Aawọ ilẹ Gẹẹsi ati Russia: Trump satilẹyin fun ilẹ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ilẹ Amẹrika ti sọ wi pe gba-gba-gba bayii loun duro ti ilẹ Gẹẹsi lori igbesẹ rẹ lati le awọn asoju ijọba orilẹede Russia mẹtalelogun kuro ni ilẹ rẹ.
Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Theresa May ni ilẹ Gẹẹsi yoo le awọn asoju naa lẹyin ti ijọba orilẹede Russia ti kọ lati salaye bi atike gbẹmigbẹmi ti wọn se ni orilẹede Russia se di eyi ti wọn lo fun alami ilẹ Gẹẹsi tẹlẹ ni ilẹ Gẹẹsi.
Ijọba orilẹede Russia ti kọ jalẹ pe oun ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbẹnusọ fun Aarẹ Donald Trum ti orilẹede Amẹrika fẹsun kan Russia pe o n ti igi bọ oju abo awọn orilẹede yoku lagbaye.
Amọsa, minisita fun ọrọ okeere ni ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson salaye wi pe, ohun ti orilẹede Russia n sọ pẹlu ikọlu naa ni wi pe "nnkan ti oju orilẹede to ba n tako Russia n ri loju yin ri yii."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninu atẹjade kan, Sarah Sanders to jẹ akọwe iroyin fun Aarẹ Trump sọ wi pe orilẹede Amẹrika fẹ rii daju pe "irufẹ ikọlu bẹẹ ko waye mọ" to si tọka si igbesẹ ati le awọn asoju ijọba orilẹede Russia naa gẹgẹbi igbesẹ to tọna."
"Ohun ti orilẹede Russia se yii ko yatọ si awọn iwa wọn atẹyinwa ti Russia maa n hu lati tapa si eto ati ilana ajọ orilẹede agbaye, to si n se atako abo awọn orilẹede yoku lagbaye nibiti ijọba tiwantiwa ti gbilẹ."
Alami ilẹ Gẹẹsi tẹlẹ, Sergei Skripal to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlaadọrin pẹlu ọmọ rẹ, Yulia Skripal, si wa ni ileewosan lẹyin ti wọn daku ni ilu Salisbury, Wiltshire ni ọjọ kẹrin osu kẹta.












