Ọ̀do mẹ́rin rẹ́wọ̀n he lórí ikú ọmọ Naijiria n'ílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Harry Uzoka

Oríṣun àwòrán, Harry Uzoka

Àkọlé àwòrán, Ọbe ni wọn fi gun Harry Uzoka pa

Ile ẹjọ Old Bailey, Ilẹ Gẹẹṣi ti ran ọmọkunrin kan l'ẹwọn fun pe o pa ọmọ Naijiria kan, Harry Uzoka ni oṣu kinni, ọdun yii ni ilu London.

Uzoka jẹ okan lara awọn ti wọn yoo kọkọ fi ọbẹ gun pa ni orilẹ-ede naa ni Ọdun 2018.

Ile ẹjọ ni nise ni George Koh gun Uzoka lọbẹ laya. Awọn meji to kọwọrin pẹlu rẹ wu iwa buruku yi naa ri ẹwọn he.

Ohun ta gbo ni pe ọrẹbinrin ni wọn n ja si.

Ninu awijare rẹ, Koh ni Uzoka lo tọja oun.

Ọkan lara awọn ti wọn ran lọ ẹwọn pẹlu rẹ jẹ ọmọ Naijiria ti orukọ rẹ n jẹ Jonathan Okigbo.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan ni adajọ a kede idajo lati ran wọn lọ ẹwọn.

Harry Uzoka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Uzoka jẹ ọmọ to mọwe

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ

Isẹ modẹli ni Uzoka ati ọrẹ́binrin rẹ jijọ n se.

Lọjọ kọkanla, ọṣu kinni ti wọn gun-un pa, awọn oniṣegun Ilẹ Gẹẹsi ja fitafita lati doola ẹmi rẹ ṣugbọn pabo lo jasi.

Ilẹ Gẹẹṣi ni awọn obi rẹ to jẹ ọmọ Naijiria bii si, ti wọn si n gbe ni adugbo Dagenham, nibi ti ọpọlọpọ ọmọ Naijiria n gbe.

Ni ọdun 2008, wọn ran an lọ ẹwọn ewe fun ọdun mẹrin nitori o kopa ninu ole jija kan, ṣugbọn ọdun meji lo lo nibẹ.

Awọn ti BBC ba sọrọ sapejuwe re gẹgẹ bi ọmọ to mọwe ati pe o ti n kọle fun iya rẹ, Josepine ni Naijiria, ti iya rẹ naa si ti pinnu lati pada wa si orilẹ-ede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Bi awọ ara awọn ọmọ Britain se ri nigba iwasẹ