Naming of Railway stations in Nigeria: Afenifere, YCE, Akitoye, Fani-Kayode ní ẹ̀tanú Obasanjo ni Buhari ṣe

Yatọ si awuyewuye to n waye lori ayelujara, awọn ọmọ bibi ilẹ Yoruba kan ti fi èrò wọn han lori bi orúkọ aarẹ Naijiria nigba kan, Olusegun Obasanjo, ko ṣe sí lara orukọ ti ijọba apapọ kede lọjọ Aje fun awọn ibudokọ oju'rin ni Naijiria.
Akọwe ẹgbẹ ọmọ bibi ilẹ Yoruba, Afenifere, Yinka Odumakin, sọ pe ẹ̀tanú lo mu ki ijọba Buhari yọ orukọ Obasanjo sọ ibudokọ oju'rin kankan.
O ni nkan to mu ki orukọ Obafemi Awolowo wà nibẹ, naa lo yẹ ko mu ki ti Obasanjo naa pẹlu wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Dókítà aláwọ̀ dúdú kéde òògùn Chloroquine fún ìwòsàn Coronavirus, Facebook yọ fídíò náà dànù
- Òtítọ́ lékè! Akinwumi Adesina bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣùn jẹgúdújẹrá tí wọ́n fi kan - AFDB
- Ṣé lóòótọ́ ni Amcon gba ilé Toke Makinwa ti wọn ní bàbá olówó rà á fun?
- A kọ òfin gígé nǹkan ọkùnrin tó bá fipá bá obìnrin lòpọ̀ - Àwọn Alfa yarí
- Agolo gáásì kéeké tó ń jò bú gbàmù l‘Eko, ẹ̀mí kan bọ́, mẹ́ta fara pa
- Ewé ṣunko! Babaláwo rèé pẹ̀lú afurasí adigunjalè mẹ́rin láhàmọ́ọ́ ọlọ́pàá
"Nkan ti wọn ṣe yii ko bojumu, ko si le gbe wọn niyi.
Ni èrò tiẹ̀, ọmọ igbimọ Agbaagba ilẹ Yoruba, Yoruba Council of Elders, Kunle Olajide sọ pe, o da oun loju pe Aarẹ Muhammadu Buhari n wa nkan nla ti yoo fi sọ ori Oloye Obasanjo ni, kii se pe o mọọmọ ma ṣe e.

Oríṣun àwòrán, Others
O fikun ọrọ rẹ pe "ko si bi a ṣe fẹ ẹ kọ ìtàn orilẹ-ede Naijiria, lai si orukọ Baba Obasanjo".
"Ẹni ti gbogbo aye n bọ̀wọ̀ fun ni Obasanjo nitori awọn nkan to ṣe nigba to fi jẹ aarẹ ológun, ati alagbada". Nitori naa, ẹ ma jẹ ki a foya rara".
O fi kun ọrọ rẹ pe nkan ti gbogbo ọmọ Naijiria, ati gbogbo ẹ̀yà yoo kan sara si ni wọn yoo fun Obasanjo, eyi to wúwo lọwọ ju fífi orukọ rẹ sọ ibudokọ oju'rin.

Lara awọn ọmọ ilẹ Yoruba to tun sọrọ ni Ọjọgbọn Banji Akintoye.
Oun naa sọ fun BBC pe, nkan buruku gba a ni bi ìjọba apapọ ko se fi orukọ Obasanjo si ara awọn eeyan naa.
O ni o yẹ ki ijọba fi ọrọ naa lọ awọn ọmọ ilẹ Yoruba ati ẹ̀yà to ku, lati gba akọsilẹ orukọ awọn eeyan to ṣe pataki si ẹ̀yà wọn, lati fun ni iru ọlá bẹ ẹ.
Ọrọ ti Minisita tẹlẹ fun irinna ofurufu, Femi Fani-Kayode sọ, ko yatọ si ti Ọjọgbọn Akintoye.
Kayode sọ pe orukọ Obasanjo lo yẹ ko siwaju gbogbo orukọ yoku.

Oríṣun àwòrán, Others
"Nkan ti wọn ṣe yẹn ko dara, paapa fun ẹni to ti jẹ aarẹ Naijiria lẹẹmeji.
Sugbọn sa, ọrọ naa ko le dun baba, nitori pe ọpọlọpọ ibi, oju ọna, ati agbegbe ni wọn ti fi sọ orúkọ rẹ. Awa ti a jẹ ọmọ Naijiria ni ọrọ naa n dùn."
Fani-Kayode fi kun ọrọ rẹ pe, ko tọ ọ láti maa fi ọrọ oṣelu bo ìtàn mọ́lẹ̀, nitori pe o yẹ ki wọn o bu ọlá fun ẹni to tọ si.

Oríṣun àwòrán, Others
Lori pe boya nitori pe Obasanjo ma n bu ẹnu ẹtẹ lu isejọba Aarẹ Buhari, o sọ pe eyi ko yẹ ko ribẹ.
"Nise lo yẹ ki wọn o ma a kan sára si baba yẹn, nitori pe Naijiria i ba dara ka ni bi gbogbo awọn olori orilẹ-ede to ti jẹ tẹlẹ ṣe n ṣe niyẹn".
Ọ̀pọ̀ òpópónà la fi sọrí Obasanjo ní Kano, ni a kò ṣe fi ibùdókọ̀ rélùwéè sọrí rẹ̀ - Buhari

Oríṣun àwòrán, others
Oriṣiriṣi awuyewuye lo ti n waye lati igba ti ikede jade pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi orukọ àwọn ọmọ Naijiria kan sọ ibudokọ oju'rin.
Bi awọn kan ṣe n kan saara si, ni awọn kan n bu ẹnu ẹtẹ lu u, paapa lẹyin ti ìwé iroyin Daily Trust, pé akiyesi si awọn orukọ naa ti ko ni orúkọ aarẹ Naijiria nigba kan, Olusegun Obasanjo ninu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Botilẹjẹ pe awọn kan sọ oko eebu si iwe iroyin naa, fun pe o gbe 'iroyin ti ko ni itumọ' jáde, awọn kan sọ pe ko tọ ọ bi orúkọ Obasanjo ko ṣe sí nibẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Amọ nigba to n fesi si awuyewuye araalu lori igbesẹ ijọba naa, agbẹnusọ fun aarẹ Muhammadu Buhari , Bashir Ahmad ni ko si ohun to jẹ pataki lori eyi.
Gẹgẹ bo ti wi "Nitori pe orukọ aarẹ tẹlẹ, Olusegun Obasanjo ko si lara orukọ awọn ọmọ Naijiria tijọba fi sọri ibudo reluwe, kii se nnkan pataki.
O ni oloye Obasanjo ni wọ̀n ti fi orukọ rẹ sọri ọpọ nnkan tẹlẹ, to fi mọ ọpọ opopona ni Kano."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Aàrẹ Buhari buwọlu yíyí orùkó àwọn ibùdókọ ọkọ ojú ìrìn bíi ti Apapa padà fi sọrí àwọn èèkàn ìlú

Ileesẹ ijọba apapọ to n risi igbokegbodo ọkọ ati eto irinna ni Naijiria ti fi atẹjade kan sita.
Nínú àtẹ̀jádé yii ni wọn ti kede loni ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn, osu keje pe awọn ibudokọ ọkọ oju irin ni Naijiria a gba orukọ tuntun.
Awọn ibudokọ ọkọ oju irin to wa ni opopona Eko si Ibadan to fi ya lọ ba ti Lagos Port Complex to wa ni ibudokọ ọkọ oju irin Apapa ni Aare Buhari ni ki wọn fi sọri igbakeji rẹ, Ọjọgbọ Yẹmi Osinbajo.
Fun alaye kikun, wo awọn orukọ ti awọn ibudokọ ọkọ oju irin naa n jẹ tẹlẹ ati orukọ tuntun ti ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari fun wọn bayii:
Ibi ti ibudokọ ọkọ oju irin naa wa Orukọ ti ibudokọ ọkọ oju irin naa n jẹ tẹlẹEni ti Buhari fi orukọ ibudokọ ọkọ oju irin tuntun naa sọri bayiiOrukó tuntun ti a o maa pe ibudokọ ọkọ oju irin naa lati isinyii
Opopona Eko si Ibadan Ibudokọ ọkọ oju irin Kajọla Ọjọgbọn Yemi Osinbajo (Igbakeji Aarẹ Buhari) Ibudokọ Yemi Osinbajo
Agbegbe Apapa ni ilu Eko Ibudokọ ọkọ oju irin Apapa Oloye Bola Ahmed Tinubu
(Agba ẹgbẹ o'selu APC) Ibudokọ Bola Tinubu
Agbegbe Ebute Metta Ibudokọ ọkọ oju irin Ebute Metta Ogagun Mobolaji Johnson ( gomina ologun ipinlẹ Eko ri) Ibudokọ Mobolaji Johnson
Agbegbe Agbado Ibudokọ ọkọ oju irin Agbado Alhaji Lateef Jakande ( gomina ipinlẹ Eko ri) Ibudokọ Lateef Jakande
Agbegbe Agege Ibudokọ ọkọ oju irin Agege Babatunde Raji Fashola (minista isẹ àti iléègbé bayii) Ibudokọ Babatunde Fashola
Agbegbe Abeokuta Ibudokọ ọkọ oju irin Abeokuta Ọjọgbọn Wole Soyinka (agba ọjẹ onkọwe) Ibudokọ Wole Soyinka
Agbegbe Papa-Lantoro Ibudokọ ọkọ oju irin Papalanto Funmilayo Ransome-Kuti (Oloogbe akinkanju obinrin Égba) Ibudokọ Funmilayo Ransome-Kuti
Agbegbe Kila- Olodo Ibudokọ ọkọ oju irin OlodoOloye Olusegun Osoba (to ti jẹ gomina ipinlẹ Ogun ri) Ibudokọ Segun Osoba
Agbegbe Omi Adio nitosi IbadaN Ibudokọ ọkọ oju irin Omi-Adio Oloogbe Ladoke Akintola (to ti jẹ Olootu guusu Iwo Oorun Naijiria ri) Ibudokọ Ladoke Akintola
Agbegbe Ibadanibudokọ ọkọ oju irin Ibadan Oloogbe Obafemi Awolowo (Baba iran Yoruba ninu oselu) Ibudokọ Obafemi Awolowo
Agbegbe aarin gbungbun akoso Ibudokọ akoso Operation Control CentreOloogbe Alex Ekwueme (to jẹ igbakeji aarẹ akọkọ ti a dibo yan ni Naijiria)Alex Ekwueme Operation Control Centre
Agbegbe Agbor Ibudokọ ọkọ oju irin Agbor Omowe Goodluck Jonathan (Aarẹ Naijiria tẹlẹ) Ibudokọ Goodluck Ebele Jonathan
Agbegbe Itakpe Ibudokọ ọkọ oju irin Itakpe Adamu Attah (Gomina Kwara akọkọ ti wọn dibo yan)
Agbegbe Ajaokuta ni ipinlẹ Kogi Ibudokọ ọkọ oju irin Ajaokuta Oloogbe Olusola Saraki (agba oje oloselu ni Kwara) Ibudoko Olusola Saraki
Agbegbe Itogbo Ibudokọ ọkọ oju irin Itogbo Augustus Aikhomu (Igbakeji aarẹ labẹ ologun tẹlẹ) Ibudoko Augustus Ahikomu
Agbegbe Agenebode Ibudokọ ọkọ oju irin AgenebodeGeorge Innih (to jẹ gomina ologun ipinle Bendel/ Kwara latijọ) Ibudokọ George Innih
Agbegbe Uromi Ibudokọ ọkọ oju irin Uromi Oloogbe Anthony Enahoro (Ajijangbara oselu awa ara wa) Ibudokọ Anthony Enahoro
Agbegbe Akehen Ibudokọ ọkọ oju irin Ekehen Tom Ikimi (to jẹ minista ọrọ ilẹ okeere tẹlẹ) Ibudokọ Tom Ikimi
Agbegbe Igbanke Ibudokọ ọkọ oju irin Igbanke Samuel Ogbemudia (To jẹ gomina ologun ipinlẹ Bendel latijọ) Ibudokọ Samuel Ogbemudia
Agbegbe Abraka Ibudokọ ọkọ oju irin Abraka ni ipinlẹ Delta David Ejoor (to jẹ ọga agba adari ologun tẹlẹ) Ibudokọ David Ejoor
Agbegbe Opara Ibudokọ ọkọ oju irin OparaMichael Ibru (to je gbajugbaja onisowo) Ibudokọ Michael Ibru
Agbegbe Ujevwuibudokọ ọkọ oju irin Ujevwu Oloogbe Alfred Rewane (to je igbakeji aaré lasiko ologun ri) Ibudokọ Alfred Rewane
Agbegbe Agboribudokọ ọkọ oju irin ni abule Reluwe ni AgborMike Akhigbe (to ti je agba ologun ri) Ibudokọ Mike Akhigbe
Ileeese ijọba apapọ to kede yii salaye pe awọn eeyan wọnyii jk akọni ni Naijiria ti wọn ti gbe ogo ilẹ yii ga daadaa lati ọdun pipẹ sẹyin titi di asiko yii.
Goodluck Ebele Jonathan: Buhari pa orúkọ ọ́fíìsì reluwé tó wà ní ìlú Agbor dà s'órúkọ asáájú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, facebook/kunle ariyo
Lọna ati fi ẹmi imoore han si iṣẹ ribiribi to ṣe lasiko iṣejọba rẹ, aarẹ Muhammadu Buhari ti ni ki wọn fi orukọ ofiisi reluwe to wa ni Agbo, sọrii aarẹ ana, Goodluck Jonathan.
Amugbalẹgbẹ aarẹ lori ọrọ ayelujara, Tolu Ogunlesi lo fi ọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ.
Ogunlesi ni "Aarẹ Muhammadu Buhari ti fọwọsi pe ki wọn fi ọfiisi reluwe to wa ni Agbo, ni ipinlẹ Delta sọri aarẹ Goodluck Jonathan."
- Gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu afurasí tí Ọlọ́pàá ní ó pa Barakat Bello, Grace Oshiagwu àtàwọn míì l'Akinyele Ibadan
- Èèmọ̀! Eyín oníròyìn fò yọ lásìkò tó n ka ìròyìn lọ́wọ́ lórí tẹlifísàn
- Ṣé ojúlówó ni Oogùn apakòkòrò 'Sanitizer' tó ń lò? Wo bóo ṣe lè mọ̀ ayédèrú
- Àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yoruba kò gbọdọ̀ gbàgbé àṣà ati ohun àdàyébá wọn - Ooni Ile Ife
"Orukọ ti yoo maa jẹ bayii ni Goodluck Jonathan Railway Station & Complex."
Ọfiisi reluwe ọhun ni ojuko ileeṣẹ ọkọ oju irin to so Itakpe ati ilu Warri papọ, oun naa lo tun so oju ọna Benin mọ Onitsha, atawọn ilu miran ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @ChibuikeAmaechi
Ọna oju irin naa wa lara ọna reluwe ti ijọba apapọ dawọle, eyii ti yoo so ipinlẹ Eko mọ Calabar atawọn ipinlẹ miran ni iha guusu-ila oorun Naijiria.
- Eruku sọ lálá níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó Lizzy Anjorin, àwòrán àti fídíò nìyíì
- Orin ìsìn ọjọ́ ìbí àṣẹ̀yìndè Ibidunni Ighodalo yóò wáyé, Tope Alabi, Kenolly àtàwọn míì tí yóò kọrin níbẹ̀ rèé
- Wo bí ètò ìsìnkú Tolulope Arotilẹ yóò ṣe lọ nílùú Abuja lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀
- Nínú èèyàn 600 tó ní coronavirus lọ́jọ́ Ẹtì, 275 ló wá láti agbègbè ilẹ̀ Yorùbá
Iṣẹ ọhun ni wọn gbe fun ileeṣẹ agbaṣẹṣe ilẹ China, CCECC lasiko iṣejọba ọmọwe Goodluck Jonathan.
Ọdun 2015 ni aarẹ Buhari fidi Jonathan janlẹ ninu idibo sipo aarẹ to waye, eyii to ṣilẹkun akọsilẹ tuntun oludije sipo aarẹ akọkọ ti yoo gbo ewuro soju aarẹ to wa lori alefa ni Naijiria.
Jonathan: Buhari ní ìwúrí ńlá nìwà ìrẹ̀lẹ̀ Goodluck Jonathan jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Adesina
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣapejuwe aarẹ ana, Goodluck Jonathan gẹgẹ bi olori to jẹ olufọkansin bi Ọgbẹni Jonathan ṣe pe ẹni ọdun mejilelọgọta l'Ọjọru.
Aarẹ Buhari ni Jonathan jẹ olori ti ifọkansin rẹ yoo maa jẹ iwuri fun ọpọ irandiran to n bọ lorilẹede Naijiria.
Ninu atẹjade ti Buhari fi sita lati ọwọ oludamọran rẹ lori ọrọ iroyin, Femi Adeṣina, aarẹ Buhari ni imọran rere ni Jonathan n fun awọn olori Naijiria atawọn olori orilẹ-ede kaakiri ilẹ Afirika, lati igba to ti kuro ni ijọba.
- Àwọn jàndùkú dáná sun Aṣáájú obìnrìn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP mọlé ní Kogi
- Àwọn ọnà ti Olusegun Aroke ń gba wọ́'ke owó nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n rèé
- Ẹ wo fídíò Kìnìhún tí wọ́n mú l'Eko ní ibùgbé rẹ̀ tuntun, Bogije, Lekki
- Seyi Makinde kò leè gba adé lórí àwa ọba 21, iléẹjọ́ ni yóò là wá níjà - Lekan Balogun
- 'Iṣẹ́ akólẹ̀ tí mò ń ṣe níbí, mi ò lè ṣe é láí lái ní Nàìjíríà tórí...'
Buhari wa gbadura ẹmi gigun ati ilera ninu ọrọ fun Jonathan ki o lee tubọ sin orilẹede Naijiria siwaju si.
Aarẹ Buhari sọ pe iwa irẹlẹ ti Jonathan ni jẹ ohun manigbagbe eleyi ti yoo mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba awọn iran to n bọ.
Buhari tun ki gbogbo idile Jonathan pe ọpọ ọdun ni yoo ṣe loke eepẹ.
Aarẹ ana Jonathan gba pe oun fidi rẹmi ninu ibo aarẹ ọdun 2015, ki ajọ eleto idibo INEC to kede Buhari gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu ibo ọhun.













