Akẹ́kọ̀ọ́ tó pa àwọn akẹgbẹ rẹ̀ dá àwọn kan sí fún ìtàn

Dimitrios Pagourtzis

Oríṣun àwòrán, GALVESTON COUNTY JAIL/TWITTER

Àkọlé àwòrán, Akẹ́kọ̀ọ́ tó pa àwọn akẹgbẹ rẹ̀ ní Texas

Akẹkọọ ilé iwe girama Santa Fe nipinlẹ Texas lorilẹede Amẹrika to yinbọn pa eeyan mẹwa ti fi oju ara rẹ han.

Iwe kan lati ile ẹjọ fihan wi pe akẹkọọ̀ apaniyan naa ni oun da awon ti oun fẹran si lati le sọ itan ara rẹ ati ohun to sẹlẹ.

Wọn ti fi ẹsun ipaniyan kan Dimitrios Pagourtzis lẹyin ti o yinbọn pa eniyan mẹwa lọjọ ẹti ni ilu Texas.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ọjọ ori rẹ ti wọn ko jọ nile ẹjọ, Ọgbẹni Pagourtzis ẹni ọdun mẹtadinlogun ju ọwọ ọtun rẹ soke lati pa ẹnu mọ, o si gba wi pe oun yinbọn pa ọpọlọpọ eniyan.

Awọn alaṣẹ ati agbofinro nibi iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Èèyàn mẹ́wá ló kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Ibọn ilewọ ti wọn ni akẹkọ naa mu lọdọ baba rẹ, ti oun pẹlu gba lọna aitọ, ni wọn ni o lo lati fi ṣiṣẹ laabi naa.

Awọn agbofinro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ibọn ilewọ ni wọn ni o lo lati fi ṣiṣẹ laabi naa.

Awọn ọlọpa ni pupọ awọn to ku naa ni wọn jẹ akẹkọ.

Gomina Greg Abbott ni awọn ọlọpa ṣawari awọn iroyin lori iwe akọsilẹ ati ẹrọ kọmputa rẹ pe o gbimọ lati ṣe iṣẹ laabi naa ki o si pa ara rẹ lẹyin o rẹyin.

ododo ati ife nibi iṣẹlẹ ijamba naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Donald Trumpṣe apejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi to "buru jai"

O ni ọmọdekunrin naa jọwọ ara rẹ fun awọn ọlọpa nitori pe ko lọkan akin lati pa ara rẹ mọ.

Ni ọdun yii nika, o ti le ni ẹgbẹrun marun awọn eeyan ti iṣẹlẹ ibọn yinyin ti ran lọ sọrun ni orilẹede Amẹrika.

Awọn to n wọde tako ibọn lilo gbe patako dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ọlọpa ni pupọ awọn to ku naa ni wọn jẹ akẹkọ

Awọn akẹkọ ni nṣe ni ọmọdekunrin ọhun naa sha dede wọ kilaasi kan ni nkan bii agogo mẹjọ ku iṣẹju diẹ ti o si ṣina ibọn bolẹ si awọn akẹkọ nibẹ.

Aarẹ Donald Trump ninu ọrọ rẹ lori iṣẹlẹ naa ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bii eyi to "buru jai"

Bẹẹ lo sọ wi pe iṣejọba oun yoo maa sa gbogbo ipa lati daabo bo awọn akẹkọ ati ileewe gbogbo nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: