Gas Explosion: Ẹ̀mí kan bọ́, èèyàn mẹ́ta fara pa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù gáàsì tó wáyé l‘Eko

Ile ti agolo gaasi ti bu

Oríṣun àwòrán, @followlasema

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkunrin kan ti wọn ko ti dárúkọ rẹ ti padanu ẹmi rẹ lasiko ti ibugbamu afẹfẹ gaasi to waye ni agbegbe Palmgrove nilu Eko.

Iroyin sọ pe agolo gaasi kan ti wọn fi n tun ẹ̀rọ amule tutu kan ṣe ninu ile alaja kan naa lo bu gbamu, nitori pe ó ń jò.

Yatọ si ọkunrin to kú, ọkunrin mẹta miran tun farapa, ti wọn si ti n gba itọju nileewosan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alaga ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Olufemi Oke-Osanyintolu, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, sọ pe wọn ti ko gbogbo eeyan to n gbe ninu ile naa kuro.

Osanyintolu ni agbegbe Cappa Avenue, Palmgrove nilu Eko ni ibugbamu naa ti waye.

Ile ti agolo gaasi ti bu

Oríṣun àwòrán, @followlasema

Ó fi kún un pe wọn ti ti ile naa pa, lati dena ijamba miran.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Eyi ko sẹyin bi awọn ibi kan lara ògiri ati òpó ile naa, ṣe ti sán, nitori ibugbamu to waye.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Simon Mallam wa nínú àwọn mẹ́fà tó ti kú nínú ìjàmbá iná gáàsì- Ìjọba Kaduna

ijamba gaasi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gas Explosion: Afẹ́fẹ́ gáàsì ṣekúpa ọ̀pọ̀ èèyàn ní Kaduna

Awọn agbofinro ipinlẹ Kaduna ti fi ninu orukọ awọn to ba iṣẹlẹ naa rin sita.

Ijamba ina afẹfẹ gaasi to ṣẹlẹ ni agbegbe Sabon Tasha ni Kaduna ni wọn ni o ti mu ẹmi Ojọgbọn Simon Mallam lọ.

Ojọgbọn Simon Mallam ni adari ajọ Nigeria Atomic Energy Commission to n mojuto ọrọ ado oloro ni Naijiria.

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Kaduna fidi ẹ mulẹ pe eniyan mẹfa lo ti jalaisi bayii ninu iṣẹlẹ naa ti awọn miran ṣi wa nile iwosan.

Opọlọpọ ile itaja lo jona mọ ile itaja afẹfẹ gaasi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ bayii.

Agbenusọ ajọ Nigeria Atomic Energy Commission fidi ẹ mulẹ fun akọroyin BBC pe, nigba ti Ojọgbọn Simon lọ gẹ irun ori rẹ ni ọkan lara awọn ile igẹrun lẹgbẹ ile itaja gaasi naa ni iṣẹlẹ naa waye.

O ni lasiko ti Ọjọgbọn Simon ṣe n gẹ irun lọwọ ni afẹfẹ gaasi naa gbina ṣugbọn gbogbo igbiyanju lati doola ẹmi rẹ ja si pabo ni eyi to ti mu ẹmi Ọjọgbọn naa lọ.

Àkọlé fídíò, Yoruba language: Ọdún 2020 to wọlẹ́ dé yìí á tu gbogbo wa lára

Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ọpa afẹfẹ gaasi to bu gbamu ti ṣekupa ọpọ eeyan niluu Kaduna lọjọ Satide.

Kọmiṣọnna eto aabo ni Kaduna, Samuel Aruwan gboṣuba fawọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri pé wọ́n tètè dìde si iṣẹlẹ naa.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni ṣaa deede ni ṣọọbu naa deede gab ina ni agbegbe Sabon Tasha ni Kaduna.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Nasir El Rufai

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nasir El Rufai

Iṣẹlẹ ọhun jẹ iyalẹnu fawọn araalu ni Kaduna eleyi ti iroyin sọ pe afẹfẹ gaasi to n jo lo ṣe okunfa rẹ.

Kọmiṣọnna fun eto aabo ni Kaduna, Samuel Aruwan gboṣuba fawọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri ninu iṣẹ ibanikẹdun to fi ṣọwọ si ẹbi awọn ti iṣẹlẹ naa mu ẹmi wọn lọ.

Iṣẹlẹ ọhun ni kọmisọnna sọ loju opo Twitter rẹ pe o ṣẹlẹ lopopona Kachia ni ijọba ibilẹ Chikun.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Àkọlé fídíò, 'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Ninu ọrọ ibanikẹdun tirẹ, Sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun aringbungbun Kaduna, Uba Sani tọrọ aforiji fawọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Bakan naa lo ki awọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri ninu iṣẹ ibanikẹdun to fi ṣọwọ si ẹbi awọn ti iṣẹlẹ naa mu ẹmi wọn lọ.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Àkọlé fídíò, 2020: Oloye Awurela Ifaleke ti wúré ọdún ìgbéga fún kóówá