ẹni ọgọta ọdun ni Akinwumi Adesina.

Òtítọ́ lékè! Akinwumi Adesina bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣùn jẹgúdújẹrá tí wọ́n fi kan - AFDB

Iwadii tuntun ti Banki Idagbasoke ilẹ Afrika, AFDB gbe kalẹ ti ni adari Banki naa, Akinwunmi Adesina ko jẹbi ẹsun jẹgudujẹra ti wọn fi kan an.

Aarẹ ilẹ Ireland tẹlẹri, Mary Robinson to fi mọ agbẹjọrọ agba lorilẹede Gambia, Hassan Jallow ati Leonard McCarthy to jẹ igbakeji aarẹ Banki apapọ lagbaye, wa lara igbimọ to ṣe iwadii Adesina finifini.

Ajọ naa ni Adesina ko jẹbi kankan ninu gbogbo ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn fi kan an.

Lara ẹsun ti wọn fi kan Adesina, to jẹ minisita fun eto ọrọ aje lorilẹede Naijiria ni lilo ipo rẹ lọna aitọ, lilu owo banki ni ponpo ati ṣiṣe oju-saaju.

Amọ, ni gbogbo igba ni Adesina ma n sọ wi pe, oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Ko to di akoko yii, ni iwadii abẹle ti kọkọ fi lede pe, Adesina ko wu iwa ibajẹ kankan, amọ orilẹede Amerika kọ iwadii naa, ti wọn si gbe omiran kalẹ.

Orilẹede Amerika wa lara awọn orilẹede mẹtadinlọgbọn to wa ninu igbimọ banki AFDB naa, ti wọn si jẹ orilẹede keji to ni ipin idokowo to pọ julọ ni banki ọhun.

Nibayii, orilẹede Amerika ni awọn faramọ abajade tuntun yii pẹlu igbagbọ pe, otitọ ni wi pe Akinwunmi Adesina ko jẹbi ẹsun iwa ibajẹ ati magomago ti wọn fi kan an.

Báńkì ìdàgbàsókè Áfríkà yóò bẹ̀rẹ̀ àkọ̀tun ìwadìí lórí Olùdarí báńkì náà, Akinwumi Adesina

Banki to wa fun idagbasoke ilẹ Afrika, The African Development Bank, sọ pe oun ti ṣe agbekalẹ igbimọ oluwadii aladani lati wadii awọn ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan Oludari banki naa, Akinwumi Adesina.

Adesina to ti fi igba kan ri jẹ Minisita fun iṣẹ agbẹ n f'ojusọna lati tun jẹ olori banki naa ninu eto idibo ti yoo waye l'oṣu Kẹjọ.

Akinwumi Adesina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Sugbọn ilẹ America lo n ṣe agbatẹru ipolongo fun wiwadii rẹ, nitori pe wọn fura si pe o n kowo jẹ, o tun n yan awọn ọmọ Naijiria nikan si awọn ipo nlanla ni banki naa. Wọn tun sọ pe awọn ti wọn ti fi ẹsun jibiti ati iwa ibajẹ kàn ni Adesina n gbega l'ẹnu isẹ.Ọgbẹni Adesina sọ pe oun ko jẹbi ẹsun kankan. Koda, iwadii abẹle ti wọn kọkọ ṣe lori rẹ sọ pe ko jẹbi.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, State of Osun: Pípe ìpínlẹ̀ Osun ni State of State Osun kò bá òfin mu-Adájọ́ Agboola