Ogun robbery: Ọlọ́pàá ní àwọn afurasí adigunjalè náà ló ń ṣe ọṣẹ́ ní Abeokuta

Awọn ọlọpaa SARS

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Babalawo kan ati awọn afurasi adigunjale marun miran, to maa n da awọn eeyan agbegbe Osiele nilu Abeokuta riboribo, ni ọwọ palaba wọn ti segi.

Osisẹ alarina fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi lo kede aseyọri yii ninu atẹjade kan to fisita lọjọ Aje.

Oyeyemi ni awọn eeyan lo ta ikọ ọlọpaa to n gbogun tiwa idigunjale SARS lolobo nipa irinsi awọn afurasi naa ati ibuba wọn to wa lagbegbe Odeda.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ni kete ti wọn ta awọn ọlọpaa SARS lolobo ni wọn ya bo adugbo naa, ti ọwọ si tẹ afurasi adigunjale mẹrin.

Ọrọ ti wọn sọ si lo jẹ ki ọwọ tẹ babalawo ti wọn lo jẹ baba isalẹ wọn, to maa n ro wọn lagbara nigba kuugba ti wọn ba n lọ sisẹ idigunjale, tabi gba ọmọ ẹgbẹ tuntun sagbo wọn."

Àkọlé fídíò, Hepatitis: A kò leè kóo nípa dídìmọ́ ara ẹni

Alarina ọlọpaa fikun pe lara awọn ohun ti wọn gba lọwọ awọn adigunjale naa ni ibọn agbelẹrọ labẹle, aake, ọbẹ meji ati oniruuru oogun abẹnu gọngọ.

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Others

O wa fikun pe Kọmisana ọlọpaa fun ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun ti pasẹ pe ki wọn se ẹkunrẹrẹ iwadii nipa awọn afurasi naa.

Géndé ọkùnrin mẹ́ta gba ìdájọ́ ikú fún ẹ̀sùn ìdigunjalè l'Ọṣun

Okun iṣekupani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gende ọkunrin mẹta ti gba idajọ iku nipa yiyẹ igi fun wọn nile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Ọṣun.

Onidajọ Jide Falola ti ile ẹjọ giga naa to wa ni ilu Ikirun sọ pe awọn mẹtẹẹta, Nuhu Jimoh, Ndubisi David ati Aderibigbe Oluwaseun, jẹbi ẹsun jija banki mẹta l'ole nilu Ikirun l'ọdun 2016.

Awọn ọkunrin naa ni wọn sọ pe wọn wa lara ikọ adigunjale to fi nnkan abugbamu fọ ilẹkun awọn banki mẹta ọhun, ki wọn o to ja wọn lole.

Ṣugbọn, ọrọ bẹyin yọ fun wọn nigba ti awọn ọlọpaa dena de wọn, ki wọn o maa ba ri owo ti wọn jiko gbe lọ.

Iroyin sọ pe ọpọlọpọ araalu ati ọlọpaa meji lo padanu ẹmi wọn lasiko ti awọn adigunjale naa ati awọn ọlọpaa kọju ija ibọn sira wọn.

Ẹsun mẹta to ni i ṣe pẹlu ole jija, ipaniyan ati nini nkan ija oloro lọna aitọ ni wọn fi kan wọn.

Bakan naa ni a gbọ pe ibọn ọlọpaa ran diẹ lara awọn adigunjale naa lọ sọrun, ti awọn yooku wọn si salọ.

Onidajọ Falola dajọ pe ki wọn o yẹgi fun awọn mẹtẹẹta titi ti ẹmi yoo fi bọ l'ẹnu wọn, to si tun paṣẹ pe ki awọn ibọn ti ileeṣẹ ọlọpaa gba lọwọ wọn o di ti ileeṣẹ ọlọpaa, ki owo ti wọn gba lọwọ wọn o si di ti ijọba ipinlẹ Ọṣun.