2019 in retrospect: Ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú dínkù lọ̀dún 2019

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii fihan pe odiwọn ẹmi to sọnu ninu ijamba ọkọ ofurufu ni gbogbo agbaye lọdun 2019 dinku gan an ni
Esi iwadii naa fihan pe ida aadọta ninu ọgọrun un ni o fi dinku.
Eniyan mẹtadinlogọta o le ni igba lo ku yatọ si ti ọdun 2018 to jẹ eniyan mẹrinlelọgbọn o le ni ẹẹdẹgbẹrun kan.
Ileeṣẹ Transport Co To70 ni iye nọmba naa dinku pẹlu ijamba Boeing 737 Max to ṣẹlẹ ni Ethiopia loṣu kẹta, ọdun 2019Lẹ́yìn tórí yọọ́ nínú ìjambà ọkọ̀; Ọ̀jọ̀gbọ̀n Pius Adesanmi kú nínú ìjàmbá bàálù Ethiopia!.
Iwadii yii tun fihan pe odiwọn irinajo pẹlu ọkọ ofurufu lọdun 2019 pọ sii ṣugbọn ijamba dinku jọjọ paapaa eyi to la ẹmi lọ.
Iṣẹ iwadii yii fihan pe ijamba ọkọ oju irin mẹrindinlaadọrun un ṣẹlẹ pẹl\u ọkọ oju irin makero mẹjọ ninu eyi ti ẹmi mẹtadinlọgọta le ni igba ti sọnu.
Dutch Shipping company ṣalaye pe awọn ẹmi to sọnu yii jẹ lati inu ijamba ọkọ akero.
Iwadii naa tun ni o le miliọnu marun un ọkọ oju irin ti wọn ṣe jade lọdun 2019.
Aviation Safety Network ni 2018 mu ẹmi ọpọ lọ ninu ijamba ọkọ ofurufu.
O ni ọgọjọ ijamba ṣẹlẹ to mu ẹmi o le ni ẹẹdẹgbẹrun eeyan lọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Iwadii naa tun ṣafihan awọn iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu to nii ṣe pẹlu awọn ọkọ ofurufu ọmọ ogun .
Bayii, wọn ti n risi ipese eto aabo lori ofurufu siii ni agbaye ni eyi to tun n ko ipa rere sii.















