Violence against women: Ilé aṣòfin Kano buwọ́ lu òfin gígé ǹkan ọkùnrin afipabánilòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Igbimọ awọn Ulamas nipinlẹ Kano ti kọ abadofin ti ile igbimọ Aṣofin ipinlẹ naa buwọlu, lati ge nnkan ọkunrin ẹnikẹni ti o ba fi ipa ba obinrin lopọ.
Ile igbimọ Aṣofin naa buwọlu abadofin to faaye gba ki wọn ge nnkan ọmọkunrin, lẹyin ti aṣofin Nuraddeen Alhassan gbe abadofin naa kalẹ ni Ọjọ kẹẹdogun, Oṣu Keje, ọdun 2020.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Agolo gáásì kéeké tó ń jò bú gbàmù l‘Eko, ẹ̀mí kan bọ́, mẹ́ta fara pa
- Ewé ṣunko! Babaláwo rèé pẹ̀lú afurasí adigunjalè mẹ́rin láhàmọ́ọ́ ọlọ́pàá
- Aàrẹ Buhari buwọlu yíyí orùkó àwọn ibùdókọ ọkọ ojú ìrìn bíi ti Apapa padà fi sọrí àwọn èèkàn ìlú
- 'kò sí ẹ̀rí àrídájú níńu ọ̀rọ̀ Akpabio'
- Ìyá òòṣà fẹ̀sùn àjẹ́ kan ìyá ẹni ọdún 90, aráàlú bá sọ ọ́ lókò pa
- Nàìjíríà ṣí àwọn ilé ìwé padà; Ìdánwò WAEC á bẹrẹ lẹyìn ọdún Iléyá!
- Sunday Igboho yarí, ó fohùn ránsẹ́ sáwọn èèyàn tó ń pẹ̀gàn rẹ̀
Ninu atẹjade ti awọn Ulamas naa fi lede, ti Alaga igbimọ naa, Sheik Ibrahim Khalil buwọlu sọ pe, awọn kọ ofin naa patapata lẹyin ti awọn ṣe agbeyẹwo rẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Bakan naa ni wọn pe fun atunṣe ofin Sharia ti ọdun 2000 ni ipinlẹ Kano.

Oríṣun àwòrán, Others
Amọ, Khalil fikun pe ipinnu awọn ko tun mọ si pe awọn gba ifipabanilọpọ laaye, abi awọn n ṣe agbatẹru fun awọn to n wu iwa buruku yii.
Igbimọ awọn Ulamas naa ni awọn yoo ṣe abẹwo si ile igbimọ Aṣofin ipinlẹ naa lati ba awọn aṣofin jiroro lori ọna abayọ si ofin tuntun naa, ni ọna ti yoo tẹlẹ ẹsin Islam.
- Aàrẹ Buhari buwọlu yíyí orùkó àwọn ibùdókọ ọkọ ojú ìrìn bíi ti Apapa padà fi sọrí àwọn èèkàn ìlú
- 'kò sí ẹ̀rí àrídájú níńu ọ̀rọ̀ Akpabio'
- Ìyá òòṣà fẹ̀sùn àjẹ́ kan ìyá ẹni ọdún 90, aráàlú bá sọ ọ́ lókò pa
- Nàìjíríà ṣí àwọn ilé ìwé padà; Ìdánwò WAEC á bẹrẹ lẹyìn ọdún Iléyá!
- Wo ọkùnrin tó fipá bá ìyá ọdún 60 lò nítorí 'ìkébè rẹ̀ tó ń mì
Wo ọkùnrin tó fipá bá ìyá ọdún 60 lò nítorí 'ìkébè rẹ̀ tó ń mì
Gbogbo awọn majẹobajẹ lorilẹede Naijiria ni wọn n ke gbajare lori ọwọja iwa ipa si awọn obinrin, paapaa julọ ifipabanilopọ.

Oríṣun àwòrán, others
Ọrọ naa gba ibi ọtọ tun yọ pẹlu iroyin arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Sani Garba ti wọn ni o fipa ba obinrin ẹni ọgọta ọdun lopọ.
Kayefi nla lo jẹ nigba ti Sani ṣalaye idi to fi hu iwa buruku to hu naa.
O ni idi iya naa to maa n ji nigbakugba to ba n rin lo mu ki oun ma lee mu ara duro mọ ti oun si fi lo ipa fi baa lo.
Hmmmm, ọrọ buruku tountẹrin. Ni bi a ṣe n sọrọ yii, ọwọ ọlọpaa ti tẹ Sani Garba ni ipinlẹ Niger.
Iroyin abẹle sọ wi pe nṣe ni afunrasi naa ja wọ yara arabinrin naa ni ọjọ kejidinlogun oṣu keje ni nnkan bi agogo mẹrin abọ irọlẹ to si fi ipa baa lo pọ.
Bakan naa ni afunrasi naa tun ṣalaye fawọn akọroyin pe ko din ni obinrin arugbo mẹta ti oun ti fipa ba lopọ ladugbo naa.
O ni oun ko lowo lati fi fẹ ọmọge loun fi doju kọ awọn abilekọ ati arugbo.












