Corona virus:Agbeegbe Wuhan ni China da bi ilu awọn oku

Ileeṣẹ iroyin BBC ṣe abẹwọ si agbeegbe Wuhan nibi ti iṣẹlẹ Corona Virus ti kọkọ waye lorilẹede China.
Fídío náà rèé
Awọn to ṣẹ abẹwọ naa sọ wi pe niṣe ni ilu naa dakẹ rọrọ bi isa oku nitori awọn eniyan tira wọn mọle lati dena titanka aarun naa.
Bakan naa ni awọn eleto aabo lorilẹede naa gba ki awọn eniyan wọ agbeegbe Wuhan, amọ wọn ko le e jade.
Lọwọlọwọ, Awon orileede to ni eniyan won ni China ti bẹrẹ si ni ko awọn eniyan wọn kuro ni agbeegbe naa.
Orilẹede Japan, Amerika ati Ilẹ Yuroopu n ko awon eniyan wọn, nigba ti Australian ti pese agbeegbe to jina si ara ilu fun awọn ọmọ ilẹ wọn to ba ti China de.









