Queen: Obabinrin Elizabeth ṣàfihàn orí adé mẹ́ta tó lè jé lẹ́yìn rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Ranald Mackechnie
Bi ọdun tuntun ṣe wọle de wẹrẹ ni 2020 yii naa ni wọn ti fi aworan tuntun sita fun ọdun mẹwaa tuntun to bẹre lati 2020 si 2030.
Aworan ori ade ilẹ Gẹẹsi ti wọn fi sita yii ṣafihan awọn oju to létọ si apere Obabinrin Elizabeth Keji ni ilẹ Gẹẹsi.
Aworan naa ṣafihan Omo ọba Wales, Duke ti Cambridge ati Omo oba George ti wọn duro pẹlu Obabinrin Elizabeth ni aafin Buchingham.
Aworan yii jẹ ẹlẹẹkeji iru rẹ ti yoo ṣafihan iran mẹrin naa papọ
Ọsẹ kan ṣaaju keresimesi to kọja ni wọn ya aworan naa ṣugbọn ti ile Oba ṣẹṣe gbee sita lati sami ọdun tuntun.
Obabinrin Elizabeth to ti pe ẹni ọdun mẹtalelaadọrun un naa duro pẹlu ayo niwaju awọn ọmọ ti Oluwa fi taa lọrẹ ninu aṣọ funfun to wọ.
Omo bibi inu Obabinrin Elizabeth, Omọọba Charles lo duro lẹyin iya rẹ ti o fi ọwọ fa ọmọ ọmọ rẹ, Omo oba George to jẹ ọmọ ọdun mẹfa bayii mọra.
Omọọba Williams to jẹ ọmọ ọmọ si Obabinrin naa duro ninu aworan naa pẹlu ẹrin pe a dupẹ iran mẹrin yii ri ọdun 2020 layọ.

Oríṣun àwòrán, Ranald Mackechnie
Lọdun 2016 ni wọn ya awọran akọkọ yii to ṣafihan iran mẹrin naa to le gun apere Oba ile Gẹẹsi.
Eyi waye nigba ti ile Oba n sami ayẹyẹ ọdun aadọrun un ti Obabinrin Elizabeth ti wa lori oke eepẹ.

Oríṣun àwòrán, PA Media
Lọjọ kejidinlogun, oṣu kejila, ọdun 2019 ni wọn ya aworan oke yii.
Eyi ṣafihan iran mẹrin naa ti wọn jọ n da ina ọdun keresi papọ.
Omọọba Charles, William ati George ni wọn duro ti Obabinrin Elizabeth ninu aworan naa.















