Royal baby: Harry ní ojú gbogbo yóò rí ọmọọba tuntun ní ọjọ́ méjì sásìkò yí

Harry ati Meghan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Michelle Obama rọọ lati ṣe ohun gbogbo ni wọntunwọnsi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọmọọba Harry ni oun ati iyawo oun, Meghan ṣi n ronu lori orukọ ti wọn yoo sọ ọmọ wọn tuntun.

O ni nigba ti a o ba fi ri ojọ meji si asiko yii, oun yoo ṣe ikede miran, "ki gbogbo awọn eeyan lee ri ọmọ tuntun naa soju".

Michelle Obama, Theresa May, Bíṣọ́ọ̀bù Curry ránṣẹ́ ìkíni kú oríire sí Harry àti Meghan

Lẹyin ti aafin ilẹ Gẹẹsi ti kede ibi ọmọ ọkunrin tuntun fun ọmọọba Harry ati aya rẹ Meghan, wọn ti gbe iwe ikede ibi rẹ siwaju aafin Buckingham palace bayii.

Lara awọn to kọkọ ki ẹbi naa ku oriire ni baba iya ọmọ, alagba Thomas Markle. Alagba Markle ṣe adura pe "ọmọ naa yoo dagba, yoo si sin ori ade atawọn eeyan ilẹ Gẹẹsi pẹlu ayọ, ati iwa rere."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bakan naa, olotu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Theresa May ti ranṣẹ ikini ku oriire si ọmọọba Harry ati Meghan fun ti ọmọọkunrin wọn.

Amọran Michelle Obama fun Meghan Markle

Michelle Obama

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu ọrọ tirẹ, aya aarẹ ana lorilẹede Amẹrika, Michelle Obama ki Ọmọọba Harry ati Meghan ku oriire na. O ni 'inu mi dun to bẹẹ ti n ko lee duro lati ri ọmọkunrin jojolo naa'

Ninu amọran to wa fun iya ọmọ tuntun naa, Michele ni loots ni pe Meghan ko ronu pe irufẹ igbe aye bayii yoo kan an gẹgẹ bi oun pẹlu lori ariwo ọja ti yoo maa wa nitori ipo rẹ lawujọ.

O rọọ lati ṣe ohun gbogbo ni wọntunwọnsi.

Ọmọọba Harry

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Harry ni ṣaka lara iya ati ọmọ le

Bakan naa, olori ilu Toronto, John Tory ti ki awọn baba ati iya tuntun naa ki oriire.

"O dara lati gbọ pe ṣaka lara iya ati ọmọ ya, mo si n reti abẹwo ẹbi yii si ilu Toronto."

Ẹwẹ, biṣọbu Micheal Curry to waasu nibi igbeyawo Harry ati Meghan ni ọdun 2018 ni ibi ọmọkunrin naa fihan pe 'ireti n bẹ'Bẹẹni o ṣe adura ibukun fun ẹbi naaati ọmọ wọn tuntun.

Harry ati Meghan nibi igbeyawo wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Michelle ni inu oun yoo dun lati ri ọmọ̀ naa laipẹ

Amọṣa, baba ọmọ naa, iyẹn Ọmọọba Harry ni awọn ko tii jiroro lori orukọ ti ọmọ naa yoo jẹ.

Bẹẹni tọkọtaya Harry ati Meghan ti dupẹ lọwọ gbogbo mutumuwa ninu atẹjade kan loju opo instagram wọn dun "atilẹyin wọn ati aanu ti wọn fi han wọn"

Atẹjade naa ni 'akoko ayọ nla lo jẹ ninu igbesi aye wọn bi wọn ṣe n ki akọbi wọn kaabọ.'

Ọmọọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bí ọmọ ọkùnrin

Harry ati Meghan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aafin Ọba ilẹ Gẹẹsi kede pe ni owurọ ọjọ aje ni o wọ ile igbẹbi lọ

Iyawo ọmọọba ilẹ gẹẹsi, Meghan Merkel ti bí ọmọ ọkùnrin.

Meghan bẹrẹ si nii rọbi bayii fun akọbi Ọmọọba Harry.

Aafin Ọba ilẹ Gẹẹsi, Buckingham palace lo kede eyii.

Gẹgẹ bii agbẹnusọ fun aafin ṣe sọ, ni owuro ọjọ aje ni Merghan wọ ile igbẹbi lọ pẹlu ọkọ rẹ, Harry ni ẹgbẹ rẹ.

Ọmọ naa ni yoo jẹ ẹẹkẹjọ ọmọ-ọmọ-ọmọ fun Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi.

Lọkọlaya Harry and Meghan ti sọ pe o di ẹyin igba ti wọn ba ti yayọ ọmọ tuntun naa pẹlu awọn mọlẹbi wọn ki wọn to kede ibi rẹ fun aye gbọ.

Ni ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwa ọdun 2018 ni wọn kede pe arabinrin Meghan ti fẹraku, iyẹn lasiko abẹwo wọn si orilẹede Australia ati New Zealand.