Obafemi Awolowo University: Olùkọ́ fásitì OAU gbòmìnira lọ́wọ́ àwọn ajínigbé

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adegbehingbe
Olukọ agba fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ to wa nilu ile Ifẹ, Ọjọgbọn Yinka Adegbehingbe ti wọn ji gbe ti gba ominira lọwọ awọn ajinigbe.
Iyawo olukọ naa, Bernice Adegbehingbe lo fidi ọrọ mulẹ fawọn oniroyin.
Alukoro fun ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oṣun, Folasade Odoro naa sọ aridaju pe Ọjọgbọn Adegbehingbe ti mori bọ lọwọ awọn ajinigbe.
Agbegbe Ikire si Apomu ni opopona marosẹ Ifẹ si Ibadan ni wọn ti ji ojọgbọn naa gbe.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC news Yoruba, alukoro ileewe fasiti OAU, Abiọdun Olarewaju ṣalaye pe ni nnkan bi agogo mẹjọ abọ si mẹsan alẹ ọjọ aiku ni wọn ji ọjọgbọn naa gbe.

Oríṣun àwòrán, oau
"Ileewe ẹkọ imọ ilera ati iṣegun ni ọgba fasiti naa ni ọjọgbọn Adegbẹhingbe ti n ṣiṣẹ. Oun ati iyawo rẹ ni wọn jijọ n rinrin ajo lasiko ti awọn ajinigbe naa ṣọṣẹ."










