Coronavirus: Àjọ WHO ní àìsàn pàjáwìrì gbogbo àgbaye ló dé yìí

Àjọ WHO ni ó ti wá ṣe pataki fun gbogbo àyé lati mọ báyìí pe wọ́n gbọdọ gbáradì láti ma jẹ ki àìsàn náà tàn kan, èyi mọ síṣe àmùjútó, ki wọ́n si maa fi afura si pamọ.
Siṣe àwári àwọn ti wọ́n ba fúnra si wọ́n ko ààrùn náà.
WHO ni ki gbogbo àwọn orile-èdè ma fi ọ̀rọ̀ náà sere ki wọ́n sì maa ni àkọsilẹ gbogbo àwọn ìwádìí wọ́n ki wọ́n si rii dáju pe wọ́n n pin ìwádìí náà pẹlu Ajo WHO.
- Ìròyìn òfegè lásán ni! A ò fi físà dun Bísọ̀bù Oyedepo- US Embassy
- Sinimá tí Lateef Adedimeji dá nikan jẹ́ òṣèré yóò jáde, Yemi Solade fi ọ̀pọ̀ fọ́tò "dẹngẹ pó" lọ́jọ́ ìbí rẹ̀
- Uber ni mo fẹ́ máa gbé báyìí, mi ò tún fẹsẹ̀ rìn mọ́ - Agunbaniro to n gba N33,000
- Bí Favour ṣe sùn, mo gbá ọmọ odó mọ́ ọ lórí a sì gé orí, ọkàn àti ọyàn rẹ̀ fún àsèjẹ - Kayeefi
Bí WHO ṣe ni àwọn ti n gbárrùkù ti àwọn orilẹ̀-èdè láti mọ iyé ènìyàn to ti lùgbàdi àìsàn náà àpẹrẹ wà pé ìbáṣepọ hàn láàrin China àti Afirika.
Dokita Matshidiso Moeti, to jẹ adari ẹkun Afirika ti fi ìlànà ránṣẹ́ si gbogbo àwọ ilẹ Afrika ti o ṣeeṣe ki àìsàn náà jẹ wọ.
Ajọ WHO ti tọka si àwọn òrilèdè ti o ṣeeṣe ki Coronavirus wọ ni Algeria, Angola, Cote d'Ivoire, Democratic Republic of Congo, Ethiopia,
Awọn orilẹ̀-èdè miran ni Ghana, Kenya, Mauritius, Nigeria, South Africa, Tanzania, Uganda and Zambia o si ṣe pàtàkì láti maa ṣe àyẹwò ni pápákọ òfùrufu ki àwọn ènìyàn to wọ ilú
Aisan Coronavirus, jẹ èyí to ma koju ija si ìlera ènìyàn to si maa n mu ọ̀fìkìn lọ́wọ́
Gẹ́gẹ́ bii ìwádìí ni ọgbọ̀n ọjọ oṣù kini ọdun 2020, ènìyàn to dín ni ẹgbẹ̀run mẹjọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilẹ Gẹẹsi ti kede pe eniyan meji ti ni aisan corona virus ni orilẹede wọn.
Adari eto ilera ni orilẹede naa, Ọjọgbọn Chris Whitty kede pe awọn mejeeji naa wa lati idle kan naa ati wi pe wọn ti bere si ni gba iwosan.
Whitty ni ajọ eleto ilera orilẹede naa wa ni sepẹ lati koju aarun naa, ati lati wa awọn ti awọn mejeeji naa ti farako lati le dẹkun itanka aarun naa.
O fikun pe awọn ti gbaradi fun aarun naa nitori naa ni awọn ṣe tete koju rẹ ki kiakia.
Wọn ko fi ohun miran lede nipa iru eniyan ti wọn jẹ ati ami idanimọ wọn.
Ko tilẹ fi lede ibi ti wọn ti n gba itọju.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ti le ni igba eniyan to ti ku latari aarun corona virus ni orilẹede China, ti ẹgbẹẹrun wọn si ti ni aisan naa kaakiri.
Bakan naa ni orilẹede mejidinlogun ti ko aarun naa, ti mejidinlọgọrun si ti ko aarun naa.
Ààrun Coronavirus ti dí àjàkálẹ̀ gbogbo àgbàyé - WHO
Ajọ eleto ilera lagbaye, WHO ti kede aarun coronavirus gẹgẹ bi ajakalẹ aarun gbogbo agbaye.
Eyi ko ṣẹyin bi Ajọ agbaye ṣe ni aisan naa n tankalẹ si kaakiri agbaye, ipaya si wa wi pe o le e ran lọ si awọn agbeegbe ti ko ni eto ilera to daju.
Olori ajọ WHO sọ wi pe kii ṣe nitori nkan to n ṣẹlẹ ni China ni awọn fi kede re, amọ ọna lati dena ki o ma ṣe de awọn orilẹede ti iya ati iṣẹ n koju ni awọn ṣe kede eto pajawiri naa.
Bakan naa ni orilẹede Amẹrika ti sọ fun awọn eniyan rẹ lati ṣọra lati lọ si orilẹede China.
O lẹ ni igba eniyan lorilẹede China to ti ku nipasẹ aarun naa, ti ẹgbẹrun mẹwa eniyan si ti ni aarun naa.
Ajọ WHO naa fikun pe aarun naa ti wa ni orilẹede mejidinlogun yatọ si China, ti eniyan mejidinlọgọrun si ti ni aarun naa, amọ ti ko si ẹni to ti ku nipasẹ aarun naa.
Iwadii fikun wi pe awọn to ni aarun naa ti lọ si ibi to ti bẹrẹ ni agbeegbe Wuhan, lorilẹede China.
Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba ń gbé láti dènà ààrùn coronavirus ní Nàìjíríà
O kere tan bayii, eeyan bi aadọsan ni iroyin sọ pe wọn ti dero ọrun lẹyin ti wọn lugbadi aarun Coronavirus to n ran kiri bi ina inu ọyẹ.
Akọsilẹ tawọn alaṣẹ orilẹede China fi sita ṣalaye pe eeyan to din diẹ lẹgbẹrun mẹjọ lo ti ni aarun ọhun eyi to bẹrẹ niluu Wuhan.
Gbogbo orilẹede lagbaaye ni wọn ti n ṣo ra bayii lẹyin ti aarun naa ti ran de orilẹede mẹrindinlogun.
Orilẹede Naijiria wa lara awọn orilẹede to n kaya soke lori aarun Coronavirus ti bẹrẹ si ni ran kaakiri agbaye.
Idi abajọ ni pe ọpọ ọmọ Naijiria lo wa lorilẹede China ti wọn n kawe atawọn mii ti wọn n rinrin ajo lọ sibẹ fun okoowo ati fawọn nnkan miiran.
Awọn ohun ti Naijiria n ṣe niyii lati gbogun ti aarun Coronavirus
Minisita fun eto ilera, Osagie Ehanire ṣalaye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kinni odun 2020 pe Naijiria naa ko ni kawọ gbera lati rii wi pe aarun naa ko wọ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Ma ṣe lọ si China bayii''
Minisita eto ilera Osagie Ehanire ti kilọ fawọn ọmọ Naijiria ti wọn fẹ rinrin ajo lọ si orililẹede China lasiko pe ki wọn maa tii lọ bayii.
O ni imọran yii ṣe pataki fawọn ọmọ Naijiria lakoko yii ki wọn maa ba lugbadi aarun naa.
Minisita tun rọ awọn to ṣẹṣẹ de lati orilẹede China atawọn orilẹede ti aarun Coronavirus ti ran de pe ki wọn ya ara wọn sọtọ fun ọsẹ meji koda bi ko ba si apẹrẹ pe wọn ti ko aarun naa.
Iṣọra lawọn abawọle si Naijiria
Minisita eto ilera Osagie Ehanire tun ṣalaye pe ijọba ti ṣeto pe kawọn ẹṣọ wa ni imurasilẹ lawọn abawọle si Naijiria to fi mọ papakọ ofurufu marun un niluu Abuja, Eko, Enugu, Port Harcourt ati ilu Kano.
Ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ ofurufu ni Naijiria naa ti rọ awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu atawọn arinrinajo lati fọwọ sowọpọ pẹlu awọn alakalẹ lati dena aarun Coronavirus ko maa ba wọ Naijiria.

Ifọwọsowọpọ ajọ NCDC ati ajọ eto ilera lagbaaye WHO
Ajọ to n ri si didena ajankalẹ aarun ni Naijiria NCDC ṣalaye pe awọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ eto ilera lagbaaye lori aarun Coronavirus.
Ajọ naa rọ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn maa paya lori aarun ọhun.
Awọn ọmọ Naijiria ni China nkọ?
Oludari ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa niluu okere, Abike Dabiri-Erewa sọ BBC pe ajọ naa ko gba iroyin pe ọmọ Naijiria kankan ti lugbadi aarun naa lorilẹede China.
Abike sọ pe awọn akẹkọọ to jẹ ọmọ Naijiria ni China ti lọ si olu ile iṣẹ orilẹede Naijiria lorilẹede naa.
O fikun ọrọ rẹ pe ijọba tin gbero lati ko awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko tii lanfaani lati lọ si olu ile iṣẹ Naijiria ni China wale.












